Tag Archives: Religious tolerance

“Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra” – “The sky is wide enough for the birds to fly without bumping into each other”

Ẹ̀sìn ti wa láyé, ki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi tó dé.  Fún àpẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ ninú “Ọlọrun” ti Yorùbá mọ̀ si “Òrìṣà-òkè” tàbi “Eledumare”.  Bi Yorùbá ṣe ḿbá Ọlọrun sọ̀rọ̀ ni ayé àtijọ́ ni ó yàtọ̀ si ti àwọn ẹlẹ́sìn igbàlódé.

Yorùbá ńlo “Ifá” lati ṣe iwadi lọ́dọ̀ “Ọlọrun”, ohun ti ó bá rú wọn lójú.  Yorùbá ma ńlo àwọn “Òrìṣà”  bi “Ògún”, “Olókun”, “Yemọja”, “Ọya”, “Ṣàngó” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bi “Onílàjà” larin èniyàn àti Eledumare.

Yorùbá ni “Ẹlẹkọ ò ni ki Alákàrà má tà”.  Ẹ̀sìn ti fa ijà ri, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, àti ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀, Onigbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ló ńṣe ẹ̀sìn wọn lai di ẹnikeji lọwọ.  Ni òkè-òkun, ẹni ti ó ni ẹ̀sìn àti ẹni ti kò ṣe ẹ̀sìn kankan ló ńṣe ti wọn lai di ara wọn lọ́wọ́.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán yi: Mùsùlùmi àti Onígbàgbọ́ ńṣe ìwàásu lẹgbẹ ara wọn.

Ó ṣe pàtàki ki ẹ ma jẹ ki àwọn Òṣèlú tàbi alai-mọ̀kan lo ẹ̀sìn lati fa ijà tàbi ogun, nitori “Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra”.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-05 13:05:43. Republished by Blog Post Promoter