Yorùbá ni “Ibi ti ẹlẹ́kún ti nsun ẹkún ni aláyọ̀ gbe nyọ́”. Òwe yi fihan ohun tó nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé. Bi ọ̀pọ̀ àwọn ti ó wà ni Òkè-òkun ti nra ẹ̀bùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ ni oriṣiriṣi fún ọdún, bẹni àwọn ti kò ni owó lati ra oúnjẹ pọ ni àgbáyé. Eyi ti ó burú jù ni àwọn ti ó wà ninú ibẹ̀rù pàtàki àwọn Onígbàgbọ́ ti kò lè lọ si ile-ijọsin lati yọ ayọ̀ ọdún iranti ọjọ́ ibi Jesu nitori ibẹ̀rù àwọn oniṣẹ ibi.
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Ori bí bẹ́, kọ́ ni oògùn ori-fí fọ́”. Bawo ni pi pa èniyàn nitori kò gba ẹ̀sìn ṣe lè mú ki èrò pọ̀ si ni irú ẹ̀sìn bẹ́ ẹ̀? Òkè-Ọya ni Àriwá Nàíjírià, Boko Haram npa èniyàn pẹ̀lú ibọn àti ohun ijà ti àwọn ti ó ka iwé ṣe, bẹni wọn korira, obinrin, iwé kikà, ẹlẹ́sìn- ìgbàgbọ́ ni Òkè-Ọya àti ẹni ti ó bá takò wọn pé ohun ti wọn nṣe kò dára. Pi pa èniyàn kọ ni yio mu ki àwọn ará ilú gba ẹ̀sìn.
A ki àwọn iyá àti bàbá àwọn ọmọ obirin ilú Chibok ti wọn ji kó lọ́ ni ilé-iwé, àwọn ẹbi ti ó pàdánù ọmọ, iyàwó, ọkọ, ẹbi, ará àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ibi – Boko Haram, pé ki Ọlọrun ki ó tù wọn ninú. A fi àsikò ọdún Keresimesi mú òbi àwọn ọmọbinrin ilé-iwé Chibok ti won ji ko, lọ́kàn le, pé ki wọn ma ṣe sọ ìrètí nù, nitori “bi ẹ̀mi bá wà ìrètí nbẹ”.
ENGLISH TRANSLATION
According to Yoruba saying “As some are mourning, some are rejoicing”. This adage is apt to describe the happenings around the world. As many Oversea or in the developed World are spending huge sum for gifts and so much food for the yuletide, so also are many people in the world facing starvation as they have no money to buy food. The worst, are those living in fear particularly the Christians that cannot go to places of worship to celebrate Christmas because of fear of the terrorists. Continue reading
Originally posted 2014-12-23 21:35:53. Republished by Blog Post Promoter