Tag Archives: Yam pottage

“Ẹ̀gẹ́ ò lẹ́wà; lásán ló fara wé Iṣu” – “Cassava has no attraction, it only resembles yam in vain”

Ẹ̀gẹ́/Gbaguda/Pákí fi ara jọ Iṣu nitori àwọn mejeeji jẹ oúnjẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn ńkọ ebè fún lati gbin.  Wọn ma nwa wọn lati inú ebè ti wọn bá ti gbó, wọn ni eèpo ti wọn ma ḿbẹ.

Ẹ̀gẹ́/Gbaguda/Pákí ni wọn fi ńṣe gaàrí, bẹni wọn lè ló fún oriṣiriṣi oúnjẹ miran bi wọn ti lè lo iṣu, ṣùgbọ́n oúnjẹ bi iyán ati àmàlà mú iṣu gbayì ju ẹ̀gẹ́ lọ.  Fún ẹ̀kọ́ yi, ohun ti a lè fi iṣu ṣe yàtọ̀ si, iyán àti àmàlà ni a fẹ́ sọ. A lè fi iṣu din dùndú, tàbi se lati fi jẹ ẹ̀wà rirò/epo/ẹ̀fọ́ rirò/ọbẹ̀ ata, tàbi fi se àsáró́/àṣáró.

Àsè tàbi àpèjẹ Yorùbá ayé òde òni, kò pé lai si àśaró/àṣáró ni ibi àsè igbéyàwó, ìsìnkú, àjọ̀dún àti bẹ̃bẹ lọ.

ENGLISH TRANSLATION  Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-14 23:23:32. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn iyàwó ti ó fi ẹ̀mi òkùnkùn pa iyá-ọkọ: Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni” – The story of how a daughter-in-law killed her mother-in-law in mysterious circumstance – We can only be sure of who we love, but not sure of who loves us”

Ìtàn ti ó wọ́pọ̀ ni, bi iyá-ọkọ ti burú lai ri ìtàn iyá-ọkọ ti ó dára sọ.  Eyi dákún àṣà burúkú ti ó gbòde láyé òde òni, nipa àwọn ọmọge ti ó ti tó wọ ilé-ọkọ tàbi obinrin àfẹ́sọ́nà ma a sọ pé àwọn ò fẹ́ ri iyá-ọkọ tàbi ki iyá-ọkọ ti kú ki àwọn tó délé.

Ni ayé àtijọ́, agbègbè kan na a ni ẹbi má ngbé – bàbá-àgbà, iyá-àgbà, bàbá, iyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, iyàwó àgbà, iyàwó kékeré, ìyàwó-ọmọ, àwọn ọmọ àti ọmọ-mọ.  Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀ kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ, ẹbi ti fúnká si ilú nlá àti òkè-òkun nitori iṣẹ́ ajé àti iṣẹ́-ijọba.

Ni ọ̀pọ̀ ọdún sẹhin, iyá kan wà ti a o pe orúkọ rẹ ni Tanimọ̀la ninú ìtàn yi.  Ó bi ọmọ ọkùnrin meje lai bi obinrin. Kékeré ni àwọn ọmọ rẹ wà nigbati ọkọ rẹ kú.  Tanimọ̀la fi ìṣẹ́ àti ìyà tọ́ àwọn ọmọ rẹ, gbogbo àwọn ọkùnrin na a si yàn wọn yanjú.  Nigbati wọn bẹ̀rẹ̀ si fẹ́ ìyàwó, inú rẹ dùn púpọ̀ pé Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ si dá obinrin ti ohun kò bi padà fún ohun.   Ó fẹ́ràn àwọn ìyàwó ọmọ rẹ gidigidi ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ rẹ  kó lọ si ilú miran pẹ̀lú ìyàwó wọn nitori iṣẹ́.  Àbi-gbẹhin rẹ nikan ni kò kúrò ni ilé nitori ohun ló bójú tó oko àti ilé ti bàbá wọn fi silẹ.  Nigbati ó fẹ ìyàwó wálé, inú iyá dùn pé ohun yio ri ẹni bá gbé.  Ìyàwó yi lẹ́wà, o si ni ọ̀yàyà, eyi tún jẹ́ ki iyá-ọkọ rẹ fẹ́ràn si gidigidi.

Yorùbá ni “Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni”.  Tanimọ̀la kò mọ̀ pé àjẹ́ ni ìyàwó-ọmọ ti ohun fẹ́ràn, ti wọn jọ ngbé yi.  Bi Tanimọ̀la bá se oúnjẹ, ohun pẹ̀lú ọmọ àti ìyàwó-ọmọ rẹ ni wọn jọ njẹ ẹ.  Bi ìyàwó bá se oúnjẹ, á bu ti iyá-ọkọ rẹ.  Kò si ìjá tàbi asọ̀ laarin wọn ti ó lè jẹ ki iyá funra.

Yam pottage

àsáró-iṣu – Yam Pottage. Courtesy: @theyorubablog

Yorùbá gbà pé ohun burúkú ni ki enia jẹun lójú orun.  Ni ọjọ́ kan, iyá ké lati ojú orun ni bi agogo mẹrin ìdájí òwúrọ̀, pe ìyàwó-ọmọ ohun ti fún ohun ni oúnjẹ jẹ ni ojú orun.  Ìyàwó-ọmọ rẹ kò sẹ́, bẹni kò sọ nkan kan.  Ọkọ rẹ kò gba iyá rẹ gbọ.  Lati igbà ti iyá ti ké pé ohun jẹ àsáró-iṣu ti ìyàwó-ọmọ ohun gbé fún òhun jẹ lójú orun ni inú rirun ti bẹ̀rẹ̀ fún iyá.  Inú rirun yi pọ̀ tó bẹ gẹ ẹ ti wọn fi gbé Tanimọ̀la kúrò ni ilé fún ìtọ́jú.  Wọn gbiyànjú titi, kò rọrùn, nitori eyi, Tanimọ̀la ni ki wọn gbé ohun padà lọ si ilé ki ohun lọ kú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-07 17:41:39. Republished by Blog Post Promoter