Ni Iránti Bàbá Ẹgbẹ́ Òṣèré Nigeria: Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde – In Memory of “Father of Nigerian Theatre”: Late Chief Hubert Adedeji Ogunde

Ẹbi, ará, iránṣẹ́ Ìjọba àti àwọn ọmọ Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde pé jọ ni ọjọ́ kẹrinlélógún oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, ni ilú Ìjẹ̀bú Ọ̀sọ̀sà ti ipinlẹ̀ Ògùn lati ṣe irànti.  Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde jade láyé ni ọjọ́ kẹrin, oṣù kẹrin ọdún mẹ̃dọgbọn sẹhin.

Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde – Late Chief Hubert Adedeji Ogunde

Eré ṣi ṣe bẹrẹ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin nigbati Yorùbá ba nṣe ọdún Eégún, eyi ti wọn fi nṣe iránti àwọn Bàbánlá Yorùbá.  Ni àsikò ọdún eégún, orin, ilú àti ijó ni wọn fi nda ilú lára yá pàtàki ni iwájú ilé Ọba. Nigbati Yorùbá gba ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, dipò ọdún eégún, ọdún Ìgbàgbọ́ bi Ajinde àti Kérésìmesì ni ọmọ ilé-iwé ọjọ́ Ọ̀sè ma nṣe eré itàn Bibeli lati dá ijọ lára yá.  Lára àwọn Òṣèré Yorùbá ti ó ti ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ jade ni Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde, Olóògbé Kọ́lá Ògúnmọ́lá àti Olóògbé Dúró Ládipọ̀.

Itàn gbi gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ pẹ̀lú eré, ilú àti orin kọjá ilẹ̀ Yorùbá titi dé Òkè-òkun kò pé lai sọ nipa Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde ti ó kọ́kọ́ dá “Ẹgbẹ́ Iṣẹ́ Òṣèré” silẹ̀ ni aadọrin ọdún sẹhin.  Olóògbé Ogunde lo ẹ̀bùn ti ó ni fi gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ gidigidi.

Gẹ́gẹ́ bi ikan ninú orin àti eré ti Olóògbé Ogunde ṣe “Yorùbá Ronú”, bi Yorùb́a bá ronú, ki ṣe ẹbi nikan ló yẹ ki ó tọ́jú ohun ti Ologbe fi silẹ̀.  Ó yẹ ki Ìjọba, pàtàki Ìjọba àwon ipinlẹ̀ Yorùbá para pọ̀ lati tọ́jú ogún “ilé iṣẹ́ Òṣèré ni Ọ̀sọ̀sà” fún li lò àwọn ọ̀dọ́ àti Òṣèré ni iránti Olóògbé Olóyè Hubert Adédèji Ogunde.

ENGLISH TRANSLATION

Family, friends, Government representatives and the children of Late Chief Hubert Adedeji Ogunde gathered on twenty fourth of April, Twenty-fifteen at Ijebu Ososa in Ogun State in remembrance of the deceased.  Late Chief Hubert Adedeji Ogunde departed the world on the fourth day of April Twenty-five years ago.

Entertainment or Play began several years ago during Yoruba Masquerade Festival, which was used in remembering the Yoruba Ancestors.  During the Masquerade Festival, music, drumming and dancing were used to entertain the community particularly in front of the King’s Palace.  When Yoruba adopted Christianity, instead of Masquerade Festival, Sunday School Pupils entertained with plays based on Bible stories during Christian Festival particularly Easter and Christmas.  Among the prominent Yoruba Actors with Christian background were Late Chief Hubert Adedeji Ogunde, Late Kola Ogunmola and Late Duro Ladipo.

The history of promoting Yoruba language and culture Oversea through theatre with plays, drumming and music beyond the shore of Nigeria would be incomplete without Late Chief Hubert Adedeji Ogunde who began the first “Professional Theatrical Company”, seventy years ago.  Late Ogunde used his talent to promote Yoruba language and culture extensively.

According to one of the songs and play of Late Ogunde titled “Yoruba, Think!”, if Yoruba are thinking, the preservation of the great legacy of Late Ogunde ought not to be left to only the family.  The Nigerian Government, in particular Western States Government should come together to renovate and preserve the “Hubert Ogunde Film Village” at Ososa (his home town) for the use of the Youths and Actors and as a Memorial Centre for Late Chief Hubert Adedeji Ogunde.

Share Button

Originally posted 2015-05-05 19:24:57. Republished by Blog Post Promoter

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.