Tag Archives: Xenophobic attacks

“A kì í fi Oníjà sílẹ̀ ká gbájúmọ́ alápepe – Pí pa Àjòjì ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú” – “One does not leave the person one has a quarrel with and face his/her lackey – Xenophobic attack in South Africa”

Foreign nationals stand with stones and bricks after a skirmish with locals in Durban.

Pí pa Àjòjì ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú – South Africa’s xenophobic attacks

Òwe Yorùbá kan sọ pé “Amúkun, ẹrù ẹ́ wọ́, ó ni ẹ̃ wò ìsàlẹ̀”.  Òwe yi ṣe é lò lati ṣe àyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ pí pa àjòjì ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú yoku, ti ó bẹ́ sílẹ ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ni oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlémẹ̃dógún.

Èniyàn dúdú ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú, jẹ ìyà lábẹ́ Ìjọba amúnisìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.  Ìfẹ́ Àlejò/Àjòjì ju ara ẹni, jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú jẹ ìyà lábẹ́ Aláwọ̀-funfun lati Òkè-òkun fún ìgbà pi pẹ́.  Ojúkòkòrò Aláwọ̀-funfun si ohun ọrọ̀ ti ó wà ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú pọ̀ si, nigbati ọkàn wọn balẹ̀ tán, wọn ṣe Ìjọba ti ó mú onílé sìn.  Ìjọba amúnisìn yi fi ipá gba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lati pin fún Aláwọ̀-funfun, wọn ṣe òfin lati ya dúdú sọ́tọ̀, pé dúdú kò lè fẹ́ funfun, wọn bẹ̀rẹ̀ si lo èniyàn dúdú bi ẹrú lóri ilẹ̀ wọn àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.  Àwọn èniyàn dúdú kò dákẹ́, wọn jà lati gba ara wọn sílẹ̀ ninú ìyà àti ìṣẹ́ yi, nitori eyi wọn pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹni wọn gbé àwọn Olóri Aláwọ̀dúdú púpọ̀ si ẹ̀wọ̀n ọdún àimoye.  Lára wọn ni “Nelson Mandela” ti ó lo ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni ẹ̀wọ̀n nitori ijà àti tú àwọn èniyàn rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ Ìjọba amúnisìn.

Ki ṣe ẹ̀yà Zulu tàbi ará ilu Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nikan ló jà lati gba òmìnira lọ́wọ́ Ìjọba Amúnusìn. Gbogbo àgbáyé àti ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú yoku dide pọ lati pa ẹnu pọ̀ bá olè wi.  Ni àsikò ijiyà yi, Ìjọba àti ará ilú Nigeria ná owó àti ara lati ri pé èniyàn dúdú ni Gúsù ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú gba òmìnira lóri ilẹ̀ wọn. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-21 18:18:36. Republished by Blog Post Promoter