Tag Archives: Tourists

“Ọ̀kọ́lé, kò lè mu ràjò” – “Home-owner cannot travel with his/her house”

IIé ihò inú àpáta – Cave House

Òrùlé wà lára ohun ini pàtàki ti ó yẹ ki èniyàn ni, ṣùgbọ́n èniyàn kò lè sun yàrá meji pọ̀ lẹ́ẹ̀kan.  Ki ṣe bi èniyàn bá fi owó ara rẹ̀ kọ́ ilé ni ìbẹ̀rẹ̀ ilé gbigbé.  Bàbá á pèsè òrùlé fún aya àti ọmọ, ki ba jẹ: ilé ẹbi, abà oko, ihò inú àpáta, ilé-àyágbé tàbi kọ́ ilé fún wọn.

Ni ayé òde oni, ilé ṣi jẹ ohun pàtàki fún èniyàn, ṣùgbọ́n á ṣe akiyesi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá, kò ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé “Ọ̀kọ́lé, kò lè mu ràjò” mọ́.  Ọ̀pọ̀ nkọ́ ilé àìmọye ti èniyàn ò gbé, lai ronú pé, bi àwọn bá ràjò, wọn ò lè gbé ikan ninú ilé yi dáni.  Ọ̀pọ̀ nkọ́ ilé fún àwọn ọmọ – fún àpẹrẹ, ẹni ti ó kọ ilé marun nitori ohun bi ọmọ marun si ilú ti wọn ngbé tàbi bi ọmọ si.

Ò̀we Yorùbá sọ pé “Ọ̀nà ló jin, ẹru ni Baba”.  Ẹ jẹ́ ki á fi òwe yi ṣe iranti pé, ayé ti lu jára, ọmọ, ẹbi àti ará kò gbé pọ̀ mọ́ bi igbà ayé-àgbẹ̀.  Bi wọn bá ti ẹ̀ gbé ilú kan naa, ìṣòro ni ki ọmọ bá Bàbá àti Ìyá gbé lọ lai-lai.  Bi ó pẹ́, bi ó yá, ọmọ tó dàgbà, á tẹ si iwájú nitori bi Bàbá bá kọ́ ilé rẹpẹtẹ si Agége, kò wúlò fún ọmọ ti o nṣiṣẹ ni Ìbàdàn, Àkúrẹ́ tàbi Òkè-òkun.  Bi Bàbá ti ó kọ ilé rẹpẹtẹ bá fẹ́ lọ ki àwọn ọmọ, ẹbi tàbi ọ̀rẹ́ ni ilú miran, ìṣòro ni ki ó gbé ikan ninú ilé rẹpẹtẹ yi dáni.

Ọ̀pọ̀ oníjìbìtì, Òṣèlú, Oníṣẹ́-Ìjọba ti ó ni ojúkòkòrò ló nkó owó ilé lọ sita lati lọ ra ilé si Òkè-Òkun lai gbé ibẹ̀, ju pé ki wọn lo o ni ọjọ melo kan lọ́dún.  Ìnáwó rẹpẹtẹ ni lati tọ́jú ilé si Òkè-Òkun tàbi ilé ti èniyàn kò gbé , nitori eyi, ọ̀pọ̀ ilé yi kò bá àwọn ti ó kọ́ ilé tàbi ra ilé kiri yi kalẹ̀. Àwọn Òṣèlu àti Oníṣẹ́ Ìjọba ti ó nja ilú lólè, lati fi owó ti wọn ji pamọ́ nipa ki kọ́ ilé rẹpẹtẹ tàbi ra ilé si Òkè-Òkun ni “Orúkọ ọmọ, òbí tàbi orúkọ ti kò ni itumọ”, kò lè gbé ilé wọnyi lọ irin àjò tàbi lọ si ọ̀run ti wọn bá kú.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-16 21:28:09. Republished by Blog Post Promoter