Ni ìrántí àwọn ti ó gbé àṣà àti èdè Yorùbá lárugẹ ti ó di olóògbé ni Ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún – In memory of Prof. Akinwunmi Isola and Baba Sala who died in 2018

A bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá si ìlú Ìbàdàn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni oṣù kejìlá, ọjọ kẹrìnlélógún, ọdún Ẹdẹgbaalemọ́kàndínlógójì. Ó kú lẹhin ti ó pé ọdún méjìdínlọ́gọ́rin ni oṣù keji, ọjọ́ kẹtàdínlógún, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe fún èdè àti àṣà Yorùbá kò ṣe é gbàgbé.  Ki Ọlọrun má a fún ẹ̀mí rẹ ni ìsimi.

Ni ìgbà ayé Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, ó fi iṣẹ́-akẹkọ gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ pẹ̀lú onkọwe-eré, eré-ṣíṣe, eré-ìtàgé àti ajàfẹtọ-àṣà.   Bi ó ti ẹ jẹ wí pé, ó kọ́ ẹ̀kọ́ lóri èdè Faransé, ó kọ ọ̀pọ̀lopọ̀ eré àti àwọn ìwé tó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ bi: Efúnṣetán Aníwúrà, Tinubu-Ìyálóde Ẹ̀gbá, Ṣaworoidẹ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀ lọ.

Mósè Ọláìyá Adéjùmọ̀ (ti àdá-pè rẹ njẹ́ Bàba Sàlá) jẹ́ ọmọ Yorùbá lati Iléṣà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.  Ni ìgbà ayé rẹ, ó lo ẹ̀bùn orin-kí kọ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kẹrinladọta sẹ́hìn, àwàdà àti eré-ìtàgé gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ.  Ni ayé ìgbàlódé, Bàba Sàlá jẹ aṣájú fún gbogbo Aláwàdà ni orílẹ̀-èdè Nigeria.

A bi Mósè Ọláìyá Adéjùmọ̀ (ti gbogbo èrò mọ̀ si “Bàba Sàlá”) ni oṣù karun jo kejidinlogun, ọdún Ẹ̀dẹ́gbaa-lémẹ́rìndínlógójì, ó gbé ayé titi di oṣù kẹwa, ọjọ́ keje ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Ogún rẹ̀ fún àwọn Òṣèré yio dúró titi. Ki Ọlọrun má a fún ẹ̀mí rẹ ni ìsimi.

ENGLISH TRANSLATION

Professor Akinwunmi Isola was born in Ibadan, Oyo State on December 24, 1939.  He died after his  78 birthday on February 17, 2018.  His immense contribution to Yoruba language and culture lives on.  May God continue to grant his soul peace.

Professor Akinwunmi Isola in his lifetime, used his scholarly work to promote Yoruba language and culture through playwright, acting, drama and culture activism.  Though he studied French language, he wrote many plays and books that promoted Yoruba language and culture such as: Efunsetan Aniwura, Madam Tinubu, Saworoide etc.

Moses Olaiya Adejumo (alias Baba Sala) is a Yoruba man from Ilesa, Osun State.  In his lifetime, he used his talent to promote Yoruba language and culture through music, comedy and drama.  Baba Sala was a forerunner for the modern day Comedians in Nigeria.

Moses Olaiya Adejumo (popularly known as Baba Sala) was born on May 18, 1936 and lived till October 7, 2018.  His legacy in the performing art lives on.  May his soul rest in peace.

Share Button

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.