Tag Archives: Tug of War

“Iwájú lèrò mbá èrò – Kò si ohun téni kan ṣe, téni kò ṣe ri” – “There is always someone ahead – Nothing is new”

Ọ̀rọ̀ ijinlẹ àti Òwe Yorùbá wà lati fi kọ́ ọgbọ́n àti imò bi èniyàn ti lè gbé igbésí ayé rere.  Ọ̀gá àgbà ninú Olórin ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú (Olóyè, Olùdarí Ebenezer Obey) kọ ninú orin ni èdè Yorùbá pé “ki lẹni kan ṣe, tẹni kan ò ṣe ri?”  Kò si owó, ọlá, ipò, agbára ti èniyàn ni, ti kò si ẹni tó ni ri tàbi ti ẹni ti ó mbọ̀ lẹhin kò lè ni.

Iwájú lèrò mbá èro -  Tug of War Game.

Iwájú lèrò mbá èro – Tug of War Game.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Iwájú lèrò mbá èrò” ṣe gba ẹni ti kò bá ni ìtẹ́lọ́rùn ni ìmọ̀ràn.  Ọjọ́ ori nlọ sókè ṣùgbọ́n ki wá lẹ̀.  Ai ni ìtẹ́lọ́rùn ló fa ki àgbàlagbà jowú ọmọdé nitori ọmọ àná ti ó rò pé kò lè da nkankan ti da nkan, tàbi ki ọ̀gá ilé-iṣẹ́ ma jowú ọmọ iṣẹ́.  Bi a bá ṣe akiyesi eré ije “Fi fa Okun” a o ri pé àwọn kan wà ni iwájú, bẹni àwọn kan wà lẹhin.  Èyi fihàn pé, “Ibi ti àgbà bá wà lọmọdé mba”, ṣùgbọ́n àgbà ti ṣe ọmọdé ri.

Ai ni ìtẹ́lọ́rùn lè fà ikú ójiji nitori àìsàn ẹ̀jẹ̀-riru, irònú, ijiyà iṣẹ́ ibi, olè jijà, ija, gbigbé oògùn olóró, èrú ṣi ṣe,  àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.  Bi èniyàn bá kọ́ ọgbọ́n ninú ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Iwájú lèrò mbá èro” yi, à ri pé, kò si ipò ti òhún wà ti kò si ẹni ti ó wà nibẹ̀ ṣáájú tàbi lẹhin òhun.  Ìmọ̀ yi kò ni jẹ́ ki èniyàn ṣi iwà hù, tàbi binú ẹni keji.  Ó ṣe pàtàki gẹ́gẹ́ bi ikan ninú orin (Olóyè Olùdari Ebenezer Obey), pe “Ipò ki pò, ti a lè wà, ká má a dúpẹ́ ló tọ́”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-08-25 20:10:57. Republished by Blog Post Promoter