Tag Archives: Gold

“Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” – “Not all that glitters is Gold”

Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàki fún ohun ẹ̀ṣọ́.  Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara.    Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi.  Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe; ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse; kò ki léwó.

Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà”, bẹni ki ṣe gbogbo  èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò.  Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku.  Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni.  Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni.

A lè fi òwe “Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà” gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ.  Àfarawé léwu, nitori ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-30 22:55:23. Republished by Blog Post Promoter

“Orúkọ rere sàn ju Wúrà ati Fàdákà”: Good name is better than Silver and Gold

Late Drummer Lee Rigby

Olõgbe Onílù Lee Rigby (ọmọ ọdun marunlélógún): Late Soldier Drummer Lee Rigby – aged 25

Olõgbe Onílù Lee Rigby (ọmọdun marunlélógún) fi orúkọ rere silẹ fun àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ẹgbẹ́ nigbàti àwọn apànìyàn Michael Adébọ́lájọ àti Michael Adébọ̀wálé ba orúkọ ẹbí wọn jẹ́.

Michael Adébọ́lájọ (ọmọ ọdun méjìdínlọ́gbọ̀n) àti Michael Adébọ̀wále (ọmọ ọdun méjìlélógún)  ti o pa Jagunjagun Onílù Lee Rigby ni Woolwich kò jẹ́wọ́ ọ̀rọ̀ Yorùbá tó sọ wípé “Orúkọ ní roni”  nítorí ìwà ìkà tí wọn hù.  “Michael” jẹ́ “Orúkọ Angẹli tó jẹ́ Olùgbèjà” ti àwọn “Onígbàgbọ́” mã nsọ ọmọ ni “ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ” tàbi “ọjọ Ìsàmì”.   “Adébọ́lájọ” túmọ̀ si wípé “Adé bá Ọla jọ” nígbàtí a lè túmọ̀ “Adébọ̀wálé” sí wípé “Adé padà wá sílé”.  Orúkọ ìdílé méjèèji yi jẹ́ orúkọ ìdílé Ọba tàbi Ìjòyè tí ó lè dé adé ni ilẹ̀ Yorùbá.

Orúkọ rere sàn ju Wúrà àti Fàdákà” nígbàtí àwọn ọmọ ìdílé bẹ̃ bá lo orúkọ nã dáradára, ṣùgbọn ìṣẹlẹ ibi yi ti ba orúkọ ìdílé Adébọ́lájọ àti Adébọ̀wálé jẹ́.

Gbogbo ọmọ Yorùbá àti Nigeria lápapọ̀ pàtàkì àwọn tí ó wà ni Ìlú-ọba, ṣe ìdárò Olõgbe Ajagun Onílù Lee Rigby, a sì gba àdúrà pé kí Ọlọrun kí ó tu ìdílé rẹ nínú.

ENGLISH TRANSLATION

Late Drummer Lee Rigby (aged 25) left a good name and legacy for his family, friends and colleagues while the “Killers Michael Adebolajo and Michael Adebowale” destroyed their family names.

Michael Adebolajo (aged 28) and Michael Adebowale (aged 22) that killed Soldier, Drummer Lee Rigby at Woolwich did not live up to the adage that said “Names do guide action” because of their evil act.  Michael “the name of an Angel that defend” that is often given by Christians to babies at birth during “Naming Ceremony” or “Baptism”.  “Adebolajo” means “Crown blends with wealth” while “Adebowale” means “The Crown returned Home”.  These two Family Names are commonly used by the “Yoruba Monarchs and the Chief’s family that can be crowned”.

According to the Yoruba adage “Good name is better than Silver and Gold” only when such family members use the names in a positive manner but in this case, Adebolajo and Adebowale family names have been destroyed as a result of this evil act.

Yoruba indigenes and all Nigerians particularly those in the United Kingdom mourn the loss of Late Soldier, Drummer Lee Rigby, and pray that God will console his family.

Share Button