Tag Archives: Education

“Iṣẹ́ ajé, sọ ọmọ nù bí òkò” – “Working for survival throws away the child like a stone”

jọ́ ti pẹ́ ti Yorùbá ti ńkúrò ni ilú kan si ilú keji, yálà fún ọrọ̀ ajé tàbi fún ẹ̀kọ-kikọ́.   Ni ayé àtijọ́, ọjọ́ pípẹ́ ni wọn fi ńrin irin-àjò nitori irin ti ọkọ̀ òfúrufú lè rin fún wákàtí kan, lè gba ọgbọ̀n ọjọ́ fun ẹni ti ó rin, tàbi wákàtí mẹrin fún ẹni ti ó wọ ọkọ̀-ilẹ̀ igbàlódé.  Eyi jẹ ki à ti gburo ẹbi tàbi ará ti ó lọ irin àjò ṣòro, ṣùgbọ́n lati igbà ti ọkọ̀ irin àjò ti bẹ̀rẹ̀ si wọ́pọ̀ ni à ti gburo ara ti bẹ̀rẹ̀ si rọrùn nitori Olùkọ̀wé le fi iwé-àkọ-ránṣé rán awakọ̀ si ọmọ, ẹbi àti ará ti ó wà ni olú ilú/agbègbè miran tàbi Òkè-òkun.

Inu oko ofurufu - Travellers on the plane.  Courtesy: @theyorubablog

Inu oko ofurufu – Travellers on the plane. Courtesy: @theyorubablog

Ninu oko ofurufu -  On the plane

Ninu oko ofurufu – On the plane. Courtesy: @theyorubablog

Yorùbá ni “Iṣẹ́ ajé, sọ ọmọ nù bí òko”.  Ki ṣe ọmọ nikan ni iṣẹ́-ajé sọnù bi òkò ni ayé òde oni, nitori ọkọ ńfi aya àti ọmọ silẹ̀; aya ńfi ọkọ àti ọmọ silẹ́, bẹni òbi ńfi ọmọ silẹ̀ lọ Òkè-òkun fún ọrọ̀ ajé. Ẹ̀rọ ayélujára àti ẹ̀rọ-isọ̀rọ̀ ti sọ ayé dẹ̀rọ̀ fún àwọn ti ó wá ọrọ̀ ajé lọ ni ayé òde oni, lati gburo àwọn ti wọn fi silẹ̀.

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-03-18 22:54:12. Republished by Blog Post Promoter