“Gèlè ò dùn bi ká mọ̀ ọ́ wé, ká mọ̀ ọ́ wé, kò tó kó yẹni”: “Head tie is not as sweet as the skill of tying, having the skill of tying is not as sweet as how well it fits”

Aṣọ Yorùbá, ìró àti bùbá kò pé lai si gèlè. Gèlè oriṣiriṣi ló wà̀, a lè lo gèlè aṣọ ìbílẹ̀ bi: aṣọ òfi/òkè, àdìrẹ, tàbi ki á yọ gèlè lára aṣọ.  Ọpọlọpọ gèle ìgbàlódé wá lati òkè òkun.

Ìmúra obinrin Yorùbá kò pé lai wé gèlè, ṣùgbọ́n òwe Yorùbá ti ó ni “Gele ko dun bi ka mo we, ka mo we, ko to ko yeni”, fihan pe ki ṣe owó ti enia ná lati ra gèlè ni ó ni kó yẹni.  A lè fi ò́we yi bá awọn obinrin ti o nṣe àṣejù tabi àṣehàn, nipa ki kó owó nlá lóri àti ra gèlè lati òkè òkun. Ọ̀pọ̀ gèlè lati òkè òkun ṣòro lati wé nitorina bi enia ò bá we dáadáa, kò ni yẹni. A le fi òwe yi tún gb́ àwọn obinrin ti ó kó gèlè aṣọ-ẹbí jọ ni ìyànjú pé ki ṣe bi gèlè ṣe pọ̀ tó ló mú kó yẹni.  Ẹ jẹ́ ki á ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntún-ìwọ̀nsì.

ENGLISH LANGUAGE

Yoruba outfit (Wrapper and top) is incomplete without a Head tie making it an integral part of Yoruba dressing.  Head tie comes in various fabrics, it can be traditional woven fabric known as (aṣọ òfi/òke), traditional tie and dye cotton fabric or cutting out the head tie from the main fabric.  Many modern head tie are from imported fabric.

A typical Yoruba woman’s dressing is incomplete without the head tie, but the Yoruba proverb that said “Head tie is not as sweet as the skill of tying, having the skill of tying is not as sweet as how well it fits”, can be used to show that it is not how expensive that determines how well the head tie will fit.  Many imported head tie fabric from abroad are stiff and difficult to tie, hence without the skill of tying it right, it may not fit.  This proverb can also be used to discourage women who are fond of piling up various head ties acquired through buying of ceremonial uniform, that it is not how many but how well.  Let us do all things in moderation.

Gèlè aṣọ òkè òkun ti ìgbàlódé̀̀̀̀ – Modern imported fabric head-tie. Courtesy: @theyorubablog

Gèlè aṣọ ànkàrá – Head tie from same (cotton fabric). Courtesy: @theyorubablog

Gèlè aṣọ òfì/òkè – Head tie from traditional woven fabric.  Courtesy: @theyorubablog

Share Button

Originally posted 2015-06-26 10:30:26. Republished by Blog Post Promoter

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.