Tag Archives: 1914 Amalgamation

“A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” – Ìdàpọ̀ Àríwá àti Gũsu Nigeria: – 1914 Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria

Ó pé ọgọrun ọdún ni ọjọ́ kini, oṣù kini ọdún Ẹgba-̃le-mẹrinla ti Ìjọba Ìlú-Ọba ti fi aṣẹ̀ da Àríwá àti Gũsu orílẹ̀ èdè ti a mọ̀ si Nigeria pọ.  Ìjọba Ìlú-Ọba kò bere lọwọ ará ilú ki wọn tó ṣe ìdàpọ̀ yi, wọn ṣe fún irọ̀rùn ọrọ̀ ajé ilú ti wọn ni.

Yorùbá ni “À jọ jẹ kò dùn bi ẹni kan kò ri”.  Ni tõtọ, Ijọba Ilu-Ọba ti fún orilẹ̀ èdè Nigeria ni ominira, ṣùgbọ́n èrè idàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ kò tán.  Gẹgẹbi Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ nigbati wọn ńṣe àdéhùn fún ominira pe: “ominira ki ṣe ni ti orúkọ ilú lásán, ṣùgbọ́n ominira fún ará ilú.  A ṣe akiyesi pe lẹhin ìdàpọ̀ ọgọrun ọdún, orilẹ̀ èdè ko ṣe ikan.

Yorùbá ni “A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ” Gẹgẹbi òwe yi, ki ṣe ki kó ọ̀kẹ́ aimoye owó lati ṣe àjọyọ̀ ìdàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ ló ṣe pàtàki, bi kò ṣé pé ki a tó ọ̀rọ̀ bára sọ.

Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ la fi dá ilé ayé”.  Bi ọkọ àti iyàwó bá wà lai bára sọ̀rọ̀, igbéyàwó á túká, nitori eyi, ó ṣe pàtàki ki gbogbo ara ilú Nigeria lápapọ̀ ṣe àpérò bi wọn ti lè bára gbé ki ilú má bã túká.

ENGLISH TRANSLATION

“One does not qualify to live with a person without also qualifying to talk to the person” – Amalgamation of the Northern and Southern Nigeria Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-07 23:11:15. Republished by Blog Post Promoter