Tag Archives: Green Party

“Bi a bà jẹ̀kọ à dári ji Ewé”: À-lò-tún-lò – “After eating the corn starch meal, forgive the leaf in which it is wrapped” – Recycling

Ewé iran - Organic food wrapping leaves.  Courtesy: @theyorubablog

Ewé iran – Organic food wrapping leaves. Courtesy: @theyorubablog

Ki ariwo à-lò-tún-lò tó gbòde ni aiyé òde òni nipa àti dáàbò bo àyíká ni Yorùbá ti ńlo à-lò-tún-lò pàtàki li lo ewé lati pọ́n oúnjẹ.

Oriṣiriṣi ewé ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn fi má ńpọ́n oúnjẹ bi: ẹ̀kọ, ọ̀ọ̀lẹ̀/mọ́in-mọ́in, irẹsi sisè (ọ̀fadà), obì àti bẹ̃bẹ lọ.  Ewé iran/ẹ̀kọ ló wọ́pọ lati fi pọ́n ẹ̀kọ, ọ̀ọ̀lẹ̀/mọ́in-mọ́in, iyán, àmàlà, irẹsi sisè àti bẹ̃bẹ lọ.  Ewé obì, ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀, ewé kókò, àti àwọn ewé yókù ni iwúlò wọn ni ilé tàbi lóko. Gbogbo ewé wọnyi wúlò fún àyiká ju ọ̀rá ti wọn ńlò lati pọ́n oúnjẹ láyé òde òni. Ewé li lo fún pi pọ́n àwọn oúnjẹ kò léwu rárá bi ọ̀rá igbàlódé.

Yorùbá ni “Bi a bà jẹ̀kọ à dári ji Ewé”.  Òwe yi túmọ̀ si pé, bi a jẹ oúnjẹ inú ewé tán, à ju ewé nù.  Ewé ti a kó sọnù wúlò fún àyiká ju ọ̀rá igbàlódé lọ.  Bi wọn da ewé si ilẹ́, yio da ilẹ́ padà, bi wọn da sinú omi/odò, kò léwu fún ẹja àti ohun ẹlẹmi inú omi/odò, bi  ọ̀rá àti ike igbàlódé ti ó ḿba àyiká jẹ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán lilo ewé lójú iwé yi.

ENGLISH TRANSLATION

Before the recycling campaign began in the recent times, in order to preserve the environment, Yoruba people had been recycling particularly in the use of leaves to wrap or preserve food.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-23 10:15:43. Republished by Blog Post Promoter