Tag Archives: Courtship

“Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi: ìyànjú fún àwọn omidan” – “There are two hundred and one suitors to a spinster, only one would make a good husband: Caution for ladies”

Ni ayé àtijọ́, òbi si òbi àti ẹbi si ẹbi ló nṣe ètò iyàwó fi fẹ́ fún ọmọ ọkùnrin ti ó bá ti bàláágà, ti wọn rò pé ó lè tọ́jú iyàwó.  Obinrin ki tètè bàláágà, nitori ki wọn tó bẹ̀rẹ̀ si ṣe nkan oṣù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin ma ndàgbà tó bi ọdún mẹrin-din-lógún tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ.  Gẹgẹ bi wọn ti ma nsọ ni igbà igbéyàwó ibilẹ “òdòdó kán wà lágbàlá ti a fẹ́ já”, bi òbi tàbi ẹbi bá ṣe akiyesi ọmọ obinrin ti ó wù wọn lati fẹ́ fún ọmọ ọkunrin wọn, yálà idilé si idilé tàbi ni agbègbè ni ibi “ọdún omidan”, wọn yio lọ bá òbi/ẹbi obinrin na a lati bẹ̀rẹ̀ ètò bi wọn yio ti fẹ fún ọmọ wọn. Ni ayé igbàlódé, obinrin yára lati bàláágà, nitori omiran a bẹ̀rẹ̀ nkan oṣú ni bi ọmọ ọdún mọ́kànlá.  Obinrin ki yára fẹ́ ọkọ mọ nitori ilé-iwé àti pé ki ṣe òbi àti ẹbi ló nfẹ́ obinrin fún ọmọ ọkùnrin mọ.

Yorùbá ma nlò ọ̀rọ̀ ti ó sọ pé “Ọ̀kan-lé-nigba lọkọ ọmọge, ikan ori rẹ ni ọkọ gidi” lati la obinrin lóye pé ki ṣe gbogbo ọkunrin ti ó bá wá bá obinrin lati sọ̀rọ̀ ifẹ́ ló ṣe tán lati fẹ́ iyàwó, gbogbo wọn kọ́ si ni “ọkọ gidi”.  Kò yẹ ki obinrin kanra tàbi lé ọkùnrin ti ó bá kọ ẹnu ifẹ́ si wọn pẹ̀lú èébú, nitori Yorùbá sọ wipé, “A kì í kí aya-ọba kó di oyún” ṣùgbọ́n ki wọn farabalẹ̀ lati mọ irú ẹni ti ọkùnrin na a jẹ.  Li lé ọkùnrin nigbati ọ̀pọ̀ ọkùnrin bá fẹ́ yan obinrin lọrẹ, pàtàki ni igba ti obinrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bàláágà, lè fa ki obinrin ṣe àṣimú ni igba ti wọn bá ṣe tán lati fẹ́ ọkọ, nitori ó ti lè bọ́ si àsikò ikánjú. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-03 21:50:24. Republished by Blog Post Promoter