Tag Archives: Hunter

Jọ mi, Jọ mi, Òkúrorò/Ìkanra ló ndà – Insisting on people doing things one’s way, would turn one to an ill-tempered or peevish person

Yorùbá ni “Bi Ọmọdé ba ṣubú á wo iwájú, bi àgbà ba ṣubú á wo ẹ̀hìn”.  Bi enia bá dé ipò àgbà, pàtàki gẹ́gẹ́ bi òbí, àgbà ìdílé tàbi ọ̀gá ilé iṣẹ́, ẹni ti ó bá ni ìfẹ́ kò ni fẹ́ ki àwọn ti ó mbọ̀ lẹhin ṣubú tàbi ki wọn kùnà.

Ẹni ti ó bá fẹ ìlọsíwájú ẹnikeji pàtàki, ọmọ ẹni, aya tabi oko eni, ẹ̀gbọ́n, àbúro, ọmọ-iṣẹ, ọmọ ilé-iwé, aládúgbò, ẹbi, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti ará, a má a tẹnu mọ ìbáwí lati kìlọ̀ fún àwọn ti ó mbọ̀ lẹhin ki wọn ma ba a ṣìnà.  Eleyi lè jẹ ki irú àgbà bẹ́ẹ̀ dàbi onikọnra lójú ẹni ti nwọn báwí.  Fún àpẹrẹ ni ayé òde òní, bi òbí ba nsọ fún ọmọdé nígbà gbogbo pé ki ó ma joko si ori ayélujára lati má a ṣeré, ki ó lè sùn ni àsikò tàbi ki ó ma ba fi àkókò ti ó yẹ kó ka iwé ṣeré lóri ayélujára, bi oníkọnra ni òbí ńrí, ṣùgbọ́n iyẹn kò ni ki òbí ma ṣe ohun ti ó yẹ lati ṣe fún di dára ọmọ.

Yorùbá sọ wi pé, “Ajá ti ó bá ma sọnù, ki gbọ́ fèrè Ọdẹ”.  Ki ènìyàn ma ba di oníkọran, kò si ẹni ti ó lè jọ ẹnikeji tán, àwọn ibeji pàápàá kò jọra.  Bi ọkọ tàbi aya bá ni dandan ni ki aya tàbi ọkọ ṣe nkan bi òhun ti fẹ́ ni ìgbà gbogbo, ìkanra ló ńdà. Nitori èyi, bi enia bá ti ṣe ìkìlọ̀, ki ó mú ẹnu kúrò ti ó bá ri wi pé ẹni ti òhun ti báwí kò fẹ́ gbọ́.

ENGLISH TRANSLATION

According to a Yoruba adage, “When a child falls, he/she looks ahead, when an elder falls, he/she reflects on the past”.  When one reaches the position of an elder, particularly as a parent, family leader, a big boss, or a benevolent person would not want those coming behind or less experienced go astray or make the same mistake one has made in the past. Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-07-24 21:38:33. Republished by Blog Post Promoter

“Ori ló mọ iṣẹ́ àṣe là”: Ògbójú-ọdẹ di Adẹmu fún Ará-Ọ̀run – “Destiny determines the work that leads to prosperity”: Great Hunter became Palm-wine tapper for the Spirits

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.  Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá. Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ẹmu ni mo wá dá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Èlèló lẹmu rẹ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà
Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,
Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi.  Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ.  Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró.  Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run.  Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.  Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu.  Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́.  Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-18 20:50:09. Republished by Blog Post Promoter

Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ – If the Hunter thinks of the suffering in the wild, he would not share his kill with anyone.

Ọlọ́dẹ/Ọdẹ - Hunter

Ọlọ́dẹ/Ọdẹ – Hunter

Láyé àtijọ́, iṣẹ́ Ọdẹ jẹ ikan ninú iṣẹ gidi ni ile Yorùbá.  Ògbójú Ọdẹ ló npa ẹranko bi Erin, Ẹkùn, Kìnìún àti Ẹfòn, Ìmàdò, Ikõkò, nígbàtí àwọn to nṣe Ọdẹ etílé npa ẹranko ìtòsí ilé bi Ọ̀kẹ́rẹ́, Òkété, Ọ̀bọ àti bẹ̃bẹ lọ.  Ẹran ìgbẹ bi Ìgalà, Àgbọ̀nrín àti , ẹran ọ̀sìn bi Àgùntàn, Ewurẹ, Òbúkọ, Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ ẹran tí o wọ́pọ̀ fún jíjẹ ni ayé àtijọ dípò ẹran Mãlu tí ó wá wọpọ láyé òde òní.

Àwọn ẹranko bi Ẹfọ̀n, Erin, Kìnìún, Ẹkùn ti dínkù nígbàtí ẹranko bi Àgbánreré ti parẹ́ ni ilẹ̀ Yorùbá.

A lè fi ò̀we Yorùbá “Bi Ọdẹ bá ro ìṣẹ́ ro ìyà inú igbó, ti ó bá pa ẹran kòní fẹ́nì kan jẹ” wé ìyá ti àwọn ti ó wà ni Ìlúọba/Ò̀kèòkun njẹ nínú òtútù lati pa owó.  Nínú owó yi, wọn a ronú àti ran àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ti wọn gbìyànjú lati ràn lọ́wọ́, ki i wo ìya ti ojú wọn rí.

Ẹ rántí wípé ẹni ti o bá laanu ló lè ronú lati ran ẹlòmíràn lọ́wọ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-23 10:15:07. Republished by Blog Post Promoter