Tag Archives: All Progressive Congress

Ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti yio du ipò fún ẹgbẹ́ kò yẹ kó fa ìjà laarin Gómìnà Àmbọ̀dé àti Bàbá Òṣèlú rẹ, Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu – Adoption of Direct Primary should not cause a rift between Gov. Ambode and his political Godfather former Gov. Bola Tinubu

Nínú gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú orílẹ̀ èdè Nigeria, àwọn alágbára díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ ni ó ńyan ẹni ti wọ́n fẹ́ ki o fi iga gbága fún ipò pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Ó ti di àṣà ki Gómìnà Èkó lo ọdún mẹrin nigbà méji tàbi ọdún mẹjọ lóri ipò Gómìnà.  Lati ìgbà òṣèlú alágbádá kẹrin ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kọkàndínlógún sẹhin ni orílẹ èdè Nigeria, ni ìpínlẹ̀ Èkó ti yan Bọ́lá Ahmed Tinubu si ipò Gómìnà.  Ìpínlẹ̀ Èkó fẹ́ràn Bọ́lá Tinubu, èyi jẹ́ ki ó di ẹni àmúyangàn fún gbogbo ẹgbẹ́ òṣèlú ti ó wà, nitori èyi ẹni ti ó bá fi ọwọ́ si, fún ipò òṣèlú ni àwọn èrò ìpínlẹ̀ Èkó mba fi ọwọ́ si.

Lẹhin ọdún mẹjọ ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá Tinubu pari àsìkò tirẹ̀, fún àìdúró iṣẹ ribiribi ti ó ṣe ni ìpínlẹ̀ Èkó, ó pẹ̀lú àwọn ògúná gbòngbò òṣèlú ti ó yan Gómìnà Babátúndé Rájí Fáṣọlá ti òhun naa lo ọdún mẹjọ. Gẹ́gẹ́ bi bàbá àgbà òṣèlú, Bọ́lá Tinubu da òróró si orí Gómìnà Àmbọ̀dé, èyi jẹ́ ki ó mókè ju gbogbo àwọn ti ó du ipò àti di Gómìnà ni ọdún kẹta sẹ́hìn, ti ó si fa ọ̀tá laarin ẹgbẹ́ àti àwọn ti ó du ipò Gómìnà fún Bọ́lá Tinubu.

Ipò Gómìnà tàbi ipò òṣèlú ki i ṣe oyè ìdílé ti kò ṣe é dù bi ìlú bá ti yan olóyè tán.  Ni ìjọba òṣèlú, ọdún mẹrin-mẹrin ni wọn ńdìbò yan àwọn òṣèlú si ipò.  Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ni àwọn fẹ́ kọ àṣà ki àwọn Bàbá-ìsàlẹ̀ má a da òróró si orí ẹni ti wọn fẹ́ fún ẹgbẹ́ mọ́, ṣùgbọ́n ki wọn gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láyè lati yan ẹni ti yio fi iga gbága fún ipò òṣèlú pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú yoku.  Èyi ló dára jù fún ìjọba tiwa ni tiwa.

Gómìnà Àmbọ̀dé ṣí ọ̀nà mọ́kànlélógún – Gov. Ambode commissions 21 Lagos Roads

Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ńpalẹ̀mọ́ lati ṣe àpèjọ òṣèlú ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yio fi dìbò àkọ́kọ lati yan ẹni ti wọn fẹ lára àwọn ti ó ba jade fún ipò oselu. Lati ìgbà ti Gómìnà tẹ́lẹ̀ Bọ́lá ti fi ọwọ́ si ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yan ẹni ti wọn fẹ́ yi, ni ìròyìn ti gbòde pé, ó ti bá ọmọ òṣèlú rẹ̀ Gómìnà Àmbọ̀dé  jà, ó sì ti da òróró lé orí Jídé Sanwóolú lati gba ipò lọ́wọ́ Gómìnà Àmbọ̀dé lẹhin ọdún mẹrin péré.  Eleyi kò yẹ kó fa ìbẹ̀rù tàbi àìsùn fún Gómìnà Àmbọ̀dé nitori àwọn iṣẹ́ ribiribi ti èrò ìpínlẹ̀ Èkó ri pé ó ti ṣe.  Àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú ti ó jade lati du ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú Gómìnà Àmbọ̀dé ni Ọ̀gbéni Jídé Sanwóolú àti Ọbáfẹ́mi Hamzat.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Gómìnà Èkó tẹ́lẹ̀, Bọ́lá Tinubu – ògúná gbòngbò Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwáju,́ fi ọwọ́ si ètò ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ dìbò yan ẹni ti wọn fẹ́ ni ipó – Former Lagos Gov. Bola Tinubu, an influential member of the All progressive Party backs the election of nominees by party members

Ki ìjọba alágbádá ìgbàlódé tó dé, Yorùbá ni bi wọ́n ṣe nṣe ètò ìlú.  Ètò ìlú ayé ìgbà àtijọ́ kò bẹ̀rẹ̀ tàbi pin si ọ̀dọ̀ Ọba àti Ìjòyè ìlú nìkan.  Ètò ìlú bẹ̀rẹ̀ lati ìdílé, nitori kò si ẹni ti kò ni olórí ẹbí tàbi àgbà ìdílé, lẹhin eyi, àdúgbò ni àgbà àdúgbò, bẹni abúlé-oko ni Baálẹ, ọjà ni olórí.

Ètò òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá bàjẹ́ lati igbà ti àwọn ológun ti bẹ̀rẹ̀ si fi ibọn gba ipò òṣèlú, nitori wọn kò náání Ọba tàbi Ìjòyè bẹni wọn kò kọ́ ológun ni iṣẹ́-òṣèlú bi kò ṣe ki wọn gbèjà ìlú tàbi orílẹ̀-èdè.  Ẹ̀yà mẹta ni Nigeria pin si tele – Yorùbá, Haúsá, Ìgbò, nṣe ètò agbègbè wọn, wọn ńsan owó-ori fún ìjọba àpapọ̀.  Ni ọ̀kànlélàádọ́ta ọdún sẹhin, ìjọba ológun da gbogbo ẹ̀yà mẹtẹta yi papọ̀ ki wọ́n tó pin si ẹ̀yà méjìlá si abẹ́ ìjọba àpapọ̀.  Lati igbà yi ni nkan kò ti rọgbọ.

Bọ́lá Tinubu, supports APC members electing their nominee

Ètò ti ìjọba-òṣèlú lọ́wọ́lọ́wọ́ – Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú, fẹ́ gbé kalẹ̀ lati yan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti yio gbé àpótí ìbò fún ipò òṣèlú nipa ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ lè dìbò yan ẹni ti ó bá wù wọ́n, dára gidigidi.  Tẹ́lẹ̀, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ni o ma ńdìbò fún àwọn ti wọn yio yàn lati gbe àpóti ìbò.  Eleyi ki i jẹ ki àwọn òṣèlú mọ ará ìlú tàbi ki ará ìlú mọ àwọn ti ó wà ni ipò òṣèlú nitori wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ìbò nitori wọn ni “Bàbá Ìsàlẹ̀” lẹhin.

Nigbati wọn lo ètò titun yi ni ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, lati yan ẹni yio gbe àpótí ìbò fún ipò Gómìnà Ọ̀ṣun, inú gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ dùn wi pé àwọn ni ipin àti yan àwọn òṣèlú.  Eleyi yi o jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ìlú lè mọ àwọn ti ó wà ni ipò òṣèlú olóri àjọ ìgbìmọ̀ kékeré, Gómìnà, aṣojú ni ipinlẹ̀ àti ni ìjọba àpapọ̀.

Gómìnà ipinlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀, Bọ́lá Ahmed Tinubu – ògúná gbòngbò Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwáju,́ ti polongo ètò ki àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ si dìbò yan ẹni ti wọn bá fẹ́ ni ipò.

ENGLISH TRANSLATION

Prior to the modern democratic dispensation, Yoruba ethnic group had their system of governance.  Governance in the olden days did not begin or end with the King and his Chiefs.  Governance begins with the family as everyone has a family head or elder, then each neighbourhood has a leader, farm settlements is led by their leader and markets have their leader too. Continue reading

Share Button