Tag Archives: Drummer Lee Rigby

“Ká kú lọ́mọdé kó yẹni sàn ju ki á dàgbà ẹ̀sin” Ológun Onilù Lee Rigby relé: “To die honourable at a young age is better than aging in disgrace”

Lee Rigby: Military Funeral for killed Soldier

Lee Rigby: Military Funeral for killed Soldier

http://www.bbc.co.uk/news/uk-england-23263754

Òṣèlú, ìjọ, ẹbi àti ará ìlúoba ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún Onílù Lee Rigby ti o jade láyé lojiji lati ọwọ́ Michael Adébọ̀lájọ́ àti Michael Adébọ̀wálé ni oṣu karun ọdun yi.  Ilu dakẹ rọrọ fún ẹ̀sin nipa tí tò si ọ̀nà ti wọ́n gbé òkú rẹ gba lọ si ilé ijọsin.

Yorùbá ni “Ká kú lọ́mọdé kó yẹni sàn ju ki á dàgbà ẹ̀sin” fi han wípé bi ó ti jẹ ọmọ ọdún marun-lélógún ni nigbati ìṣẹ̀lẹ̀ ibi yi sẹlẹ̀, wọn si òkú Lee Rigby bi ọba.  Awọn ti o ge ẹ̀mí rẹ kúrú wà ni ọgbà ẹwọn, lati dàgbà ẹsin ninu ẹwọn.

Ki Ọlọrun tu ẹbi àti ọmọ Olõgbé ninu.  Sùn re o Onílù Lee Rigby.

ENGLISH TRANSLATION

The Politicians, the Church, Family and the people of the United Kingdom came together to pay their last respect to the late Soldier, Drummer Lee Rigby that met his untimely death in the hands of duo Michael Adebolajo and Michael Adebowale.  The Town stood still by lining the Street while the burial procession to the Church.

Yoruba adage said “It is better to die honourably at young age than to age with disgrace”.  This adage showed that even though Lee Rigby was only 25 years at the time of the unfortunate death, he was given a burial befitting for the King.  Those who cut his live short are in prison to age with disgrace in prison.

May God console his family especially his young son.  Rest in peace Drummer Lee Rigby.

Share Button

“Orúkọ rere sàn ju Wúrà ati Fàdákà”: Good name is better than Silver and Gold

Late Drummer Lee Rigby

Olõgbe Onílù Lee Rigby (ọmọ ọdun marunlélógún): Late Soldier Drummer Lee Rigby – aged 25

Olõgbe Onílù Lee Rigby (ọmọdun marunlélógún) fi orúkọ rere silẹ fun àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ẹgbẹ́ nigbàti àwọn apànìyàn Michael Adébọ́lájọ àti Michael Adébọ̀wálé ba orúkọ ẹbí wọn jẹ́.

Michael Adébọ́lájọ (ọmọ ọdun méjìdínlọ́gbọ̀n) àti Michael Adébọ̀wále (ọmọ ọdun méjìlélógún)  ti o pa Jagunjagun Onílù Lee Rigby ni Woolwich kò jẹ́wọ́ ọ̀rọ̀ Yorùbá tó sọ wípé “Orúkọ ní roni”  nítorí ìwà ìkà tí wọn hù.  “Michael” jẹ́ “Orúkọ Angẹli tó jẹ́ Olùgbèjà” ti àwọn “Onígbàgbọ́” mã nsọ ọmọ ni “ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ” tàbi “ọjọ Ìsàmì”.   “Adébọ́lájọ” túmọ̀ si wípé “Adé bá Ọla jọ” nígbàtí a lè túmọ̀ “Adébọ̀wálé” sí wípé “Adé padà wá sílé”.  Orúkọ ìdílé méjèèji yi jẹ́ orúkọ ìdílé Ọba tàbi Ìjòyè tí ó lè dé adé ni ilẹ̀ Yorùbá.

Orúkọ rere sàn ju Wúrà àti Fàdákà” nígbàtí àwọn ọmọ ìdílé bẹ̃ bá lo orúkọ nã dáradára, ṣùgbọn ìṣẹlẹ ibi yi ti ba orúkọ ìdílé Adébọ́lájọ àti Adébọ̀wálé jẹ́.

Gbogbo ọmọ Yorùbá àti Nigeria lápapọ̀ pàtàkì àwọn tí ó wà ni Ìlú-ọba, ṣe ìdárò Olõgbe Ajagun Onílù Lee Rigby, a sì gba àdúrà pé kí Ọlọrun kí ó tu ìdílé rẹ nínú.

ENGLISH TRANSLATION

Late Drummer Lee Rigby (aged 25) left a good name and legacy for his family, friends and colleagues while the “Killers Michael Adebolajo and Michael Adebowale” destroyed their family names.

Michael Adebolajo (aged 28) and Michael Adebowale (aged 22) that killed Soldier, Drummer Lee Rigby at Woolwich did not live up to the adage that said “Names do guide action” because of their evil act.  Michael “the name of an Angel that defend” that is often given by Christians to babies at birth during “Naming Ceremony” or “Baptism”.  “Adebolajo” means “Crown blends with wealth” while “Adebowale” means “The Crown returned Home”.  These two Family Names are commonly used by the “Yoruba Monarchs and the Chief’s family that can be crowned”.

According to the Yoruba adage “Good name is better than Silver and Gold” only when such family members use the names in a positive manner but in this case, Adebolajo and Adebowale family names have been destroyed as a result of this evil act.

Yoruba indigenes and all Nigerians particularly those in the United Kingdom mourn the loss of Late Soldier, Drummer Lee Rigby, and pray that God will console his family.

Share Button