Tag Archives: No gas

“Èkó – Aginjù laarin àwọn Olú Ilú Àgbáyé”: “Lagos – A Jungle among the World Big Cities”

Èkó ni olú ilú Nigeria fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ki àwọn Ijọba Ológun tó kó Olú Ilú Nigeria lọ si Abuja ni bi ọdún mẹrinlélógún sẹhin.  Ki kó olú ilú kúrò ni Èkó kò din èrò ti o nwọ Èkó kù, ilú Èkó ngbòrò si ni, ṣùgbọn bi èrò ti npọ si, Ijọba àpapọ̀ kò ran Eko lọwọ nipa ipèsè owó tó tó ni àsikò fún ohun amáyédẹrùn.

Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀ - Heavy Lagos traffic. Courtesy: @theyorubablog

Sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀ – Heavy Lagos traffic. Courtesy: @theyorubablog

Ká fi Èkó wé àwọn olú ilú yoku ni àgbáyé àti àwọn ilú nla ti omi yi ká, inira Èkó pọ̀ ju àwọn ilú wọnyi lọ.  Kò si iná mọ̀nàmọ́ná ti ó ṣe deede, kò si omi mimu fún ará ilú pàtàki fún àwọn agbègbè titun.  Eyi ti ó burú jù ni ki èniyàn jade, kó má mọ igbà ti ó ma padà wọlé nipa li lo bi wákàti mẹ́fà tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ ninú sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ ọkọ̀, nitori ọ̀nà kò tó, bẹni kò dára, iwà-kuwà pọ̀ fún awakọ̀, ọkọ̀ àti èrò pọ̀ ju òpópó ọ̀nà lọ.

Bi Ijọba àpapọ̀ Nigeria ti ri owó ori gbà ni Èkó ju gbogbo àwọn ilú yoku lọ tó, kò si irànlọ́wọ́ lati tú ọ̀nà Ijọba àpapọ̀ ṣe.  Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Ijọba Ológun di Èkó lọ́wọ́ lati pèsè ọkọ̀ ojú irin ti ó ngbé èrò púpọ̀ ti Gómìnà Lateef Jakande bẹ̀rẹ̀.  Bi Èkó ti tóbi tó, ibùdókọ òfúrufú kan ló wà lójú kan naa ni Ìkẹjà fún àwọn ti ó nlọ si gbogbo àgbáyé àti àwọn ti ó fẹ́ lọ si ilú Nigeria miran.  Lati igbà ti Ijọba Ológun ti lé àwọn àjòjì ti ó dá ilé ọjà nla silẹ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àwọn Olówó ilú kò ronú lati ṣe irú ilé ọjà bẹ́ ẹ̀ si gbogbo agbègbè Èkó fún irọ̀rùn ará ilú ju bi gbogbo ọjà nla ti kó ori jọ si Erékùṣù Èkó.  Àwọn nkan wọnyi àti iwà ibàjẹ́ àti ojúkòkòrò Ijọba Ológun àti Alágbádá (Òṣèlú) ló sọ Èkó di aginjù laarin àwọn olú ilú àgbáyé.

A lérò wi pé Ijọba Òṣèlú ti àwọn ará ilú yàn fún “àyipadà” kúrò ninú iwà ibàjẹ́ tó gba orilẹ̀ èdè kan fún igbà pi pẹ́, yio wa àtúnṣe fún Èkó.  Gómìnà Akinwunmi Àmbọ̀dé ni lati wá àtúnṣe si iyà ti ojú ará ilú nri nipa gbi gbé ọkàn lé ọkọ̀ ilẹ́ fún ohun irinna nikan, nipa pi pari iṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin àti ibùdókọ̀ ojú omi ti Ijọba Gómìnà Babátúndé Raji Fáṣọlá bẹ̀rẹ̀, ki wọn si ṣe kun nipa ipèsè ibùdókọ òfúrufú àti ohun amáyédẹrùn yoku.

“Èkó kò ni bàjẹ́ o – ó bàjẹ́ ti”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-15 20:33:21. Republished by Blog Post Promoter