Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

Ọdún tuntun káàbọ̀ – Ẹgbà-lé-mẹ́rìnlà – Welcoming the New Year – 2014

Ẹ kú ọdún o – Season Greetings. Courtesy: @theyorubablog

kú dún

Festive Greetings

 kú ìyè dún

Greetings on the return of the year

dún á ya abo

Prosperous New Year  

À èyí ṣe àmọ́dún o.                                                  Better years ahead

View more presentations or Upload your own.
Share Button

Originally posted 2013-12-31 23:11:39. Republished by Blog Post Promoter

“Àjẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́” – Ìkìlọ̀: ẹ jẹun díẹ̀ – Ẹ kú ọdún o, à ṣèyí ṣè àmọ́dún o – “Eating without looking back, is the cause of disgrace for the Pig” – Caution: eat moderately during the Yuletide.

Iyán àti ẹ̀fọ́ rírò – Pounded Yam and mixed stewed vegetable soup. Courtesy: @theyorubablog

Ni asiko ọdún, pataki, asiko ọdún iranti ọjọ ibi Jesu, bi oúnjẹ ti pọ̀ tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti o wa ni Òkè-okun àti àwọn díẹ̀ ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, bẹ̃ ni o ṣọ̀wọ́n tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé.

Ò̀we Yorùbá ni, “Ọ̀kánjúwà-á bu òkèlè, ojú rẹ à lami”.  Bi enia ò bá ni ọ̀kánjúwà, á mọ irú òkèlè ti ó lè gba ọ̀nà ọ̀fun rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀kánjúwa á bu  lai ronu pe òkèlè ti ó ju ọ̀nà ọ̀fun lọ á fa ẹkún.  Òwe yi bá àwọn ti ó ṣe jura wọn lọ tàbi ki ó jẹ igbèsè lati ra ẹ̀bùn, oúnjẹ ti wọn ò ni jẹ tán, aṣọ, bàtà àti oriṣiriṣi ti wọn ri ni ìpolówó lai mọ̀ pé ọdún á ré kọjá.  Lẹhin ọdún, ọ̀pọ̀ a fi igbèsè bẹ̀rẹ̀ ọdún titun,  eyi a fa ìrora àti ọ̀rọ̀ ti ó ṣòro si ayé irú ẹni bẹ̃.

Àjẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ – Eating without looking back, is the cause of disgrace for the Pig. Courtesy: @theyorubablog

Yorùbá ni “Ájẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ”, nitori eyi ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin ti ẹ ni ìfẹ́ àti gbé èdè àti àṣà̀̀ Yorùbá lárugẹ, pe ki ẹ ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Ẹ kú ọdún o, ọdún titun ti o ḿbọ̀ lọ́nà á ya abo fún gbogbo wa.

ENGLISH TRANSLATION

During this yuletide, particularly during the remembrance of Jesus’ birth – Christmas celebration, as there is abundance of food for many people in the developed world and some in Africa so also is scarcity for many others all over the world.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-12-24 23:01:10. Republished by Blog Post Promoter

Bi ọmọ ò jọ ṣòkòtò á jọ kíjìpá: Ibáṣe pọ Idilé Yorùbá – If a child does not take after the father, he/she should take after the mother – Yoruba Family Relationship

Bàbá, iyá àti ọmọ ni wọn mọ si Idilé ni Òkè-òkun ṣùgbọ́n ni ilẹ̀ Yorùbá kò ri bẹ́ ẹ̀, nitori ẹbi Eg bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹni, ọmọ, ọkọ àti aya wọn ni a mọ̀ si Idilé.  Yorùbá fẹ́ràn lati má a bọ̀wọ̀ fún àgbà nitori eyi, ẹni ti ó bá ju Bàbá àti Ìyá ẹni lọ Bàbá tàbi Ìyá la n pè é, wọn ki pe àgbà ni orúko nitori eyi, wọn lè fi orúkọ ọmọ pe àgbà tàbi ki wọn lo orúkọ apejuwe (bi Bàbá Èkó, Iyá Ìbàdàn).  Ẹ ṣe à yẹ̀ wò àlàyé àti pi pè ibáṣepọ̀ idilé ni ojú iwé yi.

The Western family is made up of, father, mother and their children but this is not so, as Yoruba family on the other hand is made up of extended family that includes; father, mother, children, half/full brothers/sisters, step children, cousins, aunties, uncles, maternal and paternal grandparents.  Yoruba people love respecting the elders, as a result, uncles and aunties that are older than one’s parents are called ‘Father’ or ‘Mother’ and elders are not called by their names as they are either called by their children’s name or by description (example Lagos Father, Ibadan Mother)  Check the explanation and prononciation below.

Share Button

Originally posted 2015-10-27 22:57:10. Republished by Blog Post Promoter

Òṣèlú Ẹ Gbé Èdè Yorùbá Lárugẹ: Politicians – Promote Yoruba Language

Yoruba, other Nigerian languages on the verge of extinction, Prof Akinwunmi Isola warns - News Sunday

Yoruba, other Nigerian languages on the verge of extinction, Prof Akinwunmi Isola warns

Nínú ìwé ìròyìn “Vanguard”, ti ọjọ́ Àìkú, oṣù kẹta, ọjọ́ , ọdún kẹrinlélógún, Ẹgbaalémétàlá, Olùkọ́ àgbà ti Èdè ati Àṣà, Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, kébòsí wípé èdè Yorùbá àti èdè abínibí miran le parun ti a ko bá kíyèsára.  Ìkìlọ̀ yí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan Olùkọ̀wé yi lati gbé èdè àti Yorùbá ga lórí ẹ̀rọ Ayélujára.

Àwọn Òṣèlú tó yẹ ki wọn gbé èdè ìlú wọn lárugẹ n dá kún pí pa èdè rẹ.  Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ko fi èdè na ṣe nkankan ni Ilé-òsèlú, wọn o sọ́, wọn ò kọ́, wọn ò ká.  Àwọn Òṣèlú ayé àtijọ́ bi Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Olóyè Ládòkè Akíntọlá, àti bẹ̃bẹ lọ gbé èdè wọn lárugẹ bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wípé wọn kàwé wọn gboyè rẹpẹtẹ. Yorùbá ní “Àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́”.  Ó yẹ ki àwọn àgbà kọ́ ọmọ lédè, kí à si gba àwọn ọmọ wa níyànjú wípé sí sọ èdè abínibí kò dá ìwè kíkà dúró ó fi kún ìmọ̀ ni.  Ó ṣeni lãnu wípé àkàkù ìwé ló pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, wọn ò gbọ́ èdè Yorùbá wọn ò dẹ̀ tún gbọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì.

Yorùbá ní “Ẹ̀bẹ̀ la mbẹ òṣìkà pé kí ó tú ìlú rẹ ṣe”, A bẹ àwọn Òṣèlú́ Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀̀yọ́, lati ṣe òfin mí mú Kíkọ àti Kíkà èdè Yorùbá múlẹ̀ ní gbogbo ilé ìwé, ní pàtàkì ní ilé-ìwé alakọbẹrẹ ilẹ̀ Yorùbá nitori ki èdè Yorùbá ma ba a parẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-03-26 21:44:54. Republished by Blog Post Promoter

“Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” – “Not all that glitters is Gold”

Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàki fún ohun ẹ̀ṣọ́.  Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara.    Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi.  Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe; ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse; kò ki léwó.

Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà”, bẹni ki ṣe gbogbo  èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò.  Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku.  Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni.  Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni.

A lè fi òwe “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ.  Àfarawé léwu, nitori ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-30 22:55:23. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri” – Ìtàn bi imú Erin ti di gigùn: “Whoever pry unnecessarily, will witness an offensive sight” – The story of how the Elephant’s nose became a trunk.

Ni igbà kan ri, imú Erin dàbi ti àwọn ẹranko tó kù ni, ṣùgbọ́n Erin fi aigbọ tara ẹni, di o ni imú gigùn.  Gbogbo nkan tó nlọ ni ayé àwọn ẹranko yoku ni Erin fẹ tọpinpin rẹ.

Yorùbá ni “Ẹni bá wá iwa-kuwa, ojú rẹ á ri irikuri”.  Ni ọjọ́ kan, gẹgẹbi iṣe Erin, ó ri ihò dúdú kan, ó ti imú bọ lati tọpinpin lai mọ pe ibẹ̀ ni Òjòlá (Ejò nla ti o ngbe ẹranko tàbi enia mi) fi ṣe ibùgbé.  Bi o ti gbé imú si inú ihò yi ni Òjòlá fa ni imú lati gbe mì.  Erin pariwo lati tú ara rẹ̀ silẹ̀ ṣùgbọ́n Òjòlá kò tu imú rẹ silẹ̀.  Ìyàwó Erin gbọ́ igbe ọkọ rẹ, o fa ni irù lati gbiyànjú ki ó tú ọkọ rẹ silẹ̀.  Bi àwọn mejeeji ti  ṣe ́gbìyànjú tó, ni imú Erin bẹ̀rẹ̀ si gùn si titi o fi já mọ́ Òjòlá lẹ́nu.

Imú Erin di gigùn – Elephant’s nose became a trunk. Courtesy: @theyorubablog.com

Imú gigùn yi dá itiju fún Erin, ó fi ara pamọ́ titi, ṣùgbọ́n nigbati àwọn ẹranko ti ó kù ri imú rẹ gigun wọn bẹ̀rẹ̀ si ṣe ilara irú imú bẹ.  Èébú dọlá, ohun itiju di ohun ilara.

Ọ̀bọ jẹ ẹranko ti ó féràn àti ma ṣe àfarawé gbogbo ẹranko yoku.   Ni ọjọ́ kan, Ọ̀bọ lọ si ibi ihò dúdú ti Erin lọ lati ṣe ohun ti Erin ṣe.  Yorùbá ni “Ohun ojú wa, lojú nri”.  Bi ó ti gbé imú si inú ihò dúdú yi ni Òjòlá gbe mi, ó si kú.  Àwọn ẹranko tó kù fi ti Ọ̀bọ kọ́gbọ́n, nitori eyi ni o fi jẹ imú Erin nikan ló gùn ni gbogbo ẹranko.

Ẹkọ pataki ninu itàn yi ni pe “àfarawé” lè fa àkóbá bi: ikú òjijì, àdánù owó àti ara, ẹ̀wọ̀n àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

ENGLISH TRANSLATION

A long time ago, the Elephant’s nose was just normal like that of other animals, but the Elephant for not minding his business became a long nose/hand animal.  The Elephant is always prying at all other animals’ matters.  Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-06-12 09:30:01. Republished by Blog Post Promoter

“Ilé làbọ̀ simi oko, ṣùgbọ́n bi ilé bá sanni àwọ̀ là nwò”: “Home is for rest on return from the farm, but the convenience of the home is a reflection on the skin”

sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ - Lagos Traffic jam.  Courtesy:  @theyorubablog

sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ – Lagos Traffic jam. Courtesy: @theyorubablog

Gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, pataki àwọn ti o fi ìfẹ́ tẹ̀ lé  àkọ-sílẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá́  lárugẹ lóri ẹ̀rọ ayélujára, mo jẹ yin ni àlàyé ohun ti ojú ri lẹhin àbọ̀ oko.  Ẹ o ṣe akiyesi wípé, ìwé kikọ wa din kù diẹ nitori adarí ìwé lọ bẹ ilé wò fún ìgbà diẹ.  Ni gbogbo àsìkò ti adarí ìwé fi wa ni ilé (Nigeria), ìṣòro nla ni lati lè kọ ìwé lori ayélujára nitori dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná.

Lagos

Lagos

Ó ṣeni lãnu pé “oko” ninu àlàyé yi (òkè-òkun/ìlú-oyinbo) sàn ju “ilé” Èkó.  Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, “kàkà ki ewé àgbọn dẹ, koko ló tún nle si”.  Ni totọ, àwọn Oní-ṣòwò ni orílẹ̀ èdè Nigeria ǹgbìyànjú, nitori kò rọrùn lati ṣòwò ni ìlú ti ohun amáyé-dẹrùn ti ìgbàlódé bi iná mona-mona, òpópónà tó dára, omi mimu, àbò, àti bẹbẹ̃ lọ, kò ti ṣe dẽde.  A ṣe akiyesi pé nkan wọ́n ni ilé ju oko lọ, pataki ìnáwó lórí ounjẹ, ẹrọ iná mọ̀nà-mọ́ná àti ọkọ̀ wíwọ̀.  Ai si iná, ariwo ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná, fèrè ọkọ̀ àti sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki akọ̀we yi gbádùn ilé bi oko.

A lè sọ wípé àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ngbiyanju, ṣùgbọ́n “omi pọ̀ ju ọkà lọ”.  Àyè iṣẹ́ ti ó yẹ ki Ìjọba àpapọ̀ ṣe ti wọn kò ṣe ńfa ìnira fún ará ìlú.  “Ẹ̀bẹ̀ là ńbẹ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe”, nitori eyi, a bẹ Ìjọba àti àwọn Gómìnà pé ki wọn sowọ́ pọ̀ lati tú orílẹ̀ èdè ṣe ni pataki ìpèsè ohun amáyé-dẹrùn.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-11-15 21:57:48. Republished by Blog Post Promoter

“Ọ̀run nyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan – Ayé Móoru” – “Heaven is collapsing, is not a problem peculiar to one person – Global Warming”

Ọ̀run nyabọ̀ – Nature’s fury

Ọ̀run nyabọ̀ – Nature’s fury

Ìbẹ̀rù tó gbòde ayé òde òni ni pé “Ayé Móoru”, nitori iṣẹ̀lẹ̀ ti o nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé bi òjò àrọ̀ irọ̀ dá ni ilú kan, ilẹ̀-riru ni òmìràn, ọ̀gbẹlẹ̀, omíyalé, ijà iná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Eleyi dá ìbẹ̀rù silẹ̀ ni àgbáyé pàtàki ni àwọn ilú Òkè-Òkun bi Àmẹ́ríkà ti ó ka àwọn iṣẹ̀lẹ̀ wọnyi si àfọwọ́fà ọmọ ẹda.  Wọn kilọ̀ pé bi wọn kò bá wá nkan ṣe si Ayé Móoru yi, ayé yio parẹ́.

Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé “Ọ̀run nyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan”, ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri amin pé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn.  Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ ni tootọ.   Elòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré.  Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wí pé àwọn sá fún.  Fún àpẹrẹ, nigbati iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹwa sẹhin.  Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.

Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wí pé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó “kú sílẹ̀ de ikú”. Bi èniyàn bẹ̀rù á kú, bi kò bẹ̀rù á kú, nitori gẹ́gẹ́ bi itàn àdáyébá, gbogbo ohun ti ó nṣẹlẹ̀ láyé òde òni ló ti ṣẹlẹ̀ ri.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-19 08:30:59. Republished by Blog Post Promoter

“Ìfura loògùn àgbà, àgbà ti kò sọnú, á sọnù”: “Suspicion is the medicine of the elder, an unthoughtful elder will be lost”

Ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni ó lè fún àgbà ni ọgbọ́n àti òye lati lè sọnú.  Oriṣiriṣi ọ̀nà ni a lè fi gbà kọ́ ẹ̀kọ́, ṣugbọn ni ayé òde òni, ohun gbogbo ni a lè ri kọ́ ni orí ayélujára.

Bi ayélujára ti sọ ayé di ẹ̀rọ̀ tó bẹ̃ ló tún bayé jẹ́ si.  Àwọn ọmọ ìgbàlódé mọ èlò ẹ̀rọ ayélujára ju àgbàlagbà lọ.  Àgbà ti kò bá ni ìfura, ki o si kọ ẹ̀kọ́ lilo ẹ̀rọ ayélujára á sọnù.

Ki ṣe orí ẹ̀rọ ayélujára nikan ni ó ti yẹ ki àgbà ma fura ki o ma ba sọnù.  Àgbà ni lati ṣe akiyesi àwọn ohun wọnyi: ṣọ́ra fún àwọn Òṣèlú nipa ṣi ṣọ́ ìbò ti a di dáradára;  owó ni ilé ifowó-pamọ́; wi wo àyíká fún amin ewu ti o le wa ni àyíká; ṣi ṣọ irú ounjẹ ti o yẹ ki a jẹ; àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-09 10:30:49. Republished by Blog Post Promoter

Àgbo Ibà – Malaria Herbal Decoction

Àgbo Ibà – Malaria Herbal Decoction

Ibà jẹ ikan ninú àwọn àrùn tó pa àwọn èniyàn jù ni àwọn orilẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.  Yorùbá ti ńlo ewé àti egbò igi ti ó wà ni oko àti àyiká ilé lati ṣe àgbo fún itọ́jú ibà ki Òyinbó tó gba ilú tó sọ ewé àti egbò igi di hóró oògùn ibà.

English Translation: malaria is one of the biggest killers of people all over Africa. Yoruba people have been using herbs and tree barks that are found all over Yoruba land to make herbal concoctions or herbal remedies to care for malaria long before Europeans arrived in Africa and turned the leaves and barks into malaria medicines.

Share Button

Originally posted 2020-09-08 02:39:18. Republished by Blog Post Promoter