“Tori wèrè ìta la ṣe n ni wèrè inú ile”: Idibò lati yan Olóri Òṣèlú ni ọdún Egbãlemẹdógún – Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu Fakọyọ – “It takes a mad family member to confront an external aggression/madness”: Election 2015 Senator Bola Ahmed Tinubu was gallant

Ẹ̀rù ba onilé àti àlejò fún Nigeria nitori idibò à ti yan Olóri Òṣèlú à̀ti àwọn Òṣèlú yoku, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun pe ọjọ́ na ti wá, ó ti lọ, ilú ti yan Olóri Òṣèlú tuntun Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lati gba ipò lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Goodluck Ebele Jonathan.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú Alágboorun ti ó ti ṣe Ìjọba fún ọdún mẹrindinlógún, ti ṣe iléri wi pé àwọn yio wa lori oyè fún àádọ́ta ọdún nitori ẹgbẹ́ wọn ló pọ̀jù ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú.  Yorùbá pa òwe pé “À ti gba ọmọ lọ́wọ́ èkùrọ́, ki ṣe ojú bọ̀rọ̀” pàtàki, à ti gba ipò lọ́wọ́ Òṣèlú ki ṣe ojú bọ̀rọ̀.  Gẹ́gẹ́ bi òwe yi, ẹnikẹni mọ̀ pé Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ki fẹ gbé ipò silẹ̀.  Bi ó bá ṣe é ṣe wọn ò kọ lati kú si ipò, nitori wọn kò sin ará ilú.

Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu ṣe àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari  -  APC Rally

Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu ṣe àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari – APC Rally

Yorùbá sọ wi pé “Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọ̀yà”, lai si ipa ti Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu kó lati kó ẹgbẹ yoku mọ́ra àti àtilẹhin rẹ fún Ọ̀gágun Muhammadu Buhari lati  jade ni igbà kẹrin fun ipò Olóri Oselu, “Àyipadà” ti ará ilú fẹ́ kò bá ma ṣe e ṣe.

 

ENGLISH TRANSLATION  

There was fear of violence both at home and abroad on the Nigerian Presidential and other Elections, but thank God, the day has come and gone without any terrible violence as anticipated.  The people have elected General Muhammadu Buhari as the new President to take over from the incumbent President Goodluck Ebele Jonathan.

The Peoples’ Democratic Party (PDP) that has ruled for sixteen years, boasted that they will rule for fifty years because they are the largest party in Africa.  One of the Yoruba proverbs that said “Extracting the palm kernel is not an easy task”, can be applied to unseating an incumbent, particularly, unseating an incumbent in Africa is not an easy task.  According to this proverb, it is well known that African Politicians find it very difficult to hand over power.  If it is possible, they would rather die as incumbent than hand over, because they are not serving the people.

Another Yoruba adage meaning “In unity we stand”, was proven in the last election, because without the gallant effort of Senator Bola Ahmed Tinubu in galvanizing the many opposition parties together, his staunch support and encouragement of General Muhammadu Buhari to contest Presidential election the fourth time, people’s desire for “Change” would not have manifested.

Share Button

Originally posted 2015-04-03 21:08:29. Republished by Blog Post Promoter

4 thoughts on ““Tori wèrè ìta la ṣe n ni wèrè inú ile”: Idibò lati yan Olóri Òṣèlú ni ọdún Egbãlemẹdógún – Aṣiwájú Bọla Ahmed Tinubu Fakọyọ – “It takes a mad family member to confront an external aggression/madness”: Election 2015 Senator Bola Ahmed Tinubu was gallant

  1. Tinuade Bambe

    Mo gbadun lati ma so Yoruba ,nitori nigbamiran ti a ba nfi ede geesi ba eniyan soro itumo re ko ma nrinle to .Papa nigbati aba nse alaye oro ti oni se pelu amoran gbigba.

    Reply
    1. Bim A Post author

      Èniyàn mi, ọ̀rọ̀ gidi lẹ sọ, ọ̀pọ̀ igbà, ọ̀rọ̀ ma nsọnù si inú itumọ̀ èdè míràn.

      Reply
  2. Tinuade Bambe

    I love to speak Yoruba language,at times when you are speaking in English the real meaning may not be understood ,especially when you are giving advice or trying to tell someone about life .

    Reply

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.