Category Archives: Yoruba Community

“Ìbẹ̀rẹ̀ kọ́ ló niṣẹ́” – Ẹ jade lọ dibò fún Gómìnà àti Aṣòfin Ipinlẹ̀ Orilẹ̀ Edè Nigeria: “The race is not to the swift” – Go out to vote to elect Governors and State Legislators in Nigeria

Ipinlẹ̀ Orilẹ̀ Edè Nigeria - States in Nigeria

Ipinlẹ̀ Orilẹ̀ Edè Nigeria – States in Nigeria

À ṣe kágbá Idibò ni orilẹ̀ èdè Nigeria yio wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkọ̀nlá, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlémẹ̃dógún, lati yan Gómìnà àti àwọn Aṣòfin Ipinlẹ̀ mẹrindinlọ́gbọ̀n.

A dúpẹ́ pé ilú jade lati dibò yan Olóri Òṣèlú àti àwọn Aṣòfin-àgbà lai mú ijà dáni bi gbogbo ilú ti bẹ̀rù pé yio ri oṣù tó kọjá.  Yorùbá sọ wi pé “Ìbẹ̀rẹ̀ kọ́ ló niṣẹ́” a fi ọ̀rọ̀ yi rọ ará ilú pé ki wọn tu jade lati dibò nitori Ìjọba àpapọ̀ kò súnmọ́ ará ilú bi ti Gómìnà àti Aṣòfin Ipinlẹ̀, ki wọn lè jẹ èrè Ìjọba Alágbádá.

 

ENGLISH TRANSLATION

In Nigeria, the final day of election is coming up on Saturday, eleventh day of April, Two thousand and fifteen, to elect Governors and State Legislators in thirty-six States.

Nigerians are grateful that people trooped out last month to cast their votes to elect the President, Senators and Federal Legislators without serious violence as people feared it would be.   Federal Government is not as close to the grass root like the Governors and the State Legislators hence, one of the Yoruba adage meaning “The race is not for the swift” is being used to encourage people to come out massively to cast their votes so that the people can enjoy the benefits of Democracy.

Share Button

Originally posted 2015-04-10 11:47:34. Republished by Blog Post Promoter

Àjọ̀dún Òmìnira Nigeria Kẹrindinlọgọta – Nigeria’s Fifty-six Independence Celebration

Àjọ̀dún Òmìnira Nigeria Kẹrindinlaadọta – Nigeria’s Fifty-six Independence Celebration.  Courtesy: @theyorubablog

Àjọ̀dún Òmìnira Nigeria Kẹrindinlaadọta – Nigeria’s Fifty-six Independence Celebration. Courtesy: @theyorubablog

Share Button

Originally posted 2016-10-01 00:37:30. Republished by Blog Post Promoter

Ayẹyẹ Aadọrun ọjọ́ ibi Alhaji Lateef Káyọ̀dé Jakande, Gómìnà Alágbádá Àkọ́kọ́ ti Ìpínlẹ̀ Èkó – Celebration of 90th Birthday of Alhaji Jakande, first Executive Governor of Lagos State

Èkó jẹ́ Olú-Ilú Nigeria fún ọdún mẹ́tàdinlọ́gọrin, ṣùgbọ́n idikọ fún òwò àti ọrọ̀ ajé lati ẹgbẹgbẹ̀run ọdún sẹhin titi di ọjọ́ oni.  “Ta ló lè mọ ori ọlọ́là lágbo?”  Gbogbo àgbáyé ló nwá lati ṣe ọrọ̀ ajé ni ilú Èkó, òbí Gómìnà Jakande kò yàtọ̀ nitori wọ́n wá lati Òmù-Àrán, ti ó wà ni ìpínlẹ Kwara lati wá ṣe òwò ni Eko bi ti gbogbo èrò lai mọ wi pé ọmọ ọkùnrin ti Ọlọrun fi ta wọ́n lọ́rẹ ni ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje ọdún Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàlémọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹ́hin ni agbègbè Ẹ̀pẹ́tẹ̀dó ni Ìsàlẹ̀-Èkó, yio di Gómìnà Alágbádá Àkọ́kọ́ ti Ìpínlẹ̀ Èkó ni ọjọ́ kan.

Àwọn Gómìnà Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan pẹ̀lú– Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Olóri- Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan
Apá-òsi si ọ̀tún: Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ambrose Ali – Ìpínlẹ̀ Bendel; Olóògbé Pa Adékúnlé Ajáṣin – Ìpínlẹ̀ Ondó, Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ – Olóri- Ẹgbẹ́ Ìṣọ̀kan, Olóògbé Olóyè Bisi Ọnabanjọ – Ìpínlẹ̀ Ògùn, Alhaji Lateef Jakande – Ìpínlẹ̀ Eko àti Olóògbé Olóyè Bọ́lá Ìgè

 

Ore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni ki èniyàn dàgbà darúgbó di aadọrun ọdún láyé.  Ki ṣe pi pẹ́ láyé lásán, ṣùgbọ́n ki a  lo àsìkò, ẹ̀bùn àti ẹ̀kọ́ ti a bá ni lati sin ẹlòmíràn gẹ́gẹ́bi Alhaji Lateef Jakande ti fi ipò Òṣèlú tirẹ̀ sin Ìpínlẹ̀ Èkó.  Kò si ẹni ti ó ńgbé ni Ìpínlẹ̀ Èkó ti kò jẹ ninú iṣẹ́ ribiribi, ti Alhaji Jakande ṣe si Ìpínlẹ̀ Èkó. Lára àwọn iṣẹ́ ná à ni:

 

Ìjọba Gómìnà Jakande ni igbà tirẹ̀ dá:

Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsi àti ilé-iṣẹ́ amóhùn-máwòrán sile,

Ki kọ́ Ilé-ìwé ọ̀fẹ́ ti o sọ ilé-iwe li lọ lati iṣipo mẹta lójúmọ́ di ìgbà kan fún gbogbo ọmọ ilé-ìwé

Di dá Ilé-iwe giga Ipinle àkọ́kọ́ ni Orilẹ̀-èdè Nigeria sílẹ̀

Bi bẹ̀rẹ̀ Ọkọ̀ ojú-irin igbàlódé ti àwọn ijọba ológun dá dúro

Ki kọ́ Ile-iwòsàn àpapọ̀ si gbogbo agbègbè

Ki kọ́ ẹgbẹgbẹ̀rún ibùgbé àrọ́wọ́tó àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ

Gbogbo ẹgbẹ́ Olùkọ̀wé à̀ti Olùdarí gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ lóri ayélujára bá ẹbi, ará àti gbogbo èrò Èkó dúpẹ́ lọ́wọ́ Èdùmàrè ti o dá ẹmi Alhaji Lateef Kayode Jakande si.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe Àjọyọ̀ Ìdásílẹ̀ Àádọ́ta Ọdún: Creation of State – Lagos Celebrates Fifty (50) Years’ Anniversary

Afárá tuntun lati Lẹkki si Ìkòyí – New Lekki-Ikoyi Bridge

Ìjọba-àpapọ̀ sọ Èkó di ìpínlẹ̀ ni àádọ́ta ọdún sẹhin.  Èkó jẹ́ olú ilú fún gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria tẹ́lẹ̀ ki wọn tó gbe lọ si Abuja.  Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ ikan ninú ipinle mẹ́fà Yorùbá.

Yorùbá ni “Èkó gba olè, ó gba ọlẹ”, ọ̀rọ̀ yi jẹ wi pé kò si irú ẹni ti ko si ni ìpínlẹ̀ Èkó nitori Èkó gba olówó, ó si gba aláini àti wi pé iṣẹ́ pọ̀ ni Èkó ju gbogbo ìpínlẹ̀ yoku lo.  Kò si ẹ̀yà tàbi ẹ̀sìn Nigeria ti kò si ni Èkó.  Nitori èyi èrò pọ̀ jù ilẹ̀ lọ nitori omi ló yi Èkó ká.

Èkó ṣe àjọ̀dún lóri agbami – Lagos celebrate on the Ocean

Àwọn Gómìnà ti ó ti jẹ lati ìgbà ti wọn ti dá ìpínlẹ̀ Èkó silẹ̀ ni wọnyi:

Gómìnà Kini – Ọ̀gágun Àgbà Mobọ́lájí Johnson – Gómìnà fún ọdún mẹjọ – àádọ́ta ọdún si ọdún méjìlélógójì sẹhin
Gómìnà Keji – Gómìnà Ori Omi Adékúnlé Lawal – Gómìnà fún ọdún méjilá – ọdún mejilélógójì titi di ogóji ọdún sẹhin
Gómìnà Kẹta – Ọ̀gágun Ori Omi Ndubuisi Kanu – Gómìnà fún ọdún kan – ogójì ọdún titi di ọdún mọ́kàndinlógójì sẹhin
Gómìnà kẹrin – Ọ̀gágun Ori Omi Ebitu Ukiwe – Gómìnà fún ọdún kan – ọdún mọ́kàndinlógóji titi di ọdún méjidinlógóji sẹhin
Gómìnà Karun – Alhaji Lateef Jakande – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹrin – lati ọdú́n mejidinlogoji titi di ọdún merinlelogbon sẹhin
Gómìnà Kẹfà – Ọ̀gágun Òfúrufú – Gbọ́láhàn Múdàṣírù – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mẹ́tàlélogbon di ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n
Gómìnà Keje – Ọ̀gá Adarioko Ojúomi Mike Akhigbe – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mọ́kànlélọ́gbọ̀n di ọdún mọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹhin
Gómìnà Kẹjọ – Ọ̀gágun Àgbà Rájí Ràsákì – Gómìnà fún ọdún mẹrin – ọdú́n mọ́kàndinlọgbọn di ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n sẹhin
Gómìnà Kẹsan – Ọ̀gá Michael Ọ̀tẹ́dọlá – Gómìnà fún ọdún kan àti oṣù mẹwa – ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n titi di ọdún mẹ́rinlélógún sẹhin
Gómìnà Kẹwa – Ọ̀gágun Ọlágúnsóyè Oyinlọlá – Gómìnà fún ọdún meta – ọdún mẹ́rinlélógún di ọdún mọ́kànlélógún sẹhin
Gómìnà Kọkànlá – Ọ̀gágun Mohammed Buba Marwa – Gómìnà fún ọdún mẹ́ta – ọdún mọ́kànlélógún di ọdún mejidinlógún sẹhin.
Gómìnà Kejilá – Ọ̀gbẹ́ni Bọla Ahmed Tinubu – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹjọ – ọdún mejidinlógún titi di ọdún mẹwa sẹhin
Gómìnà Kẹtàlá – Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé Rájí Fáṣọlá – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹ́jọ – ọdún mẹwa titi di ọdún meji sẹhin
Gómìnà Kẹrinlá – Ọ̀gbẹ́ni Akínwùnmí Ambọde – Gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́ lati ọdún meji titi di òni

Yàtọ̀ si ìgbà Ìjọba Ológun, Èkó gbádùn ìdúróṣinṣin ni àsìkò Ìjọba Alágbádá tàbi Ìjọba Tiwantiwa lati ọdún kẹtàdínlógún sẹhin.  Eyi jẹ ki ipinle Èkó mókè ju gbogbo ìpínlẹ̀ yókù lọ.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2017-05-26 23:08:56. Republished by Blog Post Promoter

Ẹkáàbọ̀ si ọdún Ẹgbàálémọ̀kándínlógún – Welcome to 2019

Àwn ohun ti a kò rò wọ̀nyí kò ni wlé tọ̀ wáAll these unexpected will not come near.

 

Share Button

Ni ìrántí àwọn ti ó gbé àṣà àti èdè Yorùbá lárugẹ ti ó di olóògbé ni Ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún – In memory of Prof. Akinwunmi Isola and Baba Sala who died in 2018

A bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá si ìlú Ìbàdàn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni oṣù kejìlá, ọjọ kẹrìnlélógún, ọdún Ẹdẹgbaalemọ́kàndínlógójì. Ó kú lẹhin ti ó pé ọdún méjìdínlọ́gọ́rin ni oṣù keji, ọjọ́ kẹtàdínlógún, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe fún èdè àti àṣà Yorùbá kò ṣe é gbàgbé.  Ki Ọlọrun má a fún ẹ̀mí rẹ ni ìsimi.

Ni ìgbà ayé Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, ó fi iṣẹ́-akẹkọ gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ pẹ̀lú onkọwe-eré, eré-ṣíṣe, eré-ìtàgé àti ajàfẹtọ-àṣà.   Bi ó ti ẹ jẹ wí pé, ó kọ́ ẹ̀kọ́ lóri èdè Faransé, ó kọ ọ̀pọ̀lopọ̀ eré àti àwọn ìwé tó gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ bi: Efúnṣetán Aníwúrà, Tinubu-Ìyálóde Ẹ̀gbá, Ṣaworoidẹ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀ lọ.

Mósè Ọláìyá Adéjùmọ̀ (ti àdá-pè rẹ njẹ́ Bàba Sàlá) jẹ́ ọmọ Yorùbá lati Iléṣà ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.  Ni ìgbà ayé rẹ, ó lo ẹ̀bùn orin-kí kọ ti ó bẹ̀rẹ̀ ni ọdún kẹrinladọta sẹ́hìn, àwàdà àti eré-ìtàgé gbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ.  Ni ayé ìgbàlódé, Bàba Sàlá jẹ aṣájú fún gbogbo Aláwàdà ni orílẹ̀-èdè Nigeria.

A bi Mósè Ọláìyá Adéjùmọ̀ (ti gbogbo èrò mọ̀ si “Bàba Sàlá”) ni oṣù karun jo kejidinlogun, ọdún Ẹ̀dẹ́gbaa-lémẹ́rìndínlógójì, ó gbé ayé titi di oṣù kẹwa, ọjọ́ keje ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún.  Ogún rẹ̀ fún àwọn Òṣèré yio dúró titi. Ki Ọlọrun má a fún ẹ̀mí rẹ ni ìsimi.

ENGLISH TRANSLATION

Professor Akinwunmi Isola was born in Ibadan, Oyo State on December 24, 1939.  He died after his  78 birthday on February 17, 2018.  His immense contribution to Yoruba language and culture lives on.  May God continue to grant his soul peace. Continue reading

Share Button

Àjọ̀dún Iṣẹ́-Ọnà Yorùbá ni London: Yoruba Art Festival London

Ni ọjọ Àbámẹ́ta àti ọjọ Àìkú oṣù keje, ọjọ́ kẹtadinlọgbọn àti ọjọ kejidinlọgbọn ọdun ẹgbã̃-le-mẹtala, wọn ṣe àjọ̀dún kẹrin Iṣẹ́-ọnà ilẹ Yorùbá, ni pápá Clissod, ni ìlú London.

Gẹgẹbi òwe Yorùbá “Ẹni ti ó ni ki ará ilé ohun má là, ará ìta ni o ya láṣọ”.  Òwe yi là le fi ba awọn èyaǹ wa wi, nitori bi Òyìnbó bá bẹ̀rẹ̀ si ṣe irú àjọ̀dún yi, awọn enia wa a tò pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ lati gba àyè lati fi iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni irú ibi bẹ̃.  Bi èrò ìwòran ti ó fẹ́ mọ nipa iṣẹ́ ọ̀na Yorùbá ti pọ̀ tó, kòsí oníṣẹ́ ọnà bi: onilù, olórin ìbìlẹ́, oníṣòwò ọjà ìbílẹ̀ àti bẹ̃bẹ̃ lọ lati polówó iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni àjọ̀dún yi.

Awọn ẹ̀ka Yorùbá ti ó wà ni Brazil ló kó onílù àti oníjò “Batala” ti ó dá awọn èrò lára ya.́  Awon olonje Yoruba ri oja ta.   Awọn onilù, oníṣòwò ibile, olórin ibile, oniṣẹ ọna ati eléré ìbílẹ̀ Yorùbá ni ìlú-ọba pàdánù àti jẹ ọrọ̀ àti polongo iṣẹ ọwọ́ wọn.

Ó ṣe pàtàkì lati parapọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ lati gbé àṣà, iṣẹ́ ọnà àti èdè Yorùbá lárugẹ.

ENGLISH LANGUAGE

On Saturday and Sunday July 27 and 28, 2013 Yoruba Art Festival was held in Clissold Park in London.

According to Yoruba adage literally translates to “Anyone that says his kinsman should not be rich would rely on outsider to borrow clothes”.  This adage can be applied to the low patronage by the Yoruba budding artists and cultural groups in the United Kingdom.  It is observed that if this event had been organized by foreigners, our people would have queued to beg for a spot to display their culture.  Many of the audience/crowd were disappointed at not seeing Yoruba Artist and other Cultural display at the event.

However, the branch of Yoruba at Brazil “Batala Dance and Drum Group” gave a good performance to entertain the crowd.  The Yoruba food Vendors made brisk business.  The Yoruba indigenous Drummers, Artists, Entertainment Group, Dancers etc. lost the opportunity to show case and advertise their skills.

It is important to join hand with love to promote Yoruba Culture, Art and Language.

Share Button

Ọpẹmipọ Jaji gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fún dídó fàdíya – Opemipo Jaji bags life imprisonment for rape

Opemipo Jaji jailed for raping girl, 11, in Enfield park

Opemipo Jaji

Ọpẹmipọ Jaji gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fún dídó fàdíya – Opemipo Jaji bags life imprisonment for rape @theyorubablog

Ni ọjọ Ẹti, oṣù kẹfa ọjọ keje, ọdún ẹgbẹrunmejilemẹtala, Adájọ́ ṣe ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére fún Ọpẹmipọ Jaji, ọmọ ọdún méjìdínlógún fún dídó fàdíya.

Laipẹ yi, Michael Adébọ́lájọ ati Michael Adébọ̀wálé wá si Iléẹjọ́ fún ẹ̀sùn apànìyàn.  Ìròyìn burúkú yi ko ti lọ lẹ̀, nígbàtí ìròyìn ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére fún Ọpẹmipọ Jaji tún jade.

Kíló nṣẹlẹ? Yorùbá ni “àgbà kì wá lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ́”.  Àsìkoì tó ki àgbàgbà Yorùbá ni Ìlúọba parapọ̀ lati ṣe iwadi ohun tó fa àwọn ọmọ tíwọ́n bẹ̀rẹ̀ si hùwà burúkú wọnyi lãrin àwon ọ̀dọ́.

ENGLISH TRANSLATION

On Friday, June 7, 2013, Opemipo Jaji, 18 years old, was sentenced to life imprisonment for rape.

Recently, Michael Adebolajo and Michael Adebowale were on trial for murder, this bad news has not gone down when the news of life imprisonment sentence for Opemipo Jaji was announced.

What is happening?  Yoruba proverb said “The elder cannot be in the market while the head of a new born is crooked”.  It is time for Yoruba Elders in the United Kingdom to come together to find out the root cause of these terrible crimes among our Youths.

Share Button