Author Archives: Bim A

About Bim A

Writer, editor and creator of theyorubablog. Keeping the Yoruba language alive.

“Àdúrà ló ńgbà, agbára ki gbà” – ohun èlò fún àdúrà ìbílẹ̀: “It is prayer that is answered, power is never answered” – Items used for traditional prayer.

Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Yorùbá ti ni ìgbàgbọ́ ninu ki a gba àdúrà nitori pe ohun gbogbo fẹ́ àdúrà “Ohun ti o dára fẹ́ àdúrà ki ó bà lé dára si, eyi ti kò dára na fẹ́ àdúrà ki ó bà lé yanjú”.  Bi àwọn “Ìgbàgbọ́ tàbi ilé-àdúrà aláṣọ funfun” ti ńlo “Àbẹ́là” gba àdúrà a ni Yorùbá ma ńlo àwọn ohun ọ̀gbin bi: Orógbó, Obì, Atare àti Oyin nibi ètò ìgbéyàwó, ìsọmọ lórúkọ, ìṣílé, àjọ̀dún àti bẹ̃bẹ lọ. Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi bi Yorùbá ti ńlo wọn fún àdúrà:

Orógbó: Bitter-kola

Orógbó: Bitter-kola

Orógbó: Bitter-kola. Courtesy: @theyorubablog

Ọpọlọpọ ìgbà ni a ki mọ ẹni ti o gbin igi orógbó nitori igi rẹ lè pé igba ọdún, nitori eyi, Yorùbá ma ńlo lati gbàdúrà nibi ṣiṣe fún ẹmi gigun pe “wa gbó wa tọ́”.

 

 

 

 

Obì: Kola-nut

Obì: Kola-nut

Obì: Kola-nut. Courtesy: @theyorubablog

Obì wulo fún ọrọ ajé.  Yorùbá ni “ọdọdún la nri orógbó, ọdọdún la nri obì lori atẹ” nitori eyi wọn a lo fún àdúrà pe “obì a bi iku, àti pé ẹni na a ṣe àmọ́dún”.

Atare: Guinea/Maleguetta/Alligator pepper

Atare: Guinea/Maleguetta/Alligator pepper

Atare: Guinea/Maleguetta/Alligator pepper. Courtesy: @theyorubablog

Ọmọ/èso pọ ninu atare, nitori eyi wọn a fi gba àdúrà, pataki fún ẹni ti o nṣe ìgbéyàwó pe “ilé wọn á kún fún ọmọ” tàbi nibi ìsọmọ lórúkọ pe “bi wọn ṣe bi ọmọ na, ilé tirẹ̀ na á kún fún ọmọ”.

 

 

 

Oyin: Honey

Oyin - Honey

Oyin – Honey. Courtesy: @theyorubablog

Òwe Yorùbá ni “Dídùn là ḿbá láfárá oyin”, nitori eyi wọn a lo oyin lati gba àdúrà nibi ìgbéyàwó, ìsọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku pe ayé ẹni ti o nṣe nkan á dùn bi oyin.

 

 

 

 

ENGLISH TRANSLATION

Since creation, Yoruba people had always believed in praying because all things require prayer “What is good require prayer for sustenance, what is bad requires prayer for solution”.  As the “Christians or the white garment Churches” use “Candles” for praying, so do Yoruba people use agricultural produce such as: Bitter-kola, Kola-nut, Alligator pepper and Honey to pray during traditional marriage, naming ceremony, house warming, anniversaries etc.  Let us note some ways Yoruba people use these items for prayer:

Most often the planter of bitter-kola tree is unknown because the tree can live for two hundred years, hence Yoruba used this to pray during ceremony for long live “the celebrant will long and old”.

Kola-nut is useful as cash crop.  Yoruba adage said “Bitter-kola is found yearly, kola-nut is found annually on market display”, as a result of this adage it is believed and reflected in the prayer that said “kola-nut will push away death and the person will live to see another year”.

Alligator pepper often carry many seeds, hence it used during prayer, particularly during traditional marriage that “the couple’s home will be full of children” or during naming ceremony that “as the baby was born so also his/her house will be full children”.

Yoruba Proverb as translated by Oyekan Owomoyela “One finds only sweetness in a honey comb”.  This can be applied to the prayer that “The celebrant’s affairs will always be characterized by pleasantness”.

Share Button

Originally posted 2013-12-13 21:05:33. Republished by Blog Post Promoter

“Bi eyi ò ṣe, omiran yio ṣe – bi Ọlọrun o pani, ẹnikan ò lè pani”: If this has not happened, something else would – If God does not kill, no one can kill”.

Ìtàn yi dá lori Bàbá ti aládũgbò mọ si “Bàbá Beyioṣe”.  Bàbá yi jẹ onígbàgbọ́, ti ki ja tabi ṣe ãpọn.  O bi ọmọ mẹta ti wọn jọ ngbe nitori iyawo rẹ ti kú. Ni ilé ti o ngbe, ó fi ifẹ hàn si àwọn olùbágbé àti aládũgbò.  Bi Bàbá yi bá fẹ́ la ija yio sọ pé “ẹ má jà, a ò mọ ohun ti Ọlọrun fi ohun ti ẹ ńjà lé lori ṣe, nitori na ‘bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe’.

Ni ọjọ́ kan, ọmọ kú fún obinrin olùbágbélé Bàbá Beyioṣe.  Bàbá tún dé ọdọ obinrin yi lati tu ninu, o sọ fún pe “Bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – ẹ pẹ̀lẹ́, a o mọ̀ ohun ti Ọlọrun fi ṣe”.  Ọrọ ìtùnú yi bi ẹniti o ṣe ọ̀fọ̀ ọmọ ti ó kú ninu tó bẹ gẹ ti o fi gbèrò pe ohun yio dán ìgbàgbọ́ Bàbá Beyioṣe wo nipa wiwo ohun ti yio ṣe ti ọmọ ti rẹ nã bá kú.

SAM_1019

Ogi – Corn starch. Courtesy: @theyorubablog

Ogi – Corn pap. Courtesy: @theyorubablog

Ni òwúrọ̀ ọjọ́ kan, Bàbá Beyioṣe, sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé ohun fẹ ji dé ibikan.  Ó ṣe ètò pé ki wọn mu ògì àti àkàrà ni òwúrọ̀ ọjọ́ na.  Àwọn ọmọ ji, wọn lọ si àrò, wọn po ògì lai mọ pe, obinrin ti ọmọ rẹ ku ti bu májèlé si ògì yi.  Àwọn ọmọ gbé ògì wọlé ṣùgbọ́n wọn dúró de ikan ninu wọn ti ó lọ ra àkàrà.  Nigbati ẹni ti ó lọ ra àkàrà de, ẹ̀gbọ́n àgbà pin àkàrà ṣùgbọ́n ija bẹ silẹ nitori ẹni ti o pin akara ko pin daradara.  Nibi ti wọn ti ńja, ògì ti o jẹ ounjẹ àárọ̀ àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe dànù.  Ori igbe ògì ti ó dànù ni àwọn ọmọ wa nigbati Bàbá Beyioṣe wọlé.  Gẹ́gẹ́ bi iṣe rẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ pé “ẹ má jà, bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – a o mọ ohun ti Ọlọrun fi ṣe”.

Obinrin ti o fi májèlé si ògì, ti o reti ki àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe ó kú, ba jade nigbati ó gbọ́ ohun ti o sọ lati tu àwọn ọmọ rẹ ninu.  Ó jẹ́wọ́ pe nitotọ, onígbàgbọ́ ni Bàbá Beyioṣe nitori ohun ti ohun ṣe, ó wá tọrọ idariji.  Bàbá Beyioṣe dariji, ó fún àwọn ọmọ lówó lati ra ounjẹ miran.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-11-29 23:33:23. Republished by Blog Post Promoter

Ìtàn Yorùbá bi Àdán ti di “Ko ṣeku, kò ṣẹyẹ” – Yoruba Folklore on how the Bat became “Neither Rat nor Bird”

Adan - Flying Bat

Àdán fò lọ bá ẹyẹ – Bat flew to join the birds @theyorubablog

Ìtàn sọ wí pé eku ni àdán tẹ́lẹ̀ ki ìjà nla tó bẹ́ sílẹ̀ laarin eku àti ẹyẹ.  Àdán rò wípé àwọn ẹyẹ fẹ́ bori, nitorina o fo lati lọ darapọ̀ mọ́ ẹyẹ lati dojú ìjà kọ àwọn ẹbi rẹ eku.

Eku àti ẹyẹ bínú si àdàn nitori ìwà àgàbàgebè ti ó hu yi, wọ́n pinu lati parapọ̀ lati dojú ìjà kọ àdán.  Nitori ìdí èyí ni àdán ṣe bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ lati fi òkùnkùn bora ni ọ̀sán fún eku àti ẹyẹ títí  di òní.

A lè fi ìtàn yi wé àwọn Òṣèlú tó nsa lati ẹgbẹ́ kan si ekeji nitori ipò̀ ati agbára lati kó owó ìlú jẹ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, wọ́n ma “lé eku meji pa òfo” ni.  Ọkùnrin ti o ni ìyàwó kan, ni àlè sita ma fara pamọ́ lati lọ sí ọ̀dọ̀ obìnrin keji ti wọ́n rò wípé́ á fún wọn ní ìgbádùn.  Nígbàtí ìyàwó ilé bá gbọ́, wọn a pa òfo lọdọ ìyàwó ilé, wọn a tún tẹ́ lọ́dọ̀ àlè.

Ẹ̀kọ́ ìtàn yí ni wípé iyè meji kò dara, ọ̀dalẹ̀ ma mba ilẹ̀ lọ ni, nitorina, ojúkòkòrò kò lérè.

ENGLISH TRANSLATION

According to Yoruba folklore, the bat was once a rat, until a great fight broke out between the rats and the birds.  Sensing that birds might win the fight, some of the rats became bats, flying to join the birds against their rat kindred. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-11 09:20:28. Republished by Blog Post Promoter

“Ẹ jáwọ́ lápọ̀n ti kò yọ̀, ẹ lọ dá omi ilá kaná” – “Restrain from pursuing non-profitable venture and seek re-direction.

Ọbẹ̀ àpọ̀n jẹ́ ọbẹ̀ yíyọ̀ bi ọbẹ̀ ilá, ṣùgbọ́n fún ẹni ti kò bá mọ̃ se, kò ni yọ̀.  Ọbẹ̀ ti enia lè yára sè ju ọbẹ̀ ilá ni, nitori bi a bá ni àpọ̀n kíkù nile, a din àkókò ti ó yẹ ki enia fi rẹ́ ilá kù.  Ọbẹ̀ ti a lè fi owó díẹ̀ sè ni.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Ẹ jáwọ́ lápọ̀n ti kò yọ̀, ẹ lọ dá omi ilá kaná” jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú fún ẹni ti ó ba ńṣe iṣẹ́ ti kò ni èrè tàbi ilọsiwájú, pé ki irú ẹni bẹ gbiyànjú àti ṣe iṣẹ́ miran ki ó má ba fi àkókò ṣòfò.  Ẹ yẹ èlò àti sise ọbẹ̀ àpọ̀n ni ojú iwé yi.

Èlò fún ikòkò Ọbẹ̀ Àpọ̀n: Ingredients for the wild-mango seed soup

Epo-pupa            – Ṣibi ijẹun mẹfa                              Palm Oil – 6 Table Spoons

Ata-gigún           – Ṣibi ijẹun kan                                 Ground Pepper – 1 Table Spoon

Iyọ̀                          – Ṣibi ijẹun kékeré kan                 Salt – 1 Teaspoon

Iyọ̀ ìgbàlódé       – Sibi ijeun kan tabi horo meji          Seasoning Salt – 1 Table Spoon or 2 Cubes

Irú                          – Ṣibi ijẹun meji                            Locust Beans seed – 2 Table Spoons

Edé                         – Ṣibi ijẹun mẹfa                           Dry Prawns/Crayfish – 6 Table Spoons

Omi                        – Ìgò omi kan                                Water –  1ltr bottle

Ẹran bí-bọ̀ tàbi din-din, Ẹja tútù tàbi gbígbẹ,    Cooked/fried meat, Fresh/Dry Fish, Cow skin,

Pọ̀nmọ́, Ṣàki àti bẹ̃bẹ lọ                                   Tripe etc.

ENGLISH TRANSLATION

 The wild-mango seed soup is a kind of slimy soup just like okra, but for someone who does not know how to prepare it, it would not be slimy.  It is easy and quick to prepare because once you have the ground powder, it saves the time spent on slicing the okra.  It can be prepared on a minimal budget.

The Yoruba adage that said “Stay off cooking a non-slimy wild-mango seed powder, and prepare for okra” can be used to advise someone doing a non-progressive or non-profitable job to try another venture in order not lose out completely.  Check the ingredients and the preparation of the wild-mango seed powder on this page.

 

Share Button

Originally posted 2014-02-22 01:38:39. Republished by Blog Post Promoter

“Orí ọti ọlọ́tí ni eṣinṣin nkúlé” – “Fly often dies on top of other people’s palm wine”.

Ìsọ̀ Ẹmu – Local Palm wine bar

Ìsọ̀ Ẹmu – Local Palm wine bar @theyorubablog.

“Ọ̀mùtí gbàgbé ìṣẹ́” fún ìgbaì diẹ ni, nítorí bí ọ̀mùtí bá jí tán, ìṣẹ́ rẹ kò tán.  Gbogbo àlàyé àti ìpolongo wípé ọtí àmun jù nfa oriṣiriṣi àìsàn burúkú àti wípé o ndójútini láwùjọ, ọpọlọpọ ọ̀mùtí á fi owó ilé-ìwé, owó ounjẹ ati ohun tó wúlò fún ọ̀mùtí àti ẹbi mu ọtí lai ro ìnira ti ó nfa fún ẹbí, ọ̀rẹ́ àti aládũgbò.  Bí Ìjọba, ẹbí àti ará ti ṣe ìkìlọ̀ tó nipa ọtí àmunpara, bi o ti ngba etí ọ̀tun wọlé lo ngba ti òsì jade fún àwọn ti ọ̀tí ba ti wọ lẹ́wù̀.

Ìrònú pẹ̀lú nkan ti ó nfa ọtí àmun jù ṣùgbọ́n ọ̀tí kò lè pa ìrònú rẹ àfi ki ó dá kun, nítorí bi ọtí bá dá lójú ọ̀mùtí, ìrònú á padà.  Ohun ti ẹbí àti ọ̀rẹ́ omuti lè ṣe ni ki wọn gbã ni ìyànjú lati lọ gba ìtọ́jú, ki irú ẹni bẹ̃ ma ba kú lọ́jọ́ àìpé.

Ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsìn, ọtí àmunpara kò yẹ ọmọ ènìà.

ENGLISH TRANSLATION

“The drunkard forgets his sorrow” but for a while, because he/she often discover that his/her sorrow is still very much around after waking up eventually.  With all the enlightenment and advertisement that alcoholism is associated with various severe diseases and the embarrassment it causes, many drunkards would forgo money for education, food and other basic need for him/herself and the family to drink without thinking of the consequences to family, friends and neighbours.  In spite of Government, family and friends’ warning to the drunkard, as the warning is going in through the right ear, it is escaping through the left for those addicted.

Depression is one of the major cause of excessive drinking, but drinking cannot cure depression except to increase it when a drunkard wake

up after his/her slumber.  What family and friends of people with alcoholism can do is to encourage him/her to seek help to avoid untimely death.

Everything should be done in moderation, excessive alcohol intake is not good for anyone.

Share Button

Originally posted 2013-07-02 16:15:53. Republished by Blog Post Promoter

“Ilé là ńwò ká tó sọmọ lórúkọ” – Orúkọ ẹni ni ìfihàn ẹni: One considers the circumstances of the home before naming a child – Your name is your identity

Ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si tijú lati jẹ orúkọ ti òbí fi èdè Yorùbá sọ wọn.  Èyi tó bá tún gba lati jẹ orúkọ Yorùbá á tún bã jẹ ni kikọ tàbi ni pipè.  Èwo ni ká kọ “Bayọ ni Bayor, Fẹmi ni Phemmy, Tọlani ni Thorlani – kilo njẹ bẹ̃?  Nigbati ẹni to ni orúkọ bá nbajẹ bawo ni àjòji ṣe lè pe orúkọ na dada? Lẹhin ọdún pipẹ́ itumọ̀ orúkọ ti wọn ba jẹ yi a sọnù.

“Ẹni ti kò bámọ̀ itàn ara rẹ̀, wọn á pe lorúkọ ti ki ṣe tirẹ, á si dáhùn”.  Á gbọ́ ti igbà òwò burúkú “Òwò Ẹrú”, ti ilú tó lágbára ra àwọn enia bi ẹni ra ohun ini. Ni àsikò yi, bi wọn bà kó enia lẹ́rú, olówó rẹ á fun lórúkọ nitori ko ma ba ranti ibi ti ó ti ḿbọ̀.  Eleyi jẹ ki ó ṣòro fún ẹrú lati mọ ibi ti wọn ti wa lẹhin ti òwò ẹrú pari.  Ohun ribiribi ti ẹrú ṣe, kò hàn si àwọn ti ó kù ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú pé dúdú ti wọn kó lẹ́rú ló ṣẽ, nitori orúkọ ti ó yi padà.

Òwe Yorùbá ni “Ilé làńwò kátó sọmọ lórúkọ”. Ó ṣeni lãnu pé ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá kò mọ iyi orúkọ wọn, nitori eyi fúnra wọn ni wọn pa orúkọ wọn da si orúkọ ti wọn kò mọ itumọ̀ rẹ.

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ maṣe jẹ́ki ẹ̀yà àti èdè Yorùbá parẹ́. “Orúkọ ẹni ni ifihàn ẹni”, ao ni parẹ máyé o (Àṣẹ)

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-21 21:13:32. Republished by Blog Post Promoter

“Ohun ti ajá mã jẹ, Èṣù á ṣẽ”: “What the dog will eat, the Devil will provide”

Yorùbá ma nṣe rúbọ Èṣù nigba gbogbo ki ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tó gbalẹ̀.  Ounjẹ ni wọn ma fi ṣè rúbo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.  Irú ounjẹ yi ni Yorùbá npè ni “ẹbọ”.  Ìta gbangba ni wọn ma ngbe irú ẹbọ bẹ si, nitori eyi ounjẹ ọ̀fẹ ma npọ fún ajá, ẹiyẹ àti awọn ẹranko miran ni igboro.

Ajá ìgboro - Stray dog eats food on the street. Courtesy: @theyorubablog

Ajá ìgboro – Stray dog eats food on the street. Courtesy: @theyorubablog

Bi ènìyàn kò ti si ninu ìhámọ́ ni ayé òde òní, bẹni ajá pãpa kò ti si ni ìhámọ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ “ajá igboro” ma jade lọ wa ounjẹ òjọ́ wọn kakiri ni.  Alãdúgbò lè pe ajá lati gbe ounjẹ àjẹkù fún pẹ̀lú, eleyi fi idi ti wọn fi nkígbe pe ajá han.  Bayi ni ará Àkúrẹ́ (olú ìlú ẹ̀yà Ondo) ti ma npe ajá fún ounjẹ ni ayé àtijọ́:

Kílí gbà, gbo, gbà, gbo

Ajá òréré́, gbà̀, gbo, gbà…

 

A lè fi òwe Yorùbá ti o ni “Ohun ti ajá mã jẹ, Èṣù á ṣẽ” yi ṣe àlàyé awọn ounjẹ ti Èṣù pèsè ni ayé òde òni wé: ẹjọ, àìsàn/àilera, ọtí/õgun-olóró tàbi ilé tẹ́tẹ́.  Ni ida keji, ajá jẹ “Agbẹjọ́rò, Babaláwo/Oníṣègùn, ilé-ọtí àti ilé iṣẹ́/ero tẹ́tẹ́”.

Adájọ́ Obinrin ati Ọkunrin -  Female and Male Judge Courtesy: @theyorubablog

Adájọ́ Obinrin ati Ọkunrin – Female and Male Judge
Courtesy: @theyorubablog

Bi a bá ṣe akiyesi, Yorùbá ni “Ọ̀gá tà, ọ̀gá ò tà, owó alágbàṣe á pé”.  Bi Agbẹjọ́rò ba bori tàbi kò bori ni ilé-ẹjọ́, owó rẹ á pé, aláìs̀an ni ilera bi ko ni ilera, Babaláwo/Oníṣègùn á gbowó.  Bi ọ̀mùtí yó tàbi kò yó, Ọlọti/Olõgun-olóró á gbowó àti bi ẹni tó ta tẹ́tẹ́ bá jẹ bi kò jẹ owó oni-tẹ́tẹ́ á pé.

 

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba often offer sacrifice before the advent of Christianity.  Food are often used for the sacrifice.  This type of food is called “Sacrifice”.  Such sacrifice are usually placed in the open, as a result, there are plenty of free meals for the dogs, birds and other animals on the Streets.

As people’s movement are not restricted like in the modern time, so also are the dogs not in restriction.  Many “Street dogs” roam around to source their meal.  Neighbours can beckon on the stray dog to offer left over meals, hence the reason for the various style of beckoning on dogs.  Check out the above recording the way people in Akure (capital of Ondo State) beckons on the Street dogs in the olden days.

We can use the Yoruba proverb that said “What the dog will eat, the Devil will provide” to compare the kind of food provided by the Devil in the modern days as: Cases, sickness, alcoholism/hard drug or gambling shop.  On the other hand, the dog can be parallel with: Lawyers, Doctors/Herbalists, Pub and Gambling House/machine.

If we observe another Yoruba proverb that “Whether the boss sells or not, the labourer will collect his/her wage”.  This means, whether the Lawyer/Barrister wins a case in court or not, his/her legal fees must be paid, same as whether the sick person is well or not, the Doctor/Herbalist has to be paid.  Whether the Drunkard/Drug addict is intoxicated or not, the Pub-owner’s will be paid.

Share Button

Originally posted 2013-10-15 20:25:03. Republished by Blog Post Promoter

OHUN TÍ́ A LÈRÍ NÍNÚ ÀTI ÀYÍKÁ ILÉ – BASIC YORUBA HOUSEHOLD ITEMS

 

YORÙBÁ ENGLISH YORÙBÁ ENGLISH
Àwo pẹrẹsẹ Plates Ṣíbí Spoon
Abọ́ Dish Ọ̀bẹ Knife
Ago Cup Ìgò Omi Water Bottle
Aago Clock Ìkòkò Omi Water Pot
Aṣọ Clothes Omi Water
Oúnjẹ Food Ibi Ìdáná Kitchen
Ilẹ̀kùn Door Igi Ìdáná Firewood
Fèrèsé Window Yàrá Room
Ijoko Seat Gbàngán Living Room
Àga Chair Ilẹ̀ilé Floor
Àga Tábìlì Table Òkèàjà Ceiling
Pẹpẹ Shelf Ọgbà Compound
Òrùlé Roof Iléìwẹ̀ Bathroom
Àpótí Aṣọ Boxes Iléìtọ̀/Iléìgbẹ́ Toilet
Share Button

Originally posted 2013-05-07 23:58:38. Republished by Blog Post Promoter

Ìtán ti a fẹ́ kà loni dá lóri Bàbá tó kó gbogbo Ẹrù fún Ẹrú – The story of the day is about a father who bequeathed all his inheritance to his Chief Slave

Share Button

Originally posted 2017-12-06 00:23:08. Republished by Blog Post Promoter

Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ kò ní jẹ ki a sùn – If you fail to warn your neighbor of danger, his cries at night might prevent you from sleeping

Ó ti lé ni ọgbọ̀n ọdún ti ìyà iná monomono ti ńfi ìyà jẹ ará ilú orílẹ̀ èdè Nigeria.  Nitori dáku-́dájí iná  mọ̀nàmọ́na ti Ìjọba àpapọ̀ pèsè, ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na kékèké ti a lè fi wé kòkòrò búburú gbòde.

Generators

Power generators: ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na. The image is from http://lowhangingfruits.blogspot.com

Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn” bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu.  Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run.  Ai sọ̀rọ̀ ará ìlú lati igbà ti aiṣe dẽde iná ti bẹrẹ lo fa hẹ̀rẹ̀huru ariwo ti ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ-iná kékèké ma ńfà.  Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun.  Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru.

Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona.  A lè fi õrun,  atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona-. Ìlú ti kò ni õrun tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi õrun pèsè iná mona-mona.

Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí.

English translation: Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-22 03:51:57. Republished by Blog Post Promoter