Category Archives: Yoruba Food

English words for Yoruba food, a life saver if you end up in a Nigerian restaurant and want a leg up on the menu.

Ijẹbu lo ni Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ gbogbo Yorùbá ló ni Ọ̀jọ̀jọ̀ – Water Yam Pottage is exclusive to Ijebu, fried water yam fritters belongs to all Yoruba.

Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi.

Fọ Iṣu Ewùrà kan
Bẹ ewùrà yi
Rin iṣu yi (pẹ̀lú pãnu ti a dálu lati fi rin gãri, ilá tàbi ewùrà)
Po iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé, ata gigún tàbi rẹ́ atarodo tútù, rin tàbi rẹ àlùbọ́sà si ewùrà rí-rin yi
Ti ó ba ki, fi omi diẹ si lati po gbogbo ẹ pọ
Gbe epo tàbi òróró kaná,
Bi ó bá ti gbóná, a lè fi ṣibi tàbi ọwọ́ da ewùrà ri-rin ti a ti pò pẹ̀lú èlò́ yi si inú epo to gbóná lati din
Wa kuro bi o ba ti jina.

ENGLISH TRANSLATION

Check out how to prepare Fried Water Yam Fritters on this page.

Wash the water yam,
Peel it,
Grate the water yam (with aluminium grater that can also
be used to grate Cassava, okra or water yam),
Mix with salt and seasoning, dry pepper or cut habanero,
grate or cut onions into the grated water yam,
If the grated water yam is too thick, add a little water to mix all together
Heat oil,
Cut with spoon or hand the mixed grated yam in small balls into the heated oil to fry
Remove the fried water yam fritters when cooked.

Share Button

Originally posted 2015-10-06 19:27:40. Republished by Blog Post Promoter

Ìpanu – “Kẹ́nu ma dilẹ̀ ni ti gúgúrú, gúgúrú ki ṣe oúnjẹ àjẹsùn”: Snacks – “Popcorn is eaten to keep the mouth busy, it is not an ideal night meal”.

Oúnjẹ òkèlè ni Yorùbá mọ̀ si oúnjẹ gidi.  Ni ọ̀pọ̀ igbà oúnjẹ òkèlè ni oúnjẹ àjẹsùn, ṣùgbọ́n ìpanu ni ohun amú inú dúró ni ọ̀sán.  Àwọn ìpanu bi gúgúrú àti ẹ̀pà, bọ̃li àti ẹ̀pà, gaàrí àti ẹ̀pà àti bẹ̃bẹ lọ ni Yorùbá njẹ ni ọ̀sán lati mu inu dúró ki wọn tó jẹ́ oúnjẹ alẹ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àwọn ìpanu wọnyi ni ojú iwé yi.

Bọli – Roasted Plantain.  Courtesy: @theyorubablog

Bọli – Roasted Plantain. Courtesy: @theyorubablog

ENGLISH TRANSLATIONS Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-10-31 17:33:49. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ̀gẹ́ ò lẹ́wà; lásán ló fara wé Iṣu” – “Cassava has no attraction, it only resembles yam in vain”

Ẹ̀gẹ́/Gbaguda/Pákí fi ara jọ Iṣu nitori àwọn mejeeji jẹ oúnjẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn ńkọ ebè fún lati gbin.  Wọn ma nwa wọn lati inú ebè ti wọn bá ti gbó, wọn ni eèpo ti wọn ma ḿbẹ.

Ẹ̀gẹ́/Gbaguda/Pákí ni wọn fi ńṣe gaàrí, bẹni wọn lè ló fún oriṣiriṣi oúnjẹ miran bi wọn ti lè lo iṣu, ṣùgbọ́n oúnjẹ bi iyán ati àmàlà mú iṣu gbayì ju ẹ̀gẹ́ lọ.  Fún ẹ̀kọ́ yi, ohun ti a lè fi iṣu ṣe yàtọ̀ si, iyán àti àmàlà ni a fẹ́ sọ. A lè fi iṣu din dùndú, tàbi se lati fi jẹ ẹ̀wà rirò/epo/ẹ̀fọ́ rirò/ọbẹ̀ ata, tàbi fi se àsáró́/àṣáró.

Àsè tàbi àpèjẹ Yorùbá ayé òde òni, kò pé lai si àśaró/àṣáró ni ibi àsè igbéyàwó, ìsìnkú, àjọ̀dún àti bẹ̃bẹ lọ.

ENGLISH TRANSLATION  Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-14 23:23:32. Republished by Blog Post Promoter

“Kò si ohun a nfi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe ni Ijeṣa, ẹiyẹ ló njẹ́” – Oú́njẹ ti a lè fi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe pọ – “Ijesha people have nothing to do with plantain, it is the food of the birds” – Plantain can be used for variety o meals.

Iyán ni oúnjẹ gidi fún Ijẹṣa, nitori wọn ni iṣu ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ.  Òwe àtijọ́ ni pé “Kò si ohun a nfi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe ni Ijeṣa, ẹiyẹ ló njẹ́” nitori ọ̀pọ̀ ohun ni a lè fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe, ni ayé òde òni, ṣùgbọ́n olówó ló njẹ́ nitori ó wọ́n.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ yára lati sè, fún àpẹrẹ, ká fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ din dòdò, ó ṣe dani kan jẹ ni àjẹ yó, tàbi jijẹ pẹ̀lú oúnjẹ miran bi dòdò àti ẹyin, dòdò àti ẹwa, dòdò àti irẹsi-ọlọ́bẹ̀ àsèpọ̀/irẹsi funfun.  Lí lo ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú fún àmàlà, sisè jẹ, tàbi sísun dára fún àwọn ti ó ni àrùn-àtọ̀gbẹ.  Ọmọdé fẹ́ràn dòdò.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú oúnjẹ ti a lè fi iṣu ṣe, ni a lè fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe.  Fún àpẹrẹ, ẹ ṣe àyẹ̀wò díẹ̀ ninú àwọn oúnjẹ wọnyi:

Oúnjẹ ti a lè fi iṣu ṣe Oúnjẹ ti a lè fi Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ṣe Yam related meals Plantain related meals
Iyán iṣu Iyán ọ̀gẹ̀dẹ̀ Pounded yam Pounded plantain
Àmàlà̀ iṣu Àmàlà ọ̀gẹ̀dẹ̀ tútù tàbi gbigbẹ Yam flour meal Raw plantain meal or Plantain flour meal
Iṣu sisè ọ̀gẹ̀dẹ̀ sisè Boiled yam Boiled plantain
Dùndú Dòdò Fried yam Fried plantain
Àsáró iṣu Àsáró ọ̀gẹ̀dẹ̀ Yam pottage Plantain pottage
Iṣu sísun ọ̀gẹ̀dẹ̀ sísun (Bọ̀ọ̀li) Roasted yam Roasted plantain
Iṣu lílọ̀ pẹ̀lú epo-pupa ọ̀gẹ̀dẹ̀ lílọ̀ pẹ̀lú epo-pupa Mashed yam with palm-oil Mashed plantain with palm-oil
Ìpékeré isu Ìpékeré ọ̀gẹ̀dẹ̀ Yam chips Plantain chips

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-05 09:00:14. Republished by Blog Post Promoter

Ounjẹ Yorùbá: Yoruba Food

Ẹ GBA OUNJẸ YORÙBÁ LÀ: SAVE YORÙBÁ: SAVE YORUBA FOOD

Ọpọlọpọ oriṣiriṣi ounjẹ Yorùbá nparẹ lọ, nípàtàkì larin awọn to ngbe ìlú nla.  Òwe Yorùbá ni “Ki àgbàdo to de ilẹ aye, adíyẹ njẹ, adíyẹ nmu”.  Itumo eyi nipe ki a to bẹrẹ si ra ounjẹ latokere, a nri ounjẹ ilẹ wa jẹ. Awọn to ngbe ilu nla bi ti Eko ko ri aye lati se ọpọlọpọ ounjẹ ilẹ wa, èyí ko jẹki àlejò mọ wipe Yorùbá ni oriṣiriṣi ọbẹ, ounjẹ ati ìpanu. Ni ọpọ ọdun sẹhin, irẹsi ki ṣe ounjẹ ojojumọ ṣugbọn fun awọn ọmọ igbalode, Irẹsi “Burẹdi” ati “Indomie” ti di ounjẹ.  Ọpọlọpọ ko ti ẹ fẹ jẹ ounjẹ ibilẹ bi awọn ounjẹ òkèlè: Iyán, Ẹba, Láfún ati bệbệ lọ.  Ti a ba ṣakiyesi, ọpọ ọmọ to dagba si Eko, ko mọ wipe Yorùbá ni ju ọbẹ ata ati ẹfọ/ila lọ.  Ọbẹ ata lo yá lati fi jẹ irẹsi, nitori ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyi le jẹ irẹsi lojojumọ, larọ, lọsan ati lalẹ.  Ni ìlú Èkó, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki obi tètè délé lẹhin iṣẹ ojọ wọn, ẹlo miran ti ji kuro nílé lati bi agogo mẹrinabọ lai pada sílé titi di agogo mẹwa alẹ nigbati awọn ọmọ tisùn.  Nitori èyí ọpọ òbí ko ri aye lati se ounjẹ Yorùbá.   Àìsí ina manamana dédé tun da kun ifẹ si ounjẹ pápàpá.

Ìyàlẹnu ni wipe ọpọ awọn ti ówà l’Okeokun ngbe ounjẹ Yorùbá larugẹ ju awọn ti ówà ni ilé lọ pàtàkì ni ilu nla. Oṣeṣe pe bi iná manamana ba ṣe dédé ounje Yoruba yio gbayi si, nitori awọn òbì ma le se oriṣiriṣi ounjẹ pamọ.   Ẹjọwọ ẹ maṣe jẹ ki a fi ounjẹ òkèrè dipo ounjẹ ilẹ wa, okùnfà gbèsè ni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-19 21:47:33. Republished by Blog Post Promoter

Síse Àpọ̀n – Preparing Wild Mango Seed Soup

Ẹ fọ ẹja, edé àti irú, ẹ dàápọ̀ pẹ̀lú ẹran bibọ, ẹja gbígbẹ, iyọ̀, irú, iyọ̀ igbàlódé àti omi sinú ikòkò kan. Ẹ gbe ka iná fún sisè.  Bi ẹ ti nse lọ, ẹ da epo-pupa sinú ikòkò keji.  Ẹ yọ epo díẹ̀, ki ẹ da àpọ̀n si lati yọ àpnọ̀ yi, bi ó ba ti gbónọ́ díẹ̀, ẹ da gbogbo èlò ọbẹ̀ inú ikòkò kini ni gbí-gbónọ́ sinú ikòkò keji ti epo àti àpọ̀n wa.  Ẹ ro pọ, ẹ yi iná rẹ silẹ̀ díẹ, ki ẹ ro titi yio fi jiná.  Ti ọbẹ̀ na bá ki jù, ẹ bu omi gbi-gbónọ́ díẹ si titi yio ri bi ẹ ṣe fẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-20 10:15:26. Republished by Blog Post Promoter

ẸGBẸ́́ YORÙBÁ NÍ ÌLÚỌBA: Finding Yoruba Food in the UK (Dalston Kingsland)

Yorùbá ní “Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ”,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba.  Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n.  Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ̃ bá lọ si òpópó Liverpool,  ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra.

Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba.  Nitõtọ, oúnjẹ Yorùbá bi iṣu, epo pupa, èlùbọ́, gãri, ẹ̀wà pupa, sèmó, iyán, ẹran, adìẹ tógbó, ẹja àti bẹ̃bẹ wa ni àrọ́wọ́to lãdugbo.  Ṣùgbọ́n, bí ènìà bá fẹ́ àwọn nkan bí ìgbín, panla, oriṣiriṣi ẹ̀fọ́ ìbílẹ̀, bọkọtọ̃, edé gbígbẹ àti bẹ̃bẹ lọ tí kòsí lãdugbo, á rí àwọn nkan wọnyi ra ni ọjà Dalston àti Kingsland fún àwọn ti o ngbe agbègbè Àríwá àti ọja Pekham fún àwọn ti o ngbe ni agbègbè Gũsu ni Olú Ìlúọba.

Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland.  Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-05 21:06:49. Republished by Blog Post Promoter

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa” – Plantain – “Unripe/rotten plantain is no easy snack, beating a bad behaved child to death is not an option”.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èso ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ohun ọgbin ti a lè ri ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàki ni agbègbè Okitipupa ni ipinlẹ Ondo.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ pé oriṣiriṣi, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ni à nsè fun jijẹ, nigbati ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ dára fún jijẹ bi èso lai sè.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tóbi ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ lọ.

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, ohun ọgbin ti ó bá pọ̀ ni agbègbè ni èniyàn ma njẹ, nitori ko si ọkọ̀ tàbi ohun irinna tó yá  lati kó irè oko kan lọ si ekeji.  Eleyi jẹ ki àwọn ti iṣu pọ ni ọ̀dọ̀ wọn lo iṣu lati ṣe oúnjẹ ni oriṣiriṣi ọ̀nà, àwọn ti o ni àgbàdo pupọ nlo fún onírúurú oúnjẹ ti a lè fi àgbàdo ṣe, àwọn ti ó ni ẹ̀gẹ́/gbaguda ma nlo lati ṣe oriṣiriṣi oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìyàtọ laarin iṣu ati ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni pé, wọn wa iṣu ninú ebè nigbati wọn nbẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóri igi rẹ.  Kò si iyàtọ̀ laarin Èlùbọ́ iṣu àti Èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀, ṣugbon bi a bá ro fun àmàlà, àmàlà iṣu dúdú díẹ ju èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ gbigbẹ, àmàlà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tútù kò dúdú ó pọ́n fẹ́rẹ́fẹ́.  Iṣu tútù kò ṣe e bùṣán nitori yio yún èniyàn ni ọ̀fun, nibi ti ó burú dé, bi omi ti wọn fi fọ iṣu bá ta si ni lára, yio fa ara yin yún. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá ti ó ni “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa”, ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò dùn lati jẹ ni tútù, eyi ti ó bá ti kẹ̀ naa kò ṣe é jẹ, ṣùgbọ́n ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ó pọ́n ṣe jẹ ni pi pọ́n lai sè nitori adùn rẹ.  Àti ewé àti èso ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ó wúlò fún jijẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-02 19:09:48. Republished by Blog Post Promoter

ÀWÒRÁN ÈLÒ ỌBẸ̀ YORÙBÁ – PHOTO GALLERY OF SOME YORUBA SOUP/STEW/SAUCE INGREDIENTS

Share Button

Originally posted 2013-05-03 23:19:39. Republished by Blog Post Promoter

Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó: “Before Yam becomes Pounded Yam it is pounded in a mortar”

Gẹ́gẹ́bí Ọba nínú Olórin ti ógbé àṣà àti orin Yorùbá lárugẹ lagbaaye (Ọba orin Sunny Ade) ti kọ wípé: “Kí iṣu tó di iyán a gún iṣu lódó”, òdodo ọ̀rọ̀ ni wípé a ni lati gún iṣu lódó kí ó tó di Iyán, ṣùgbọ́n fún ìrọ̀rùn àwọn tí ó ní ìfẹ́ oúnje abínibí tí ó wà ni Ìlúọba/Òkèòkun, a ò gún iṣu lódó mọ, a ro lórí iná bí ìgbà ti a ro Èlùbọ́ to di Àmàlà ni.

Ìyàtọ̀ tó wà laarin Èlùbọ́ tó di Àmàlà àti iṣu tó di Iyán tí a rò nínú ìkòkò ni wípé, Àmàlà dúdú, Iyán funfun, ṣùgbọ́n Àmàlà fẹ́lẹ́ ju Iyán lọ.  A ní lati ṣe àlàyé fún àjòjì wípeí ara iṣu ni Èlùbọ́ tó di Àmàlà ti jáde gẹ́gẹ́bi Iyán ti jáde lára Iṣu. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-03-17 09:20:09. Republished by Blog Post Promoter