Tag Archives: Upright character

Tọ́jú Ìwà Rẹ Ọ̀rẹ́ Mi – Ọ̀rọ̀-orin lati Ìwé Olóògbé Olóyè J.F. Ọdúnjọ – My friend, care about your character – a poem by late Chief J.F. Odunjo

Ọ̀rọ̀-orin yi jẹ ikan ninú àwọn àkọ́-sórí ni ilé-ìwé alakọbẹrẹ ni ilẹ̀ Yorùbá ni igbà ti ile-iwe àpapọ̀ yè koro.  Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ti gbogbo ilé-ìwé ti kọ èdè abínibí silẹ̀, ọ̀rọ̀-orin ti kò ni ìtumọ̀ ni àṣà àti èdè Yorùbá ni àwọn ọmọ ilé-ìwé ńkà.  Tàbi bawo ni “afárá tó wó lulẹ̀ ni ìlú-ọba” ṣe kan ọmọ ti kò ri iná, omi mímọ́ mu, ọ̀nà gidi, ilé-ìwé ti idaji rẹ ti wó, tàbi ti kò ri afárá ri ni abúlé rẹ̀, ti jẹ́?  A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣòfin àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó ti ó ṣe òfin ki wọn bẹ̀rẹ̀ si kọ́ èdè àti àṣà Yorùbá ni gbogbo ilé-ìwé pátápátá.  A lérò wi pé eleyi yi o jẹ́ ki àwọn olùkọ́ àti ọmọ ilé-ìwé bẹ̀rẹ̀ si kọ́ ọ̀rọ̀-orin tàbi àkọ́-sórí ti ó mú ọgbọ́n dáni.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò ki kọ àti ki kà  ọ̀rọ̀-orin yi.

Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi;
Ọlá a má ṣi lọ n’ilé ẹni’
Ẹwà a si ma ṣi l’ára ènìà

Olówó òní ńd’olòṣì b’ó d’ọ̀la
Òkun l’ọlá; òkun n’igbi ọrọ̀
Gbogbo wọn ló ńṣí lọ n’ilé ẹni;
Ṣùgbọ́n ìwà̀ ni mbá ni dé sare’e
Owó kò jẹ́ nkan fún ni,
Ìwà l’ẹwà ọmọ ènìà.

Bi o lówó bi o kò n’íwà ńkọ́?
Tani jẹ f’inú tán ẹ bá ṣ’ohun rere?
Tàbi ki o jẹ́ obìnrin rọ̀gbọ̀dọ́;
Ti o bá jìnà s’ìwà ti ẹ̀dá ńfẹ́,
Tani jẹ́ fẹ́ ọ s’ílé bi aya?
Tàbi ki o jẹ oníjìbìtì ènìà;
Bi o tilẹ̀ mọ ìwé àmọ̀dájú,
Tani jẹ́ gbé’ṣé ajé fún ọ ṣe?

Tọ́jú ìwà rẹ, ọ̀rẹ́ mi,
Ìwà kò sí, ẹ̀kọ́ dègbé;
Gbogbo ayé ni ‘nfẹ́ ‘ni t’ó jẹ́ rere.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-08-10 02:12:55. Republished by Blog Post Promoter