Tag Archives: meals

Ounjẹ Yorùbá: Yoruba Food

Ẹ GBA OUNJẸ YORÙBÁ LÀ: SAVE YORÙBÁ: SAVE YORUBA FOOD

Ọpọlọpọ oriṣiriṣi ounjẹ Yorùbá nparẹ lọ, nípàtàkì larin awọn to ngbe ìlú nla.  Òwe Yorùbá ni “Ki àgbàdo to de ilẹ aye, adíyẹ njẹ, adíyẹ nmu”.  Itumo eyi nipe ki a to bẹrẹ si ra ounjẹ latokere, a nri ounjẹ ilẹ wa jẹ. Awọn to ngbe ilu nla bi ti Eko ko ri aye lati se ọpọlọpọ ounjẹ ilẹ wa, èyí ko jẹki àlejò mọ wipe Yorùbá ni oriṣiriṣi ọbẹ, ounjẹ ati ìpanu. Ni ọpọ ọdun sẹhin, irẹsi ki ṣe ounjẹ ojojumọ ṣugbọn fun awọn ọmọ igbalode, Irẹsi “Burẹdi” ati “Indomie” ti di ounjẹ.  Ọpọlọpọ ko ti ẹ fẹ jẹ ounjẹ ibilẹ bi awọn ounjẹ òkèlè: Iyán, Ẹba, Láfún ati bệbệ lọ.  Ti a ba ṣakiyesi, ọpọ ọmọ to dagba si Eko, ko mọ wipe Yorùbá ni ju ọbẹ ata ati ẹfọ/ila lọ.  Ọbẹ ata lo yá lati fi jẹ irẹsi, nitori ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyi le jẹ irẹsi lojojumọ, larọ, lọsan ati lalẹ.  Ni ìlú Èkó, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki obi tètè délé lẹhin iṣẹ ojọ wọn, ẹlo miran ti ji kuro nílé lati bi agogo mẹrinabọ lai pada sílé titi di agogo mẹwa alẹ nigbati awọn ọmọ tisùn.  Nitori èyí ọpọ òbí ko ri aye lati se ounjẹ Yorùbá.   Àìsí ina manamana dédé tun da kun ifẹ si ounjẹ pápàpá.

Ìyàlẹnu ni wipe ọpọ awọn ti ówà l’Okeokun ngbe ounjẹ Yorùbá larugẹ ju awọn ti ówà ni ilé lọ pàtàkì ni ilu nla. Oṣeṣe pe bi iná manamana ba ṣe dédé ounje Yoruba yio gbayi si, nitori awọn òbì ma le se oriṣiriṣi ounjẹ pamọ.   Ẹjọwọ ẹ maṣe jẹ ki a fi ounjẹ òkèrè dipo ounjẹ ilẹ wa, okùnfà gbèsè ni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-19 21:47:33. Republished by Blog Post Promoter