Tag Archives: Oyo

Ẹ̀kọ́ àti Ọgbọ́n ni Ọ̀rọ̀ Àgbà lati Ẹnu Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ lórí Ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán Òpómúléró – Review of Words of Wisdom by Dr. Victor Omololu Olunloyo on Opomulero TV

Bi a ba fi eti si ọ̀rọ̀ ti àgbà Yorùbá Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ  ni ori ẹ̀rọ “Amóhùnmáwòrán Òpómúléró”, ni ori ayélujára, a o ṣe àkíyèsí àwọn nkan wọnyi:

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ fi àṣà Yorùbá ti ó ti ńparẹ́ hàn nipa bi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú “Oríkì”

Nínú ìtàn lati ẹnu agba, a o ri pé Bàbá loye lati kékeré.  Nkan bàbàrà ni ki ọmọ jade ni ilé ìwé giga ni ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ki ó si gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n ni ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.  Ni ọdún Ẹgbàádínméjìdínlógójì,  Gẹ́gẹ́ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ẹ̀kọ́ Ìṣirò, Ìjọba Ipinlẹ Ìwọ Oòrùn ayé ìgbà yẹn kò sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ kéré jú lati fún ni ipò Alaṣẹ lóri iṣẹ́ Ìdàgbàsókè Ìtọ́jú Owó.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ fihàn pé, lai si ni ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, kò ni ki á di ọ̀tá bi ti ayé òde òní.  A ri àpẹrẹ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ ṣe súnmọ́ Olóògbé Olóye Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tó, bi ó ti jẹ́ wi pé wọn kò si ninú ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, àwọn méjèèji jẹ olootọ ti ó si ni ìgboyà.

Ọgbọ́n ki i tán, bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ti kàwé tó, Bàbá ṣi ńkàwé lati wá ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ọgbọ́n púpọ̀ wà ni ọ̀rọ̀ àgbà yi, ẹ ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yi lóri Amóhùnmáwòrán Òpómúléró.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-03-30 20:39:07. Republished by Blog Post Promoter

“Ikú tó fẹ́ pani, bó bá sini ni fìlà, ọpẹ́ ló yẹ ká dá”: Idibò yan Òṣèlú ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún – “Escaping death by the whisker calls for gratitude”: Election of Twenty-fifteen

Ni igbà ipalẹ̀mọ́ idibò, ẹ̀rù ba ará ilú nitori wọn kò mọ ohun ti ó lè sẹlẹ̀.  Àwọn ti ó ndu ipò jade ni rẹpẹtẹ fún ètò-òṣèlú, eyi ti ó fa ki àwọn jàndùkú bẹ̀rẹ̀ ijà ti ó fa sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ pàtàki ni ilú Èkó, eleyi fa ibẹ̀rù pé ọjọ́ idibò yio burú.

Ẹgbẹ́ Onigbalẹ -  APC Logo

Ẹgbẹ́ Onigbalẹ – APC Logo

Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ ki i mi ni ikùn àgbà” ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ mi ni ikùn Ọba Èkó, Ọba Rilwanu Akiolu nigbati ó ṣe ipàdé pẹ̀lú àwọn àgbà Ìgbò Èkó, pé ti wọn kò bá dibò fún ẹni ti ohun fẹ, wọn yio bá òkun lọ.  Ọ̀rọ̀ Ọba Rilwanu Akiolu bi ará ilé àti oko ninú.  Eleyi tún dá kún ibẹ̀rù pé ija yio bẹ́ ni ọjọ́ idibò, nitori eyi ọpọlọpọ ará ilú ko jade lati dibò.

Gbogbo àgbáyé ló mọ̀ wi pé àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ki i fẹ gbé Ìjọba silẹ.  Ki ṣe pe wọn ni ifẹ́ ilu,́ bi kò ṣe pé, ó gbà wọn láyè lati lo ipò wọn lati ji owó ilú fún ara àti ẹbi wọn.  Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá pe “Ikú tó fẹ́ pani, bó bá sini ni fìlà, ọpẹ́ ló yẹ ká dá”, ikú tó fẹ́ pa ará ilú ti re kọja nitori ọjọ́ idibò lati yan Gómìnà àti Aṣòfin-ipinlẹ̀ ti lọ lai mú ogun dáni bi ará ilú ti rò.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò èsi idibò:

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-04-14 19:16:02. Republished by Blog Post Promoter