Tag Archives: Britain Europe

ÀṢÀ ÌDÁBẸ́: A Culture of Female Genital Mutilation #IWD

Ìdábẹ́ jẹ ìkan nínú àṣà Yorùbá tí ólòdì si ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.  Gẹ́gẹ́bí ìtàn ìdábẹ́, Yorùbá ndabẹ fún ob̀nrin ní àti ìkókó títí dé ọmọ ọdún kan,  nwọn ní ìgbàgbọ́ wipe yio da ìṣekúṣe dúró lára obìnrin.

Tiítí òde òní, àṣà Yorùbá ṣì nfi ìyàtọ̀ sí àárín obìnrin ati ọkùnrin, ní títọ́ àti ní àwùjọ.  Gẹ́gẹ́bí Olókìkí Oló́rin Jùjú Ebenezer Obey ti kọ́ lórin: “Àwa ọkùnrin le láya mẹ́fà, kò burú, ọkùnrin kan ṣoṣo lọba Olúwa mi yàn fún obìnrin”.

Gẹ́gẹ́bí Ìwé Ìròyìn Ìrọ̀lẹ́ ti ìlú London, ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta, ọdún ẹgbẹ̀rún méji léní mẹ́tàlá, wọn ṣe àkíyèsí wípé àṣà ìdábẹ́ wọ́pọ̀ lãrin àwọn ẹ̀yà tó kéréjù ní Ìlú-Òyìnbó.  Wọ́n ṣe àlàyé àlébù tí àṣà burúkú yi jẹ́ fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá dábẹ́ fún, ara àlébù bi: ọmọ lè kú ikú ẹ̀jẹ̀ dídà, ìṣòro tí irú ẹni bẹ bá fẹ tọ̀, ìsòro ní ìgbà ìbímọ àti bẹbẹ lọ. Ìjọba ti pèsè owó pùpọ̀ lati fi òpin sí àṣà ìdábẹ́ ní Ìlú-Ọba.

Bí a ti nṣe àjọ̀dún “Ọjọ́ áwọn Obìnrin lagbaaye,” oṣe pàtàkì kí Yorùbá ní ilé àti ní àjò, di àṣà tí ó bùkún àwọn ọmọ mú, kí a sì ju àṣà tí ó mú ìpalára dání dànù.  Ìdábẹ́ kò lè dá ìṣekúṣe dúró, nítorí kò sí ìwáìdí pé bóyá ó dá tàbí dín ìṣekúṣe dúró lãrin obìnrin.  Ẹ̀kọ́ áti àbójútó lati ọ̀dọ́ òbí/alabojuto ló lè dá ìṣekúṣe dúró, ki ṣe ìdábẹ́.

English translation below:

THE CULTURE OF FEMALE GENITAL MUTILATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-03-08 17:47:03. Republished by Blog Post Promoter