Category Archives: Essays in Yoruba Language

Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter Holiday

Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.

Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó.  Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn.  A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà.  Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.

Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ.  Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀.  Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá.  Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.

Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó.  Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi.  Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde.  Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn  àwọn àgbàlagbà.  Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin.  Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́.  Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ.  A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.

Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile.  Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.

ENGLISH TRANSLATION

I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter

Ohun ti mo fẹ́ràn nipa Ìsimi Iparí Ọ̀sẹ̀ – What I love about the Weekend Break

Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ karun ti a ti bẹ̀rẹ̀ ilé-iwé ni ọ̀sẹ̀, inú mi ma ń dùn nitori ilé-iwé ti pari ni agogo kan ọ̀sán, ti ìsimi bẹ̀rẹ̀.

Mo fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma nri àwọn òbí mi.  Lati ọjọ́ Ajé titi dé ọjọ́ Ẹti, mi o ki ri ìyá àti bàbá mi nitori súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ni Èkó, wọn yio ti jade ni ilé ni kùtùkùtù òwúrọ̀ ki n tó ji, wọn yio pẹ́ wọlé lẹhin ti mo bá ti sùn.

Mo tún fẹ́ràn ìsimi ipari ọ̀sẹ̀ nitori mo ma ńsùn pẹ́, mo tún ma a ńri àyè wo eré lori amóhùn-máwòrán.  Ni àkókò ilé-iwé, mo ni lati ji ni agogo mẹfa òwúrọ̀ lati múra fún ọkọ̀ ilé-iwé ti yio gbé mi ni agogo meje òwúrọ̀.  Ṣùgbọ́n ní igbà ìsimi ipari ọ̀sẹ̀, mo lè sùn di agogo mẹjọ òwúrọ̀.  Ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìyá mi ma nṣe oriṣiriṣi oúnjẹ ti ó dùn, mo tún ma njẹun púpọ̀.  Ni ọjọ́ Àikú (ọjọ́ ìsimi) bàbá mi ma ngbé wa lọ si ilé-ìjọ́sìn, lẹhin isin, a ma nlọ ki bàbá àti ìyá àgbà.  Bàbá àti ìyá àgbà dára púpọ̀.

Ni ọjọ́ Àikú ti ìsimi ti fẹ́ pari, inú mi ki i dùn nigbati òbí mi bá sọ wi pé mo ni lati tètè sùn lati palẹ̀mọ́ fún ilé-iwé ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ Ajé.

ENGLISH LANGUAGE

On Friday the fifth day of schooling, I am always very happy because school closes at one o’clock in the afternoon when the weekend begins. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-07-06 01:10:04. Republished by Blog Post Promoter

Àròkọ ni Èdè Yorùbá – Essay in Yoruba Language

Idi ti a fi bẹ̀rẹ̀ si kọ iwé ni èdè Yorùbá lóri ayélujára ni lati jẹ́ ki ẹnikẹ́ni ti ó fẹ́ mọ̀ nipa èdè àti àṣà Yorùbá ri ìrànlọ́wọ́ lóri ayélujára.

A ò bẹ̀rẹ̀ si kọ àwọn àròkọ ni èdè Yorùbá lati ran àwọn ọmọ ilé-iwé lọ́wọ́ nipa ki kọ àpẹrẹ oriṣiriṣi àròkọ ni èdè Yorùbá àti itumọ̀ rẹ ni èdè Gẹ̀ẹ́si.  A o si tún ka a ni èdè Yorùbá fún ìrànlọ́wọ́ ẹni ti ó fẹ mọ bi ohun ti lè ka a, ṣùgbọ́n kò wà fún àdàkọ.

ENGLISH TRANSLATION

Why The Yoruba Blog is creating a category for Essay in Yoruba language on the internet is to make available on line such resources for those who may be interested.

We shall begin to publish various samples of essay in Yoruba language in order to assist students, interpreted the essay as well as an audio recording of the essay in Yoruba, however, it is not to be copied.

Share Button

Originally posted 2018-06-15 19:19:46. Republished by Blog Post Promoter

Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká – Effect of Environmental Pollution on Rapid Climate Change

Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ ṣe àkiyesi pe enia ndá kún yí yára bi ojú-ọjọ́ ti nyi padà nitori èérí-àyíká.  Ojú-ọjọ́ ti nyí padà lati ìgbà ti aláyé ti dá ayé, ṣùgbọ́n àyípadà ojú-ọjọ́ ni ayé òde òní yára ju ti ìgbà àtijọ́ lọ.

Yorùbá sọ wi pé “Ogun à sọ tẹ́lẹ̀, ki i pa arọ tó bá gbọ́n”. Àsìkò tó lati fi etí si ìkìlọ̀ Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ lóri yí yára bi ojú-ọjọ́ ti nyi padà. Àwọn Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ ńké ìbòsí nipa ohun ti èérí àyíká ndá kún gbi gbóná àgbáyé àti ki ènìyàn ṣe àtúnṣe, lati din ìgbóná kù. Ìgbà gbogbo ni àwọn Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ Àyíká nṣe àlàyé yi ni Àjọ Ìfohùnṣọ̀kan Ìpínlẹ̀ Àgbáyé.

Lára ohun ti o ndá kún èérí àyíká, Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀ tọ́ka si ọkọ̀, ẹ̀rọ mọ̀nà-mọ́ná, ẹ̀rọ-ilé-iṣẹ́, ṣ̀ugbọ́n èyí ti ó burú jù ni àwọn ohun ti wọ́n fi ike ṣe bi i: igò-ike, àpò-ike, ọ̀rá-ike, ike-ìṣeré àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bi ohun ti o ndá kún yi yára bi ojú-ọjọ́ ti nyi padà.

Lára ohun ti o ndá kún èérí àyíká – Factors contributing to Environmental Pollution Courtesy@theyorubablog

Ewé, ìwé tàbi páálí ti a kó sọnù, wúlò fún àyiká ju ọ̀rá ati ike igbàlódé lọ.  Bi wọ́n bá da àwọn ohun ti wọ́n fi ike ṣe dànù si ààtàn tàbi si odò, ki i jẹrà bi ewé. Bi wọn da ewé si ilẹ́, yio da ilẹ́ padà lai ni ewu fún ekòló, igbin àti àwọn kòkòrò kékeré yókù. Bi wọn da ewé, ìwé tàbi páálí si inú omi/odò, kò léwu fún ẹja àti ohun ẹlẹmi inú omi/odò, bi ti ọ̀rá àti ike igbàlódé to léwu fún ẹja àti ẹranko inú odò.

Àwọn ohun ti a lè ṣe lati fi etí si ìkìlọ̀ àwọn Ẹlẹkọ-ìjìnlẹ̀, ni ki a din li lo ọ̀rá ike àti ohun ti a fi ike ṣe kù bi a kò bá lè da dúró pátápátá.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni ìlú Òyìnbó ló ti ṣe òfin lati din li lò ike kù, àwọn miran ti bẹ̀rẹ̀ si gba owó fún àpò-ike ni ọjá lati jẹ́ ki àwọn enia lo àpò àlòtúnlò.  Bi ó bá ṣe kókó ki á pọ́n oúnjẹ, a lè lo ewé fi pọ́n,  jú ọ̀rá tàbi ike lọ.  Ki a fi páálí tàbi apẹ̀rẹ̀ ọparun kó ẹrù, lo àpò àlòtúnlò lati ra ọjà, ka lo ìkòkò alámọ̀ lati ṣe oúnjẹ tàbi tọ́jú oúnjẹ kó lè gbóná, àti ki a din li lo ike kù yio din yi yára bi ojú-ọjọ́ ti nyí padà kù.

Lára àtúnṣe ti ìjọba lè ṣe, ni ki òṣè̀lú ṣe òfin lati din èérí kù, ìpèsè ilé iṣẹ́ ti ó lè sọ àwọn ohun ti a fi ike ṣe di àlòtúnlò àti ki kó ẹ̀gbin ni àsìkò.

Ohun ti gbogbo ará ilu,́ pàtàki àwọn ọ̀dọ́ tún lè ṣe, ni ṣi ṣa ọ̀rá tàbi ike omi àti ohun ti wọn fi ike ṣe, ti o ti dá èérí rẹpẹtẹ si inú odò àti àyíká kúrò.  Gbi gbin igi àti ṣe ètò fún àyè ti omi lè wọ́ si ni ìgbà òjò na a yio din ìgbóná àgbáyé kù.

http://www.theyorubablog.com/wp-content/uploads/2019/01/Voice_190114_2-1.3gp

ENGLISH TRANSLATION

Scientists observed that human activities are contributing to the rapid change of environment as a result of environmental pollution.  From time immemorial, climate had always changed but the change in recent years has been more rapid than usual.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2019-01-15 00:58:39. Republished by Blog Post Promoter

Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká – Effect of Environmental Pollution on Rapid Climate Change

Ẹ wo àròkọ “Yí Yára bi Ojú-ọjọ́ ti nyí padà nitori Èérí Àyíká” lóri ayélujára ni ojú ewé yi: Check out the essay on “Effect of environmental pollution on rapid climate change” on our YouTube channel on the internet.

Share Button

Originally posted 2019-01-21 17:55:15. Republished by Blog Post Promoter