Tag Archives: Agriculture

“Iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́” – “Work is the antidote for destitution/poverty”

Orin fun Àgbẹ̀:                            Yoruba song encouraging farming:
Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ni iṣẹ́ ilẹ̀ wa a,               Farming is the job of our land
Ẹni kò ṣiṣẹ́, á mà jalè,                  He who fails to work, will steal
Ìwé kí kọ́, lai si ọkọ́ àti àdá         Education without the hoe and cutlass (farm tools)
Kò ì pé o, kò ì pé o.                      Is incomplete, it is incomplete

Orin yi fi bi Yorùbá ti ka iṣẹ abínibí àkọ́kọ́ si hàn.  Olùkọ́, a má kọ àwọn ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ni orin yi lati kọ wọn bi iṣẹ́-àgbẹ̀ ti ṣe kókó tó, nitori eyi, bi wọn ti nkọ́ iwé, ki wọn kọ́ iṣẹ́-àgbẹ̀ pẹ̀lú.  “Olùpàṣẹ, ọ̀gá ninú Olórin Olóyè Ebenezer Obey” fi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Bi ebi bá kúrò ninú ìṣẹ́, ìṣẹ́ bùṣe” kọrin.  Àgbẹ̀ ni ó npèsè oúnjẹ ti ará ilú njẹ àti ohun ọ̀gbin fún tità ni ilé àti si Òkè-òkun.

Àgbẹ̀ - Local African Farmer

Àgbẹ̀ – Local African Farmer

Owó Àgbẹ ni Nàíjíríà fi ja ogun-abẹ́lé fún ọdún mẹta lai yá owó ni bi ọdún mẹta-din-laadọta titi di ọdún mẹrin-le-logoji sẹhin.  Lẹhin ogun-abẹ́le yi, Naijiria ri epo-rọ̀bì ni rẹpẹtẹ fún tita si Òkè-òkun.  Dipò ki wọn fi owó epo-rọ̀bì yi pèsè ẹ̀rọ oko-igbálódé fún àwọn Àgbẹ̀ lati rọ́pò ọkọ́ àti àdá, ṣe ni wọn fi owó epo-rọ̀bì ra irà-kurà ẹrù àti oúnjẹ lati Ò̀kè-òkun wọ ilú.  Eyi ló fa ifẹ́-kufẹ si oúnjẹ àti ohun ti ó bá ti Oke-okun bọ̀ titi di òni.

Gẹ́gẹ́ bi Ọba-olórin Sunny Ade ti kọ́ lórin pé “Kò si Àgbẹ̀ mọ́ lóko, ará oko ti dari wálé”.  Gbogbo ará oko ti kúrò lóko wá si ilú nlá lati ṣe “iṣẹ́-oṣù tàbi iṣẹ́-Ìjọba” dipò iṣẹ́-àgbẹ̀.  Owó iná-kuna yi sọ ọ̀pọ̀ di ọ̀lẹ nitori ó rọrùn lati ṣe iṣẹ́ oṣù ni ibòji ilé-iṣẹ́, lẹhin iwé-mẹfa tàbi iwé-mẹwa ju ki wọn ṣe iṣẹ́-àgbẹ̀ lọ.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Iṣẹ́ loògùn ìṣẹ́” kò bá ohun ti o nṣẹ lẹ̀ ni ayé òde òni lọ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́-Ijọba tàbi oniṣẹ́-oṣù wà ninú ìṣẹ́, nitori wọn kò ri owó gbà déédé mọ, bẹni àwọn ti ó fẹhinti lẹ́nu iṣẹ́ kò ri  owó-ifẹhinti gbà nitori Ìjọba Ológun, Òṣèlú àti Ọ̀gá ilé-iṣẹ́ ngba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọn nja ilé-iṣẹ́ àti  ilú ló olè nipa ki kó owó jẹ.

Oriṣiriṣi iṣẹ́-ọwọ́ àti òwò ló wà yàtọ̀ si iṣẹ́-àgbẹ̀.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, “Ọ̀nà kan kò wọ ọjà, ló mú telọ (aránṣọ) tó nta ẹ̀kọ”. Ohun ti oniṣẹ́-oṣù àti òṣiṣẹ́-Ìjọba lè ṣe lati lo iṣẹ́ fún oògùn ìṣẹ́ ni, ki wọn ni oko lẹgbẹ pẹ̀lú iṣẹ́-oṣù tàbi ki wọn kọ́ iṣẹ́-ọwọ́ miran ti wọn lè ṣe lẹhin ifẹhinti.

ENGLISH TRANSLATION
Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-16 22:22:59. Republished by Blog Post Promoter