Tag Archives: Swimmer

Àjàpá àti Ọmọdé Mẹta – “Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́” – The Tortoise and the three playful children “A mouth that will not stay shut, the lips that will not stay closed, invites trouble for the cheek”

Ni abúlé Yorùbá nigbati ko ti si ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì tabi ẹ̀rọ amú-òhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ ayélujára, àwọn ọmọdé má nkó ara jọ lati ṣe eré lẹhin iṣẹ́ oojọ Bàbá àti Ìyá wọn.  Pataki, ni igba ọ̀gbẹlẹ̀ nigbati iṣẹ́ oko din kù.

Ọmọdé Mẹta - 3 young boys playing.  Courtesy: @theyorubablog

Ọmọdé Mẹta – 3 young boys playing. Courtesy: @theyorubablog

Àwọn ọmọdé kunrin mẹta bẹ̀rẹ̀ si ṣe eré ìdárayá leti òkun lai bikità ohun ti ó nlọ ni àyíká.  Ọmọ kini lérí pé ohun lè gun igi ọ̀pẹ pẹ̀lu ọwọ́ lásá̀n, ekeji ni ohun lè wẹ òkun yi já, ẹni kẹta ni ohun lè ta ọfà si ọ̀run.  Àjàpá gbọ́ gbogbo ìlérí àwọn mẹta yi ṣe, ó gbé ìròyìn lọ fún Ọba, pé ohun ti ri àwọn ti ó lè ṣe nkan ti ẹni kan kò ṣerí.  Ọba àti àgbà ìlú kò fẹ́ gba ohun ti Àjàpá wi gbọ́ nitori ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n o ni ki Ọba ṣe ohun ti ó bá fẹ́ fún ohun ti ìròyìn ti ohun mú wá kò bá ṣẹ.

Ọba ránṣẹ́ pé àwọn ọmọdé kunrin mẹta yi, pé ki wọn wa ṣe ohun ti wọn ṣèlérí pé wọn lè ṣe.  Yorùbá ni “Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́”.  Ìbẹ̀rù ba àwọn ọmọ yi, ẹbí wọn bẹ Ọba pe eré ọmọdé lásán ni àwọn ọmọ yi fi sọ gbogbo ohun ti wọn sọ, ṣùgbọ́n ẹ̀pa ò bóró mọ́ gbogbo ará ìlú (àti Àjàpá) ti pé jọ lati wòran.  Àwọn ọmọde mẹta yi bẹ̀rẹ̀ si kọ orin arò bayi:

 

Ọmọdé mẹ́ta nṣère

Éré o, érè ayọ̀ 2ce

Ọ̀kán lóhun yó gọ̀p

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀gọ̀pẹ, ọ̀gọ̀pẹ, ọ̀gọ̀p

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀kán lóhun yó wẹ̀kun

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀wẹ̀kun, ọ̀wẹ̀kun, ọ̀wẹ̀kun

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀kán lóhun ó tafà sọ́run,

Éré o, érè ayọ̀

Ọ̀tàfa, ọ̀tàfa, ọ̀tàfa

Éré o, érè ayọ̀.

Èyi ti ó ni ohun lè gun ọ̀pẹ, dé ìdí ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹkún.  O gun lẹ̃ kini, ó ṣubú, o gun lẹ̃ keji kọjá ibi tó dé ni àkọ́kọ́ ki ó tó ṣubú.  Èyi jẹ ki àwọn ará ìlú bẹ̀rẹ̀ si pàtẹ́wọ́ lati ki láyà, ó bá mú ọ̀pẹ gùn ni ẹ̃kẹta, ó́ gun dé orí.  Ariwo sọ, inú ará ìlú dùn.  Nigbati ọmọdé keji ti o ni ohun lè wẹ́ òkun ja, gbọ́ ariwo ìdùn nú yi, eleyi ki láyà.  Bi ti ẹni àkọ́kọ́, ọmọdé keji ti ó ni ohun lè wẹ òkun já, o wẹ dé odi keji, nibiti wọn ti fi ijó àti ayọ̀ pàdé rẹ.  Eleyi ló fún ọmọdé kẹta ni ìgboiyà pe ohun na lè ṣe ohun ti ohun ti ṣe ìlérí rẹ.  Ó ta ọfà lẹ̃ kini, ọfà na, kò rin jinà ki o to wálẹ̀.  O tã lẹ̃ keji, ọfà yi lọ bi ẹni pé kòní padà̀ si ilẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún wálẹ̀ .  Ni igbà kẹta ọfà na lọ sókè ọ̀run lai padà.  Ariwo sọ, ṣùgbọ́n ìtìjú bo Àjàpá. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-09-20 22:16:26. Republished by Blog Post Promoter