Tag Archives: Historian

“Bàbá Ìtàn Ìkọ̀lé-Èkìtì, Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí relé” – “The Father of History of Ikole-Ekiti, Late Professor Emeritus Ade Ajayi has gone home”

Babá re lé ò,
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Bàbá re lé ò,
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Ilé ò, ilé, Ilé ò, ilé,
Babá re lé ò,
Ilé ló lọ́ tarà-rà

Ni Àṣà Yorùbá, ọmọdé ló nkú, àgbà ki kú, àgbà ma nrelé ni.  Ọ̀fọ̀ ni ikú ọmọdé jẹ́, ijó àti ilú ni wọn fi nṣe ìsìnku àgbà lati sín dé ilé ikẹhin.  Ìròyìn ikú Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí kàn lẹhin ikú rẹ ni ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ,ọdún Ẹgbã-le-mẹrinla.  A bi ni ilú Ìkọ̀lé-Èkìtì ni ọdún marun-le-lọgọrin sẹhin.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọdé àti àgbà ilú lati onírúurú iṣẹ́àti àwọn èniyàn pàtàki ni ilé-lóko péjọ ni ọjọ kọkàn-din-logun, oṣù kẹsan,ọdún Ẹgbã-le-mẹrinla lati ṣe ìsìnku rẹ.

http://www.ngrguardiannews.com/news/national-news/179784-eulogies-as-eminent-scholar-ade-ajayi-is-buried

Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí - Late Professor Emeritus Ade Ajayi

Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí – Late Professor Emeritus Ade Ajayi

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé “Ẹni ti kò bá mọ ìtàn ara rẹ, yio dahun si orúkọ tí kò jẹ́”.  Ki awọn bi Olóògbé tó bẹ̀rẹ̀ si kọ Ìtàn Yorùbá àti ilẹ́ Aláwọ̀-dúdú silẹ̀, àwọn Aláwọ̀-funfun kò rò pé Aláwọ̀-dúdú ni Ìtàn nitori wọn kò kọ silẹ̀, wọn nsọ Ìtàn lati ẹnu-dé-ẹnu ni.  Nitori eyi, ohun ti ó wu Aláwọ̀-funfun ni wọn nkọ.  Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí, kọ́ ẹ̀kọ́, ó si gboyè rẹpẹtẹ lori Ìtàn, pàtàki lati jẹ́ ki Yorùbá mọ ìtàn ara wọn.  Ó lo imọ̀ yi lati kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwé itan, ikan lára iwé wọnyi ni “Ìtàn àti Ogun jijà Yorùbá”.  Ó tún kọ nipa Ìgbési-ayé “Olóògbé Olóri àwọn Alufaa Àjàyí Crowther” àti “Onidajọ Káyọ̀dé Ẹ̀ṣọ́”.

Yorùbá pa òwe pé “Àgbà ki wà lọ́jà, ki ori ọmọ titun wọ”, Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí ni Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, Èkó kẹta.  Nitori ìfẹ́ ti ó ni si ìdàgbà sókè Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, ìtàn àti ìpamọ́ ohun-ìtàn, ó kọ iwé si Olóri Òṣèlú Nigeria (Goodluck Ebele Jonathan), nigbà Ìporúkọdà lójiji lati Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó si orúkọ Olóògbé MKO Abiọ́lá – ti gbogbo ilú dibò fún lati ṣe Olóri Òṣèlú, ṣùgbọ́n àwọn Ìjọba Ológun kò jẹ́ kó dé ipó yi.  Olóri Òṣèlú Nigeria yi ọkàn padà lati ma yi orúkọ Ilé-ẹ̀kọ Giga yi padà lojiji nitori ọ̀wọ̀ ti ó ni fún Olóògbé. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-26 17:56:15. Republished by Blog Post Promoter