Tag Archives: Migrating

“Ibi ti à ńgbé là ńṣe…” – Ìfi ìdí kalẹ̀ ni Ìlú-Ọba – One should live according to the custom and fashion of the place where one find oneself in…” – Settling down in the United Kingdom

 Ẹ̀kọ́ púpọ̀ ni enia lè ri kọ́ ni irin àjò.  A lè rin irin àjò fún ìgbà díẹ̀ tàbi pípẹ́ lati bẹ ilú nã wò tàbi lati lọ tẹ̀dó si àjò.

wọ ọkọ̀ òfũrufu – Boarding Aeroplane. Courtesy: @theyorubablog

Oriṣiriṣi ọ̀nà ni enia lè gbà dé àjò, ṣùgbọ́n eyi ti ó wọ́pò jù láyé òde òni ni lati wọ ọkọ̀ òfũrufú, bóyá lati lọ kọ́ ẹ̀kọ si, lati ṣe ìbẹ̀wò, lati lọ ṣiṣẹ́ tàbi lati lọ bá ẹbi gbé (fún àpẹrẹ: ìyàwó lọ bá ọkọ, ọkọ lọ bá ìyàwó, ìyá/bàbá lọ bá ọmọ tàbi ọmọ lọ bá bàbá). Gbogbo ọ̀nà yi ni Yorùbá ti lọ lati dé Ìlú-Ọba.

Àṣepọ̀ laarin ará Ìlú-Ọba àti Yorùbá ti lè ni ọgọrun ọdún, nitori eyi, kò si ibi ti enia dé ni Ìlú-Ọba ni pataki àwọn Olú-Ìlú, ti kò ri ẹni ti ó ńsọ èdè Yorùbá tàbi gbé irú ilú bẹ.  A ṣe akiyesi pé lati bi ọdún mẹwa sẹhin, àṣepọ̀ laarin ọmọ Yorùbá ni Ìlú-Ọba din kù.  Ni ìgbà kan ri, bi ọmọ Yorùbá bá ri ara, wọn a ki ara wọn.

Òwe Yorùbá ni “Ibi ti a ngbe la nse; bi a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ a di ìkúùkù”, àwọn ọ̀nà ti a lè fi ṣe ibi ti a ngbe: Ki ka ìwé nipa àṣà àti iṣẹ ìlú ti a nlọ ninu ìwé tàbi ṣe iwadi lori ayélujára; wiwa ibùgbé; lọ si Ilé-Ìjọ́sìn; Ọjà; Ọkọ̀ wiwọ̀ àti bẹ̃bẹ lọ.

Ẹ fi ojú sọ́nà fún àlàyé lori àwọn ọ̀nà ti enia lè lò lati tètè fi idi kalẹ̀ ni àjò.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-03 23:45:42. Republished by Blog Post Promoter