“Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ”: “Life devoid of consumption of pepper is trifle”

Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Ata gbigbẹ, Ata gígún àti awọn èlò ọbẹ̀ – Jalapeno, Serrano, Cayenne & various spices. Courtesy: @theyorubablog

Ata ṣe pàtàki ninu àwọn èlò ọbẹ̀.  Yorùbá ni “Ẹ̀mí ti ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ” nitori eyi, lai si ata ninu ọbẹ̀, ọbẹ̀ o pe.  Ko si ọbẹ̀ Yoruba ti enia ma jẹ lai ni ata, fún àpẹrẹ wọn ki jẹ ila funfun tàbi Ewédú ti wọn se lai ni ata lai bu ata ọbẹ̀ si.

Oriṣiriṣi ata: Ata-rodo, Ata-ṣọmbọ, Ata-wẹ́wẹ́, Ata-Ijọsin, Tataṣe, Ata gbigbẹ, Ata gígún

Àwòrán ata ti ó wá ni ojú ewé yi wọ́pọ̀ ni ọjà Yorùbá.

 

Atarodo – Habanero pepper. Courtesy: @theyorubablog

 

Tataṣe – Bell pepper. Courtesy: @theyorubablog

 

 

 

 

Ọbẹ̀ Yorùbá ti wọn fi ata gígún àti èlò ilẹ̀ wa se ki wọn bi ọbẹ̀ ìgbà lódé ti wọn fi èlò okere se.  Bi nkan ti wọn to ni ilu, a le fi Ẹ̃dẹgbẹrin Naira se ìkòkò àwọn ọbẹ̀ Yorùbá bi: ilá-àsèpọ̀, ẹ̀gúsí funfun, àpọ̀n, àjó àti bẹ̃bẹ lọ fún idile enia mẹfa.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-06 09:00:39. Republished by Blog Post Promoter

Ọ̀tún wẹ Òsì, Òsì wẹ Ọ̀tún, Lọwọ́ fi Nmọ: Right Washing The Left & The Left Washing The Right Makes For Clean Hands

Washing hands

There is a Yoruba saying that, the right hand washes the left, and the left washes the right for clean hands. Image is courtesy of Microsoft Free Images.

Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ọwọ́ ni a fi njẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá, nítorí kò si ṣíbí tó dára tó ọwọ́ lati fi jẹ oúnjẹ òkèlè bi iyán, èyí jẹ kó ṣe pàtàkì lati fọ ọwọ́ mejeji lẹ́hìn oúnjẹ.  Fífọ ọwọ́ kan kòlè mọ́ bi ka fọ ọwọ́ mejeji.

Ọ̀rọ̀, “ọ̀tún wẹ òsì, òsì wẹ ọ̀tún, lọwọ́ fi nmọ” wúlò lati gba àwọn ènìà níyànjú wípé àgbájọwọ́ lãrin ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ará ìlú lérè.

Yorùbá ni “Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọya, ajẹjẹ ọwọ́ kan ko gbe ẹrú dórí”, ọmọ Yorùbá nílélóko, ẹ jẹ́kí a parapọ̀ tún ílú ṣe.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-10 02:30:45. Republished by Blog Post Promoter

“Ọdún nlọ si òpin”: Ẹ ṣọ́ra fún oníjìbìtì/ẹlẹ́tàn – “End of year is fast approaching”: Beware of (419) Fraudsters

Ìparí ọdún sún mọ́lé, àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì/ẹlẹ́tàn ma nbọ́ sita lati ṣe iṣẹ́ ibi, nipa ji ja àwọn ará ilú ti kò bá funra ni olè.  Àṣà Yorùbá ni ayé àtijọ́ ni lati gbé àwọn ti ó bá hùwà rere ga, lati yẹ àwọn ti ó bá ṣe iṣẹ́ àṣe yọri si.

Ẹ ṣọ́ra bi ẹ bá fẹ́ gbowó lẹ́nu ẹ̀rọ-owó – Beware of ATM thieves

Ẹ ṣọ́ra bi ẹ bá fẹ́ gbowó lẹ́nu ẹ̀rọ-owó – Beware of ATM theft

Yorùbá ni “Ọmọ ẹ o ṣe àgbàfọ̀, ó kó aṣọ wálé, ẹ ò ri ojú olè bi”, ọ̀pọ̀ òbi ki bèrè bi ọmọ wọn ti ri owó mọ nitori àwọn ẹlẹ̀tàn/oníjìbìtì/ ori ayélujára àti Òṣèlú nkó ohun ti ki ṣe ti wọn wálé.  Ẹ̀sìn àti àṣà ayé òde òni ngbe àwọn olè àti oníjìbìtì lárugẹ.   Nitori eyi “olówó ojiji” pọ si láwùjọ laarin ẹni ti ó wà ni ipò giga àti ipò kékeré.  Iṣẹ́ Ọlọrun àti Òṣèlú ti di ọ̀nà ti èniyàn fi le di “olówó lojiji”.  Ọ̀̀pọ̀ ọmọ ilé-iwé giga ti kò ti ilé-ọlọ́rọ̀, tàbi ilé Òṣèlú jade, ti yi si olè jijà lori ayélujára ju pé ki wọn di gun jalè.

Ni ayé àtijọ́, bi ọdún bá dé, olè jija pẹ̀lú ipá ló wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni iwà ẹ̀tàn ti a mọ̀ si oníjìbìtì pàtàki ni ori ayélujára ló wọ́pọ̀.  Ó ti pẹ ti ẹ̀tàn/jibiti ori ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n, irú àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì ma nko ọ̀pọ̀ iwe lori ayélujára si ẹgbẹgbẹ̀rún èniyàn ni àgbáyé pẹ̀lú èrò lati jẹ nibi ti wọn kò ṣe si.   Ẹni ti kò bá funra á jábọ́ si wọn lọwọ, nitori eyi ẹ ṣọ́ra fún àdàmọdi iwé lati ilé-ifowó-pamọ́ tàbi ọ̀dọ̀ ẹni ti ẹ kò mọ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-28 10:45:51. Republished by Blog Post Promoter

ÌJÀPÁ JẸ ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ: The Tortoise is Punished for not Heeding to a Warning

ÌJÀPÁ/Àjàpá JẸ ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ: THE RESULT OF DISOBEDIENCE AND GREED

The African tortoise

The tragic Tortoise — having eaten food made for his wife by the Herbalist — there really should have been a warning as to consequence. Image is courtesy of @theyorubablog

Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Ìjàpá/Àjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí.  Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn.  Yáníbo ko dúró lásán, ó tọ Babaláwo lọ láti ṣe ãjo bí òhun ti le ri ọmọ bí.

Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo.  Babaláwo kìlọ̀ fún Ìjàpá gidigidi wípé õgùn yí, obìnrin nìkan ló wà fún, pé kí o maṣe tọwò.  Ìjàpá ọkọ Yáníbo ṣe àìgbọràn, ó gbọ õrùn àsèjẹ, ó tanwò, ó ri wípé ó dùn, nítorí ìwà wobiliki ọkánjúwà, o ba jẹ àsèj̀ẹ tí Babaláwo ṣe ìkìlọ̀ kí ó majẹ. Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú.  Yorùbá ni “ohun ti a ni ki Baba mágbọ, Baba ni yio parí rẹ”.  Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ:

Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀,  Alugbirinrin 2ce
Õgùn to ṣe fún mi lẹ́rẹkan, Alugbinrin
Tóní nma ma fọwọ́ kẹnu, Alugbinrin
Tóní nma ma fẹsẹ kẹnu,  Alugbinrin
Mo fọwọ kan ọbẹ̀, mo mú kẹnu, Alugbinrin
Mofẹsẹ kan lẹ mo mu kẹnu, Alugbinrin
Mobojú wo kùn o ri gbẹndu, Alugbinrin
Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀, Alugbinrin 2ce

Play the Tortoise’ tragic song here:

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: Babalawo mo wa bebe(mp3)

Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀.  Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú.

Ìtàn yí kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú.  Ìtàn Yorùbá yi wúlò lati ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ti o nwa owó òjijì nípa gbígbé õgùn olóró mì lati kọjá lọ si òkè okun/Ìlúòyìnbó lai bìkítà pé, bí egbògi olóró yí ba bẹ́ si inú lai tètè jẹ́wọ́, ikú ló ma nfa.  Ìtàn nã bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-21 10:45:28. Republished by Blog Post Promoter

“Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”: “A borrowed trouser/pant, if it is not too loose on the legs, it is too tight at the thigh”.

Ìwà àti ìṣe ọ̀dọ́ ìgbàlódé, kò fi àṣà àti èdè Yorùbá hàn rárá.

Aṣọ àlòkù ti gbòde, dipò aṣọ ìbílẹ̀.  Ọpọlọpọ aṣọ àgbàwọ̀ yi kò wà fún ara àti lilò ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú.  Ọ̀dọ́ miran a wọ asọ àti bàtà òtútù ninu ooru.  Ọ̀pọ̀ Olùṣọ́-àgùntàn àti Oníhìnrere, ki wọ́ aṣọ ìbílẹ̀, wọn a di bi ìrẹ̀ pẹ̀lú aṣọ òtútù.

Èdè ẹnu wọn kò jọ Oyinbo, kò jọ Yorùbá nitori àti fi ipá sọ èdè Gẹẹsi.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”.  Bi a bá wo òwe yi, àti tun ṣòkòtò àgbàwọ̀ ṣe lati báni mu, ni ìnáwó púpọ̀ tàbi ki ó má yẹni.  Bi a bá fi òwe yi ṣe akiyesi, aṣọ àlòkù ti wọn kó wọ̀ ìlú npa ọrọ̀ ilẹ̀ wa.  Àwọn ti ó rán-aṣọ àti àwọn ti ó hun aṣọ ìbílẹ̀, ko ri iṣẹ́ ṣe tó nitori aṣọ àlòkù/òkèrè ti àwọn ọdọ kó owó lé .  A lè fi òwe yi bá àwọn ti ó nwọ aṣọ-alaṣọ àti àwọn ti ó fẹ́ gbàgbé èdè wọn nitori èdè Gẹẹsi wi.  Òwe yi tún bá àwọn Òṣèlú ti ó nlo àṣà Òṣè́lú ti òkè-òkun/Ìlú-Oyinbo lai wo bi wọn ti lè tunṣe lati bá ìlú wọn mu. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-13 16:33:18. Republished by Blog Post Promoter

Bί a bá ránni ni iṣẹ ẹrú: One sent on a slavish errand (on man’s inhumanity to man)


The Mido Macia Story courtesy of NEWSY reporting from multiple sources and giving a broader view


Yorὺbá nί “Bί a bá ránni nί iṣẹ ẹrú, a fi tọmọ jẹ”.  Ọlọpa tί o yẹ ki o dãbo bo ará àti ẹrú nί ìlú, nhuwa ìkà sί àwọn tί o yẹ ki wọn ṣọ.  Ọlọpa South Africa so ọdọmọkunrin ọmọ ọdún mẹta dinlọgbọn – Mido Gracia, mọ ọk`ọ ọlọpa, wọ larin ìgboro, lu, lẹhin gbogbo eleyi, ju si àtìm`ọle tίtί o fi kú.  Ọlọpa wọnyi hὺ ìwà ìkà yί nίgbangba lai bìkίtà pe aye ti lujára. Eleyi fi “Ìwà ìkà ọmọ enia sί ọmọ enia han”.   Ọlọpa South Africa ṣi àṣẹ ti wọn nί lὸ, wọn rán wọn niṣe ẹrú, wọn o fi tọmọ jẹ.  Sὺnre o Mido Macia.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba proverb says that, “One sent on a slavish errand, should deliver the message with the discretion of an heir”. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-03-02 00:25:30. Republished by Blog Post Promoter

“Bi a bà jẹ̀kọ à dári ji Ewé”: À-lò-tún-lò – “After eating the corn starch meal, forgive the leaf in which it is wrapped” – Recycling

Ewé iran - Organic food wrapping leaves.  Courtesy: @theyorubablog

Ewé iran – Organic food wrapping leaves. Courtesy: @theyorubablog

Ki ariwo à-lò-tún-lò tó gbòde ni aiyé òde òni nipa àti dáàbò bo àyíká ni Yorùbá ti ńlo à-lò-tún-lò pàtàki li lo ewé lati pọ́n oúnjẹ.

Oriṣiriṣi ewé ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn fi má ńpọ́n oúnjẹ bi: ẹ̀kọ, ọ̀ọ̀lẹ̀/mọ́in-mọ́in, irẹsi sisè (ọ̀fadà), obì àti bẹ̃bẹ lọ.  Ewé iran/ẹ̀kọ ló wọ́pọ lati fi pọ́n ẹ̀kọ, ọ̀ọ̀lẹ̀/mọ́in-mọ́in, iyán, àmàlà, irẹsi sisè àti bẹ̃bẹ lọ.  Ewé obì, ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀, ewé kókò, àti àwọn ewé yókù ni iwúlò wọn ni ilé tàbi lóko. Gbogbo ewé wọnyi wúlò fún àyiká ju ọ̀rá ti wọn ńlò lati pọ́n oúnjẹ láyé òde òni. Ewé li lo fún pi pọ́n àwọn oúnjẹ kò léwu rárá bi ọ̀rá igbàlódé.

Yorùbá ni “Bi a bà jẹ̀kọ à dári ji Ewé”.  Òwe yi túmọ̀ si pé, bi a jẹ oúnjẹ inú ewé tán, à ju ewé nù.  Ewé ti a kó sọnù wúlò fún àyiká ju ọ̀rá igbàlódé lọ.  Bi wọn da ewé si ilẹ́, yio da ilẹ́ padà, bi wọn da sinú omi/odò, kò léwu fún ẹja àti ohun ẹlẹmi inú omi/odò, bi  ọ̀rá àti ike igbàlódé ti ó ḿba àyiká jẹ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán lilo ewé lójú iwé yi.

ENGLISH TRANSLATION

Before the recycling campaign began in the recent times, in order to preserve the environment, Yoruba people had been recycling particularly in the use of leaves to wrap or preserve food.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-23 10:15:43. Republished by Blog Post Promoter

A Dúpẹ́ fún Ẹyin Àyànfẹ́ tó Bẹ̀rẹ̀ sí Tẹ̀léwa ní Twitter: Thank You to Our New Twitter Followers

Twitter followers

Twitter followers

Ẹfi ojú sọ́na lọ́sọ̀sẹ̀ fún kíkọ nípa àwọn nkan wọnyi lédè Yorùbá àti ìtum̀ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì: Ìmúlò Òwe, Kíkọ Èdè, Ìtàn àti Ìròyìn tí a lè fi kọ́gbọ́n, Ẹgbẹ́ àti Oúnjẹ Yorùbá ni ìlú London, New York, Chicago, Orlando àti bẹ̃bẹ lọ.  Ẹ bá wa sowọ́pọ̀ láti ri pé èdè wa kò kú nípa kíkọ àti kíkà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ẹ ṣé púpọ̀, ilé àti èdè Yorùbà kò ní parun o lágbára Èdùmàrè (Àṣẹ).

ENGLISH TRANSLATION

Watch out weekly for postings on: application of Yoruba Proverbs, posts to help you learn Yoruba, folklore, news that we can learn lessons from, stories about the Yoruba community and food in London, New York, Chicago, Orlando etc.  Join us to ensure that the Yoruba language is not extinct by writing and reading Yoruba on the Internet.

Thanks so much, The Yoruba language will not be destroyed by the power of God and our collective efforts (Amen).

 

Share Button

Originally posted 2013-05-17 02:06:24. Republished by Blog Post Promoter

Tọ́jú Ìwà Rẹ Ọ̀rẹ́ Mi – Ọ̀rọ̀-orin lati Ìwé Olóògbé Olóyè J.F. Ọdúnjọ – My friend, care about your character – a poem by late Chief J.F. Odunjo

Ọ̀rọ̀-orin yi jẹ ikan ninú àwọn àkọ́-sórí ni ilé-ìwé alakọbẹrẹ ni ilẹ̀ Yorùbá ni igbà ti ile-iwe àpapọ̀ yè koro.  Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ti gbogbo ilé-ìwé ti kọ èdè abínibí silẹ̀, ọ̀rọ̀-orin ti kò ni ìtumọ̀ ni àṣà àti èdè Yorùbá ni àwọn ọmọ ilé-ìwé ńkà.  Tàbi bawo ni “afárá tó wó lulẹ̀ ni ìlú-ọba” ṣe kan ọmọ ti kò ri iná, omi mímọ́ mu, ọ̀nà gidi, ilé-ìwé ti idaji rẹ ti wó, tàbi ti kò ri afárá ri ni abúlé rẹ̀, ti jẹ́?  A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ti ó ṣe òfin ki wọn bẹ̀rẹ̀ si kọ́ èdè àti àṣà Yorùbá ni gbogbo ilé-ìwé pátápátá.  A lérò wi pé eleyi yi o jẹ́ ki àwọn olùkọ́ àti ọmọ ilé-ìwé bẹ̀rẹ̀ si kọ́ ọ̀rọ̀-orin tàbi àkọ́-sórí ti ó mú ọgbọ́n dáni.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò ki kọ àti ki kà  ọ̀rọ̀-orin yi.

Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi;
Ọlá a má ṣi lọ n’ilé ẹni’
Ẹwà a si ma ṣi l’ára ènìà

Olówó òní ńd’olòṣì b’ó d’ọ̀la
Òkun l’ọlá; òkun n’igbi ọrọ̀
Gbogbo wọn ló ńṣí lọ n’ilé ẹni;
Ṣùgbọ́n ìwà̀ ni mbá ni dé sare’e
Owó kò jẹ́ nkan fún ni,
Ìwà l’ẹwà ọmọ ènìà.

Bi o lówó bi o kò n’íwà ńkọ́?
Tani jẹ f’inú tán ẹ bá ṣ’ohun rere?
Tàbi ki o jẹ́ obìnrin rọ̀gbọ̀dọ́;
Ti o bá jìnà s’ìwà ti ẹ̀dá ńfẹ́,
Tani jẹ́ fẹ́ ọ s’ílé bi aya?
Tàbi ki o jẹ oníjìbìtì ènìà;
Bi o tilẹ̀ mọ ìwé àmọ̀dájú,
Tani jẹ́ gbé’ṣé ajé fún ọ ṣe?

Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi,
Ìwà kò sí, ẹ̀kọ́ dègbé;
Gbogbo ayé ni ‘nfẹ́ ‘ni t’ó jẹ́ rere.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-08-10 02:12:55. Republished by Blog Post Promoter

Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter Holiday

Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.

Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó.  Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn.  A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà.  Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.

Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ.  Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀.  Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá.  Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.

Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó.  Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi.  Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde.  Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn  àwọn àgbàlagbà.  Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin.  Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́.  Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ.  A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.

Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile.  Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.

ENGLISH TRANSLATION

I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter