Tag Archives: Easter Celebration

Bi mo ṣe lo Ìsimi Àjíǹde tó kọjá – How I spent the last Easter Holiday

Ìsimi ọdún Àjíǹde tó kọjá dùn púpọ̀ nitori mo lọ lo ìsimi náà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ẹbí rẹ ni ilú Èkó.

Èkó jinà si ilú mi nitori a pẹ́ púpọ̀ ninú ọkọ̀ elérò ti àwọn òbí mi fi mi si ni idikọ̀ ni Ìkàrẹ́-Àkókó ni ipinlẹ̀ Ondó.  Lára ilú ti mo ri ni ọ̀nà ni Ọ̀wọ̀, Àkúrẹ́, Ilé-Ifẹ̀ àti Ìbàdàn.  A dúró lati ra àkàrà ni ìyànà Iléṣà.  Ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ wa pàdé mi ni idikọ̀ ni Ọjọta ni Èkó lati gbémi dé ilé wọn.

Èkó tóbi púpọ̀, ilé gogoro pọ̀, ọkọ̀ oriṣiriṣi náà pọ̀ rẹpẹtẹ ju ti ilú mi lọ.  Ilé ẹ̀gbọ́n Bàbá mi tóbi púpọ̀.  Wọ́n fún èmi nikan ni yàrá.  Yàrá mi dára púpọ̀, ó ni ilé-ìwẹ̀ àti ilé-ìgbẹ́ ti rẹ̀ lọ́tọ̀.

Ojojúmọ́ ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ ngbé mi jade lọ si oriṣiriṣi ibi ni Èkó.  Ni ọjọ́ Ẹtì (Jimọ) Olóyin wọ́n gbé mi lọ si ilé-ìjọ́sìn, ẹsin ọjọ náà fa ìrònú nitori wọn ṣe eré bi wọn ṣe kan Jésù mọ́gi, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ Aj̀íǹde, èrò ti ó múra dáradára pọ̀ ni ilé-ìjọsìn, ẹ̀sìn dùn gidigidi.  Mo wọ̀ lára aṣọ tuntun ti ìyàwó ẹ̀gbọ́n Bàbá mi rà fún mi fún ọdún Àjíǹde.  Lati ilé-ìjọ́sìn ọmọdé, àwa ọmọdé jó wọ ilé-ìjọ́sìn  àwọn àgbàlagbà.  Wọn fún gbogbo wa ni oúnjẹ (ìrẹsì àti itan adìyẹ ti ó tóbi) lẹhin isin.  Ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keji Àjíǹde, a lọ si etí òkun lati lọ gba afẹ́fẹ́.  Ẹ̀rù omi nlá náà bà mi lakọkọ, ṣùgbọ́n nitori èrò àti àwọn ọmọdé pọ̀ léti òkun, nkò bẹ̀rù mọ.  A jẹ oriṣiriṣi oúnjẹ, a jó, mo si tún gun ẹsin leti òkun.

Lẹhin ọ̀sẹ̀ meji ti ilé-iwé ti fẹ́ wọlé, ẹ̀gbọ́n Bàbá mi àti ìyàwó rẹ̀ gbé mi padà lọ si idikọ̀ lati padà si ilú mi pẹ̀lú ẹ̀bún oriṣiriṣi lati fún ará ile.  Inú mi bàjẹ́, kò wù mi lati padà, mo ké nitori mo gbádùn Èkó gidigidi.

ENGLISH TRANSLATION

I really had a nice time during the last Easter/Spring holiday because I spent the holiday with my paternal uncle (my father’s older brother) and his family in Lagos. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-06-15 19:28:13. Republished by Blog Post Promoter