Tag Archives: Second hand clothing

“Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”: “A borrowed trouser/pant, if it is not too loose on the legs, it is too tight at the thigh”.

Ìwà àti ìṣe ọ̀dọ́ ìgbàlódé, kò fi àṣà àti èdè Yorùbá hàn rárá.

Aṣọ àlòkù ti gbòde, dipò aṣọ ìbílẹ̀.  Ọpọlọpọ aṣọ àgbàwọ̀ yi kò wà fún ara àti lilò ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú.  Ọ̀dọ́ miran a wọ asọ àti bàtà òtútù ninu ooru.  Ọ̀pọ̀ Olùṣọ́-àgùntàn àti Oníhìnrere, ki wọ́ aṣọ ìbílẹ̀, wọn a di bi ìrẹ̀ pẹ̀lú aṣọ òtútù.

Èdè ẹnu wọn kò jọ Oyinbo, kò jọ Yorùbá nitori àti fi ipá sọ èdè Gẹẹsi.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan”.  Bi a bá wo òwe yi, àti tun ṣòkòtò àgbàwọ̀ ṣe lati báni mu, ni ìnáwó púpọ̀ tàbi ki ó má yẹni.  Bi a bá fi òwe yi ṣe akiyesi, aṣọ àlòkù ti wọn kó wọ̀ ìlú npa ọrọ̀ ilẹ̀ wa.  Àwọn ti ó rán-aṣọ àti àwọn ti ó hun aṣọ ìbílẹ̀, ko ri iṣẹ́ ṣe tó nitori aṣọ àlòkù/òkèrè ti àwọn ọdọ kó owó lé .  A lè fi òwe yi bá àwọn ti ó nwọ aṣọ-alaṣọ àti àwọn ti ó fẹ́ gbàgbé èdè wọn nitori èdè Gẹẹsi wi.  Òwe yi tún bá àwọn Òṣèlú ti ó nlo àṣà Òṣè́lú ti òkè-òkun/Ìlú-Oyinbo lai wo bi wọn ti lè tunṣe lati bá ìlú wọn mu. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-13 16:33:18. Republished by Blog Post Promoter