Tag Archives: Barrel

“Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro” – “Empty barrel makes most noise”

Àgbá ti ó kún fún epo-rọ̀bì – Barrel full of Crude oil

Àgbá ti ó kún fún epo-rọ̀bì – Barrel full of Crude oil

Àgbá ti ó kún fún ohun ti ó wúlò bi epo-rọ̀bì, epo-pupa, epo-òróró, epo-oyinbo, ọ̀dà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ki pariwo.  Àgbá òfìfo, kò ni nkan ninú tàbi o ni nkan díẹ̀, irú àgbá yi bi o ti wù ki ó lẹ́wà tó, ni ariwo rẹ máa ńpọ̀ ti wọn ba yi lóri afárá tàbi ori titi ọlọ́dà.

Oil-Barrels-2619620

Àgbá òfìfo ti ó lẹ́wà – Colourful empty barrels

Àgbá òfìfo ni àwọn ti ó wà ni òkè-òkun/ilú òyìnbó ti ó jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati wá ṣe àṣehàn ti wọn bá ti àjò bọ, ohun ti wọn kò tó wọn a pariwo pé àwọn jù bẹ́ẹ̀ lọ.  Ni tòótọ́, ìyàtọ̀ òkè-òkun/ilú-òyìnbó si ilẹ̀ Yorùbá ni pé, àti ọlọ́rọ̀ àti aláìní ló ni ohun amáyé-dẹrùn bi omi, iná mọ̀nà-mọ́ná, titi ọlọ́dà, ilé-iwé gidi, igboro ti ó mọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.  Àwọn Òṣèlú kò kọjá òfin, bẹni irònú wọn ki ṣe ki á di Òṣèlú lati kó owó ilú jẹ.

Ni ayé àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá, owó kọ́ ni wọn fi ńmọ ẹni gidi, àpọ́nlé/ọ̀wọ̀ wà fún àgbà, ẹni ti ó bá kàwé, olootọ enia, ẹni tó tẹpá mọ́ṣẹ́,  akin-kanjú àti ẹni ti ó ni òye.  Ni ayé òde òni, àgbá òfìfo ti pọ ninú ará ilú, àwọn Òṣèlú àti àwọn òṣiṣẹ́ ijọba.  Bi wọn bá ti ri owó ni ọ̀nà èrú, wọn a lọ si òkè-òkun/ilú-òyìnbó lati ṣe àṣehàn si àwọn ti wọn bá lọhun lati yangàn pẹ̀lú ogún ilé ti wọn kọ́ lai yáwó, ọkọ̀ mẹwa ti wọn ni, ọmọ-ọ̀dọ̀ ti wọn ni àti ayé ijẹkújẹ ti wọn ńjẹ ni ilé.  Wọn á ni àwọn kò lè gbé òkè-òkun/ilú-òyìnbó, ṣùgbọ́n bi àisàn bá dé, wọn á mọ ọ̀nà òkè-òkun/ilú-òyìnbó fún iwòsàn àti lati jẹ ìgbádùn ohun amáyé-derùn miran ti wọn ti fi èrú bàjẹ́ ni ilú tiwọn.

Bi àgbá ti ó ni ohun ti ó wúlò ninú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni gidi tó ṣe àṣe yọri ki pariwo. Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni “Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro”, bá ẹni-kẹ́ni ti ó bá ńṣe àṣehàn tàbi gbéraga wi pé ki wọn yé pariwo ẹnu.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-08-08 18:20:28. Republished by Blog Post Promoter