Category Archives: Yoruba related News

Yoruba related news…

Gó́mìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá – Lagos Governor Akinwunmi Ambode signed into Law Yoruba Language Preservation and Promotion Bill

Ọ̀túnba Gàní Adams ṣe ìwúyè – Chief Gani Adams’ installation as the Aare Ona Kakanfo

Aàrẹ Ọ̀nà Kakanfo, Ọ̀túnba Gàní Adams ti wọn ṣe ìwúyè fún ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, oṣù kini, ọjọ́ kẹtàlá ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún fi ẹ̀dùn ọkàn hàn nipa bi àṣà àti ìṣe Yoruba ti fẹ́ parẹ́.  Nigba ìwúyè, Ọ̀túnba Gàní Adams ṣe àlàyé pé́ ori ire ni wi pé kò si ogun ti ó nja ilẹ̀ Yoruba lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣùgbọ́n òhun yio tẹra mọ́ṣẹ́ lati dáàbò àti bójútó àṣà àti ìṣe Yorùbá.

Ìpínlẹ̀ Èkó ti tún ta wọ́n yọ lẹ́ ẹ̀kan si.  Ni Ọjọ́bọ̀, oṣù keji ọjọ́ kẹjọ, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún, Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin ti yio ṣe ìpamọ́ àti gbé èdè Yorùbá ga.

Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin – Gov Akinwunmi Ambode signed Yoruba Language Preservation and Promotion bill

Akọ̀wé Yorùbá lóri ayélujára yin Gó́mìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé àti àwọn Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó fún iṣẹ́ takuntakun ti wọ́n ṣe lati ṣe òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá.

 

 

 

ENGLISH TRANSLATION

The 15th Aare Ona Kakanfo, Chief Gani Adams who was installed on Saturday, January, 13, 2018 expressed the concern that Yoruba culture and values are going into extinction.  During his installation, he opined that though he was lucky that there is no war ravaging Yoruba nation right now, he will continue to work tirelessly to protect and preserve Yoruba culture and values. Continue reading

Share

A ò lè tori a mà jẹran dọ̀bálẹ̀ fún Mãlu – Àgbẹ́kọ̀yà kọ Àṣejù Fúlàní Darandaran – Agbekoya (meaning Farmers reject oppression) condemn the excesses of Fulani Herdsmen

Ìròyìn tó gbòde, ni ọ̀rọ̀ Ìjọba-àpapọ̀ ti ó fẹ ki gbogbo ìpínlẹ̀ ni Nigeria pèsè àyè ni ọ̀fẹ́ fún àwọn darandaran lati tẹ̀dó dípò ki wọn ma kó Mãlu kiri.

Ni ipinlẹ si ìpínlẹ̀, oníkálùkù lò ni iṣẹ́ tàbi òwò tirẹ̀.  Iṣẹ́ àgbẹ̀ ló wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ni ayé àtijọ.  Bi iṣẹ́ àgbẹ̀ ti ṣe pàtàki fún Yoruba, bẹ ni ise darandaran jẹ́ fún Fúlàní ni òkè-ọya.  Ìyàtọ̀ ti ó wà ni àwọn iṣẹ́ mejeeji ni wi pé, àgbẹ̀ ńṣe oko ni agbègbè rẹ, nigbati darandaran ńda ẹran wọn kakiri lati ìlú kan si ekeji.

Ilẹ̀ pọ̀ ju èrò lọ ni oke- ọya ju odò-ọya lọ. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “A o ri ibi sùn, ajá ńhanrun”.  Ìjà Sèríà àti Boko Haram ti ṣi ọpọlọpọ ni idi kúrò ni òkè-ọya bọ́ si odò-ọya.    Àyè kò tó fún ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn ti ó ngbé ni odò-ọya pàtàki fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ó dari wále nitori ija Bókó Haram àti ogun abẹ́lé yoku ni òkè-ọya.

Fúlàní Darandaran – Fulani Herdsman

Yorùbá fẹran àlejò púpọ̀, darandaran ti nda ẹran wá si ilẹ̀ Yorùbá lai si ìjà, ọ̀na ti jin. Ọba, Ìjòyè àti ọlọ́rọ̀ àyè àtijọ́ ma nni agbo ẹran tàbi Mãlu ti àwọn Fúlàní mba wọn tọ́jú.  Ibùjẹ-ẹran tún wà ni ilẹ̀- Yorùbá ni Àkùnnù-Àkókó. Ni ayé òde òni, kò bójú mu lati da ẹran kiri ni igboro àti ilú nlá.    Di da ẹran kiri ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjàmbá ọkọ̀ tó ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí lọ.  Ki ẹran má a jẹ ohun ọ̀gbìn àgbẹ̀ àti ba oko jẹ kò bójú mu.  Èyí ti ó́ burú ju ni darandaran ti ó ngbé ìbọn dání dípò ọ̀pá-ìdaran, ti wọn ti pa olóko tori ki malu lè jẹun.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “A ò lè tori a ma jẹ́ran, dọ̀bálẹ̀ fún Mãlu”, eleyi ló jẹ́ ki ẹgbẹ́ Àgbẹ́kọ̀yà kọ ètò ìjọba àpapọ̀ lati pèsè ilẹ̀-ọ̀fẹ́ fún àwọn Fulani ti ó nda ẹran ni ipinle Yorùbá àti lati kọ ìyà lọ́wọ́ daran-daran ti o ngbé ìbọn lati da ẹran.

Ni ilú òyìnbó, àgbẹ àti àwọn ti o ńsin ẹran nri ìrànlọwọ gbà ni ọdọ Ìjọba. Ó yẹ ki ijoba apapo pèsè irinṣẹ́ ìgbàlódé fún àwọn àgbẹ̀ àti ki àwọn ipinlẹ̀ pèsè àyè rẹpẹtẹ fún oko lati gbin oúnjẹ fún àwọn ogúnlọ́gọ̀ èrò ti ó pọ̀si odò-ọya ju ìpèsè ilé ọ̀fẹ́ fún darandaran.   Ìmọ̀ràn fún Ìjọba-àpapọ̀ ni ki wọn lo ilẹ̀ ti ó pọ̀ rẹpẹtẹ ni òkè-ọya pàtàki igbó Sambisa ti àwọn Bókó Haram fi ṣe ibùjòkó tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba lọ́wọ́lọ́wọ́ tó lé wọn jade fun agbo malu.

ENGLISH TRANSLATION

The current news in Nigeria is the Federal Government’s directives for the States to voluntarily give land for herdsmen’s colony to stem the current practice of herdsmen moving from place to place for grazing.  Continue reading

Share

A kú ọdún tuntun – Happy New Year

Share

A kú Ìdùnnú Ìdúpẹ́ – Happy Thanksgiving

Bi Ọlọrun ti ńdárí ẹ̀ṣẹ̀ ji èniyàn
Bi Olóri Òṣèlú Àmẹ́rikà ti ńdáríji tòlótòló
Bẹni ki èniyàn dári ji ẹni ti ó bá ṣẹ́, nitori ki a lè fi ìdùnnú dúpẹ́.

Olóri Òṣèlú Àmẹ́rikà dáríji tòlótòló – American President pardons the Turkey during Thanksgiving

 

 

Share

Ikú kò mọ àgbà, ó mú ọmọdé bi Jidé Tinubu – Death is no respecter of age, Jide Tinubu was snatched away by death

Òwe Yorùbá sọ wi pé “bi iná bá kú, á fi eérú bojú, bi ọ̀gẹ̀dẹ̀ bá kú, á fi ọmọ ẹ rọ́pò”.  Òwe yi fi hàn ipò ti Yorùbá fi ọmọ si.  Kò si ẹni ti kò ni kú, ṣùgbọ́n ọ̀fọ̀ nlá ni ikú ọmọ jẹ́ fún òbí àti àwọn ti olóògbé bá fi silẹ̀ pàtàki àbíkú àgbà.  Ìròyìn ikú Jidé Tinubu àrólé Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu kàn pé ó jade láyé ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kini oṣù kọkànlá ọdún Ẹgbàálémẹ́tàdínlógún.

Góm̀nà tẹ́lẹ̀ Bọla Tinubu pẹ̀lú ìyàwó Rẹ̀mí àti ọmọ rẹ olóògbé Jidé nigbà ayẹyẹ ìwé-ẹri Agbejọ́rò – former Gov Tinubu with his wife Remi and late son Jide during his Law School graduation

Ọlọrun ki ó dáwọ́ àbíkú àgbà dúró, ki ó si tu bàbá olóògbé,  Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀ Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed, ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo ẹbí ninú.  Ki Èdùmàrè dá ikú ọ̀dọ́ dúró, kó tu gbogbo àwọn ti irú ọ̀fọ̀ bẹ́ ẹ̀ bá ṣẹ̀ ninú.

ENGLISH TRANSLATION

According to one of the Yoruba proverbs translated thus “fire is succeeded by ashes, plantain/banana is replaced by its fruits”.  This proverb reflects the hope Yoruba placed on their children. Death is unavoidable by everyone, however, the death of one’s child is often a terrible bereavement for the parents of the deceased particularly the death of an adult child.  On Wednesday, November 1, 2017, the news of the death of Jide Tinubu the first son of the former Governor of Lagos State, Bola Ahmed Tinubu was announced. Continue reading

Share

Ìròyìn kàn pé Ọ̀túnba Gani Adams ni Aàrẹ Ọ̀na Kakanfo Yorùbá karùndinlógún – Chief Gani Adams has been announced as the Fifteenth Generalissimo of Yorubaland

Ọba Lamidi Adéyẹmi àti Ọ̀túnba Gani Adams – Aláafin Lamidi Adeyemi & Chief Gani Adams

Lẹhin ọdún kọkàndinlógún ikú Olóògbé Olóyè M.K.O Abíọ́lá, Aàrẹ Ọ̀na Kakanfo Yorùbá kẹ̀rinlá, Ọba Lamidi Adéyẹmi yan Ọ̀túnba Gani Adams si ipò Aàrẹ Ọ̀na Kakanfo Yorùbá karùndinlógún.

Ọ̀túnba Gani Adams ni olùdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Ọmọ Oòduà, ti wọn dá silẹ̀ ni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kẹjọ ọdún kẹtàlélógún sẹhin ni Mushin, lati jà fún gbi gbé ipò Olórí Òṣèlú fún M.K.O Abiola ti ó mókè ni ìbò ti wọn di ni ọjọ́ kejila ọdún kẹrinlélógún sẹhin lai si ìjà tàbi asọ̀ ni gbogbo orílẹ̀ èdè Nigeria.  Kò bojú wẹ̀hin lati ọdún kẹtàlélógún lati má a jà fún Yorùbá lati gba ẹ̀tọ́, iyì àti gbi gbé àṣà Yorùbá ga kakiri àgbáyé.  Fún akitiyan yi, wọn ti fi jẹ oyè mejilelaadọta kakiri, ṣùgbọ́n adé gbogbo oyè yi ni Aare Ona Kakanfo.

Bi àwọn alatako diẹ ti wa ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàgbà Yorùbá ti fi ọwọ́ si yin yan Ọ̀túnba Gani Adams si ipò Aare Ona Kakanfo karundinlogun.  Lára àwọn enia pàtàki ti ó ki kú ori ire ni, Ọọni Ifẹ̀, Gómìnà Bọ́la Tinubu, Gómìnà Rauf Arẹ́gbẹ́sọlá, àwọn ọ̀gá olórin àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.

Olùkọ̀wé Yorùbá lóri Ayélujára kí Ọ̀túnba Gani Adams kú ori ire, oyè á mọ́rí o, ẹ ò ni kú léwe, ẹmi ọlá á gùn lati má a jà fún Yorùbá àti lati gbé àṣà Yorùbá lárugẹ si, ni gbogbo àgbáyé.

ENGLISH TRANSLATION

Nineteen years after the death of Chief M.K.O. Abiola, the fourteenth Generalissimo of Yorubaland, the Alafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi has nominated Chief Gani Adams as the 15h Generalissimo of Yorubaland.

Chief Gani Adams was the founder of the Odua Youth Movement which was formed on August 25, 1994 at Mushin, Lagos, to fight for the actualisation of June 12, 1993 Presidential election won by Chief M.KO. Abiola in a free and fair election all over Nigeria.  He has not looked back since he came to prominence in 1994 as he continued to fight to uphold the dignity, honour and culture of his people.  His action of defending and promoting Yoruba culture has earned him fifty-two titles but the crown of all the titles is the Aare Ona Kakanfo.

Although there are some oppositions, many prominent Yoruba leaders have endorsed the nomination of Otunba Gani Adams as the fifteen Aare Ona Kakanfo.  Prominent among them are, Ooni of Ife, Governors – Ahmed Bola Tinubu (former Governor of Lagos State), Rauf Aregbesola (Osun State Governor), prominent Musicians etc.

The Yoruba Blog congratulates Chief Gani Adams and pray that he will not die young but live long to continue in the service of defending Yorubaland and promoting her culture all over the world.

Share

Adébáyọ̀ Fálétí, ògúná gbòngbò ti ó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ jade láyé: A Prominent Yoruba language and Culture promoter has departed the world

Àwọn iwé ìròyìn gbe jade wi pé Adébáyọ̀ Fálétí, ògúná gbòngbò ninú àwọn ti ó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ ni àgbáyé, re ibi àgbà nrè ni ọjọ́ ìsimi ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje, ọdún Ẹgbàálémẹ́tàdinlógún.  Ọmọ ọdún mẹrindinlaadọrun ni olóògbé Fálétí ki wọn tó jade láyé.

Olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí relé – Late Adebayo Faleti has gone home.

Ni ìgbá ayé olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí, ó jẹ́ ìkan ninú àwọn òṣìṣẹ́ àkọ́kọ́ ni ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́ ni ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú ti wọn dá sílẹ̀ ni Ìbàdàn ti ó jẹ́ olú ilú ẹ̀yà Yorùbá ni ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀ èdè Nigeria.  Ó gbé èdè Yorùbá lárugẹ nipa ṣi ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì si èdè Yorùbá, ó kọ ìwé itumọ̀ ọ̀rọ̀ nipa li lo orúkọ Yorùbá.  Kò tán síbẹ, oníròyìn ni, ó fi eré ìtàgé gbé èdè Yorùbá lárugẹ nipa di dá ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Ọ̀yọ́ fún ìgbéga eré ìtàgé silẹ̀ ni ọdún mejidinlaadọrin sẹhin.  Lára àwọn eré Yorùbá ti olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí kọ, ti ó si ṣe ni “Mágùn, Àfọ̀njá, Baṣọ̀run Gáà àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ́ lọ.

Ẹ̀kọ́ pọ̀ fún ọ̀dọ́ ayé òde òní lati kọ́ lára ìgbésí ayé olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí.  Lára ẹ̀kọ́ yi ni wi pe, ìwé kí kà ṣe pàtàkì, bi kò ti ẹ̀ si ìrànlọ́wọ́ lati ka ìwé ni ọmọdé, bi enia bá ka ìwé ni àgbà yio wúlò.  Olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí padà si ilé-ìwé  lati lọ pari ìwé mẹfa ti ó dá dúró nigbati kó si agbára fún bàbá rẹ.  Lẹhin eyi ó fi àgbà ara ka ìwé ni ilé-ìwé ẹ̀kọ́ giga.  Ó gbé ìgbésí ayé rere nipa ìtọ́jú àwọn ọmọ àti ìyàwó, ó si fún àwọn ọmọ ni ẹ̀kọ́ ilé àti ti ilé-ìwé.

Fún àwon iṣẹ́ ribiribi yi, olóògbé Adébáyọ̀ Fálétí gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn àpínfún ni orilẹ̀ èdè Nigeria àti ni òkè-òkun.

ENGLISH TRANSLATION

Many Nigerian Newspapers broke the news of the death of Adebayo Faleti, a prominent promoter of Yoruba language and culture on Sunday, 23rd day of year 2017.  He was 86 years at the time he departed the world.

During his lifetime, he was one of the pioneering staff of the Western Nigeria Television (WNTV) at Ibadan capital of Western State of Nigeria and the first of its kind in Africa.  He promoted Yoruba language as a Translator of English to Yoruba, he wrote a book on the meaning and use of Yoruba names.  That was not all, he was a Broadcaster and he used acting to promote Yoruba language and culture by establishing the ‘Oyo Youth Operatic Society’ sixty eight years ago.  Among the plays he wrote and acted in were ‘Magun, Afonja, Basorun Gaa’ etc.

The youths of nowadays have many lessons to learn from the life of late Adebayo Faleti.  Among such lessons, were the importance of education, even when there was no opportunity at a younger age, going to school as a later life learner often becomes very useful.  Late Adebayo Faleti returned to school at a later age to complete his primary school education which was hindered as a result of the father not being able to afford it. After completing primary six, he continued higher education as a later life learner.  He lived a life worthy of emulation by being responsible, caring for his children and wives and he gave his children formal and informal education.

Late Adebayo Faleti bagged many awards in Nigeria and abroad as a recognition of his immense contribution.

Share

Ọdún wọlé dé, ẹ ṣọ́ra fún ewu àfọwọ́fà ti ọti àmu párà lè fà – End of Year Celebration is here, beware of attracted danger caused

Ẹ kú àsikò yi o.  Bawo ni ipalẹ̀mọ́ ọdún Kérésìmesì àti ọdún titun?

Ni àsikò ọdún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi oúnjẹ  àjẹ jù àti ọti à mu para yọ ayọ̀ ọdún.  Ni òtitọ́, ará ilú nké pé kò si owó àti ọ̀wọ́n ọjà, nitori eyi ayé àjẹ jù le ma si, ṣùgbọ́n bi ẹlòmíràn kò ni owó, á gba àwin ọti pé àwọn fẹ́ fi pa irònú rẹ́.  Àwọn miran nlo egbò igi olóró ti á gbọ́ wi pé ó ti wọ́pọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nigeria pàtàki laarin àwọn ọ̀dọ́.  À fọwọ́ fà ni gbogbo eyi.

Kò si iyàtọ̀ laarin ọlọ́tí pẹ̀lú ẹni ti ó mu egbò igi olóró àti wèrè, nitori ihùwà ọlọ́ti àti ẹni lo oògùn olóró kò yàtọ̀ si ti wèrè bi wọn bá ti yó.  Bi ẹni ti ó mu àmu para àti ẹni lo egbò igi olóró bá wa ọkọ̀, àkóbá ni fún àwọn awakọ̀ yoku àti àwọn arin nà yoku.

Ki ọdún titun lè bá wa láyọ̀, ikilọ ni àsikò yi ni wi pé “Ki ẹni bá mú ọti tàbi ẹni tó lo egbò igi olóró ma ṣe wa ọkọ̀”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Ariwo Nigeria lóri èsi Idibo ni Amẹ́rikà: Nigerian’s noise on American Election Result

Èsi ibò ti wọn di ni ilú Amẹ́rikà ni oṣù kọkànlá, ọjọ́ kẹjọ jade ni òru ọjọ́ kẹjọ mọ́jú ọjọ́ kẹsan ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún.   Àwọn mẹta ti ó gbé àpóti ibò fún ipò olóri òṣèlú ni, Hillary Clinton, obinrin àkọ́kọ́ lati dé irú ipò bẹ́ ẹ̀ fún ẹgbẹ́ (Democrat), Donald J. Trump, Oniṣòwò nlá ti kò ṣe iṣẹ́ Ìjọba kankan ri fún ẹgbẹ́ (Republican) àti Gary Johnson fún ẹgbẹ́ kẹta (Libertarian).

Èsi ibò yi ya gbogbo àgbáyé lẹ́nu nitori àwọn ọ̀rọ̀ ti Donald Trump (Olóri ẹgbẹ́ GOP)  ti sọ siwájú nigbati ti ó polongo lati dé ipò.  Àwọn ọ̀rọ̀ iko rira wọnyi lòdi si àwọn obinrin, ẹ̀yà miran ti ó yàtọ̀ si ẹ̀yà rẹ, àlejò, ẹlẹ́sin Mùsùlùmi àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Owe Yoruba so wipe “Bi Ẹlẹ́bọ kò bá peni, Àṣefín kò yẹni”.   Donald Trump ò ka gbogbo ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú si nkankan tàbi dárúkọ Nigeria.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wi pé nitori Amẹ́rikà ti nṣe Òṣèlú ti wa ntiwa fún igbalélógòji ọdún, ẹni ti wọn yio yan si irú ipò yi á ni iwà àkójọ àti ẹ̀mi àkóso si onírúurú àwọn enia ti ó wà ni gbogbo àgbáyé.

Ariwo Nigeria lóri èsi Idibo ni Amẹ́rikà: Nigerian Media's frenzy on US Election.

Ariwo Nigeria lóri èsi Idibo ni Amẹ́rikà: Nigerian Media’s frenzy on US Election.

Òwe Yorùbá ni “Bi èniyàn bá ni kò si irú òhun, àwọn ọlọ́gbọ́n a máa wòye”.  Lati igbà ti iròyin ibo ti jade pé Donald J. Trump ló wọlé, gẹ́gẹ́ bi wọn ti nṣe é, àwọn Olóri ilú àgbáyé ló kọ iwé tàbi pè lati ki ku ori ire.  Ó ṣe ni laanu wi pé, àwọn tó wà ni ilé aṣòfin Nigeria,  àti oriṣiriṣi àwọn Òṣèlú kékeré yókù lo nkọ iwé.  Gbogbo ìròyìn lati Nigeria kò ri ọ̀rọ̀ àti ìṣò̀ro ti ó dojú kọ ilú ti wọn sọ mọ, ju ọ̀rọ̀ èsi ibò ni Amẹ́rikà.  Eyi kò fi ọgbọ́n han nitori ìyà ti ó njẹ ará ilú Nigeria kọjá ki wọn ma sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari lati ṣe àyipadà kúrò ni iwà ibàjẹ́ ti ó ba ilú jẹ, ki ilú lè tòrò, ki ó si lè pèsè oúnjẹ àti ohun amáyédẹrùn fún ará ilú.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Muhammad Ali – Ọ̀gá pátápátá Afẹ̀ṣẹ́ kù bi Òjò àwọn Akànṣẹ́ Relé: “The Greatest Boxer” – Muhammad Ali has gone home

Worshipers and well-wishers take photographs as the casket with the body of the late boxing champion Muhammad Ali is brought for his jenazah, …

Ìròyìn ikú Muhammad Ali ọmọ ọdún mẹ́rinlélaadọrin kàn ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹta, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún.  Bi ó ti ẹ jẹ wi pé, Ali ti wà lóri àisàn fún bi ọgbọ̀n ọdún, inú ọmọdé àti àgbà ni àgbáyé ṣe ìdárò nigbati wọn gbọ ìròyìn ikú rẹ.

Ki ṣe iṣẹ́ akànṣẹ́ nikan ni Muhammad Ali dúró fún, ó dúró fún ohun ti ó gbàgbọ́ lai bẹ̀rù.  Ni bi ọdún marun-dinlọgọta sẹhin, nigbati Aláwọ-funfun ṣe òfin lati ya Aláwọ̀-dúdú si ọ̀tọ̀, pé wọn kò lè lo ohun amáyédẹrùn (bi ọkọ̀ wi wọ̀ pọ̀, ilé oúnjẹ, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀  lọ)  ti wọn pèsè fún ará ilú pẹ̀lú Aláwọ-funfun, Muhammad Ali kò pa ẹnu mọ lati dẹbi fún irú òfin àti iwà burúkú yi.  Ó kọ̀ lati lọ jagun (Vietnam), ti kò gbàgbọ́ nitori ó gbàgbọ́ pé alafia dára ju ogun lọ.  Muhammad Ali yi orúkọ ẹrú “Cacius Clay’’àti ẹ̀sìn padà lati kọ ẹ̀hin si iwà burúkú ti Aláwọ-funfun hù si enia rẹ.

Muhammad Ali mú adùn wọ iṣẹ́ akànṣẹ́, ó fi ọlà rẹ ṣe àánú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláìní, ó si jẹ àwòkọ̀ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ pàtàki Aláwọ̀-dúdú ti ó fi hà̀n pé ‘kò si ohun ti kò ṣe é ṣe, bi enia bá fi ọkàn si’.  Eleyi jẹ ki èrò fẹ́ràn rẹ púpọ̀.

Muhammad Ali and Joe Frazier – The Thrilla In Manila

Àwọn Olóri Ilú àti Ẹlẹ́sin ni oriṣiriṣi ati gbogbo àgbáyé ṣe ìdárò Muhammad Ali bi wọn ti ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin tó yẹ fún Ọba, ni ibi ìtẹ́ ìsìnkú ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹwa, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, ọmọ-ọmọ, Ìyàwó, ẹbi àti ará ló gbẹ̀hin rẹ.  Sùn re o.

 

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share