Tag Archives: Open Primary

Ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti yio du ipò fún ẹgbẹ́ kò yẹ kó fa ìjà laarin Gómìnà Àmbọ̀dé àti Bàbá Òṣèlú rẹ, Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu – Adoption of Direct Primary should not cause a rift between Gov. Ambode and his political Godfather former Gov. Bola Tinubu

Nínú gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú orílẹ̀ èdè Nigeria, àwọn alágbára díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ni ó ńyan ẹni ti wọ́n fẹ́ ki o fi iga gbága fún ipò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Ó ti di àṣà ki Gómìnà Èkó lo ọdún mẹrin nigbà méji tàbi ọdún mẹjọ lóri ipò Gómìnà.  Lati ìgbà òṣèlú alágbádá kẹrin ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kọkàndínlógún sẹhin ni orílẹ èdè Nigeria, ni ìpínlẹ̀ Èkó ti yan Bọ́lá Ahmed Tinubu si ipò Gómìnà.  Ìpínlẹ̀ Èkó fẹ́ràn Bọ́lá Tinubu, èyi jẹ́ ki ó di ẹni àmúyangàn fún gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ti ó wà, nitori èyi ẹni ti ó bá fi ọwọ́ si, fún ipò òṣèlú ni àwọn èrò ìpínlẹ̀ Èkó mba fi ọwọ́ si.

Lẹhin ọdún mẹjọ ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu pari àsìkò tirẹ̀, fún àìdúró iṣẹ ribiribi ti ó ṣe ni ìpínlẹ̀ Èkó, ó pẹ̀lú àwọn ògúná gbòngbò òṣèlú ti ó yan Gómìnà Babátúndé Rájí Fáṣọlá ti òhun naa lo ọdún mẹjọ. Gẹ́gẹ́ bi bàbá àgbà òṣèlú, Bọ́lá Tinubu da òróró si orí Gómìnà Àmbọ̀dé, èyi jẹ́ ki ó mókè ju gbogbo àwọn ti ó du ipò àti di Gómìnà ni ọdún kẹta sẹ́hìn, ti ó si fa ọ̀tá laarin ẹgbẹ́ àti àwọn ti ó du ipò Gómìnà fún Bọ́lá Tinubu.

Ipò Gómìnà tàbi ipò òṣèlú ki i ṣe oyè ìdílé ti kò ṣe é dù bi ìlú bá ti yan olóyè tán.  Ni ìjọba òṣèlú, ọdún mẹrin-mẹrin ni wọn ńdìbò yan àwọn òṣèlú si ipò.  Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ni àwọn fẹ́ kọ àṣà ki àwọn Bàbá-ìsàlẹ̀ má a da òróró si orí ẹni ti wọn fẹ́ fún ẹgbẹ́ mọ́, ṣùgbọ́n ki wọn gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láyè lati yan ẹni ti yio fi iga gbága fún ipò òṣèlú pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Èyi ló dára jù fún ìjọba tiwa ni tiwa.

Gómìnà Àmbọ̀dé ṣí ọ̀nà mọ́kànlélógún – Gov. Ambode commissions 21 Lagos Roads

Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ńpalẹ̀mọ́ lati ṣe àpèjọ òṣèlú ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yio fi dìbò àkọ́kọ lati yan ẹni ti wọn fẹ lára àwọn ti ó ba jade fún ipò oselu. Lati ìgbà ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá ti fi ọwọ́ si ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti wọn fẹ́ yi, ni ìròyìn ti gbòde pé, ó ti bá ọmọ òṣèlú rẹ̀ Gómìnà Àmbọ̀dé  jà, ó sì ti da òróró lé orí Jídé Sanwóolú lati gba ipò lọ́wọ́ Gómìnà Àmbọ̀dé lẹhin ọdún mẹrin péré.  Eleyi kò yẹ kó fa ìbẹ̀rù tàbi àìsùn fún Gómìnà Àmbọ̀dé nitori àwọn iṣẹ́ ribiribi ti èrò ìpínlẹ̀ Èkó ri pé ó ti ṣe.  Àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ti ó jade lati du ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú Gómìnà Àmbọ̀dé ni Ọ̀gbéni Jídé Sanwóolú àti Ọbáfẹ́mi Hamzat.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button