Tag Archives: Yoruba markets in diaspora

ẸGBẸ́́ YORÙBÁ NÍ ÌLÚỌBA: Finding Yoruba Food in the UK (Dalston Kingsland)

Yorùbá ní “Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ”,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba.  Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n.  Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ̃ bá lọ si òpópó Liverpool,  ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra.

Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba.  Nitõtọ, oúnjẹ Yorùbá bi iṣu, epo pupa, èlùbọ́, gãri, ẹ̀wà pupa, sèmó, iyán, ẹran, adìẹ tógbó, ẹja àti bẹ̃bẹ wa ni àrọ́wọ́to lãdugbo.  Ṣùgbọ́n, bí ènìà bá fẹ́ àwọn nkan bí ìgbín, panla, oriṣiriṣi ẹ̀fọ́ ìbílẹ̀, bọkọtọ̃, edé gbígbẹ àti bẹ̃bẹ lọ tí kòsí lãdugbo, á rí àwọn nkan wọnyi ra ni ọjà Dalston àti Kingsland fún àwọn ti o ngbe agbègbè Àríwá àti ọja Pekham fún àwọn ti o ngbe ni agbègbè Gũsu ni Olú Ìlúọba.

Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland.  Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-05 21:06:49. Republished by Blog Post Promoter