Ààntéré ọmọ Òrìṣà-Omi – “Ọmọ o láyọ̀lé, ẹni ọmọ sin lo bimọ”: Aantere – The River goddess child “Children are not to be rejoiced over, only those whose children bury them really have children”.

Yorùbá ka ọmọ si ọlá àti iyì ti yio tọ́jú ìyá àti bàbá lọ́jọ́ alẹ́.  Eyi han ni orúkọ ti Yorùbá nsọ ọmọ bi: Ọmọlọlá, Ọmọniyi, Ọmọlẹ̀yẹ, Ọmọ́yẹmi, Ọlọ́mọ́là, Ọlọ́mọlólayé, Ọmọdunni, Ọmọwunmi, Ọmọgbemi, Ọmọ́dára àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  A o tun ṣe akiyesi ni àṣà Yorùbá pe bi obinrin ba wọ ilé ọkọ, wọn ki pe ni orúkọ ti ìyá ati bàbá sọ, wọn a fun ni orúkọ ni ilé ọkọ.  Nigbati ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé wọn a pe ni “Ìyàwó” ṣùgbọ́n bi ó bá ti bímọ a di “Ìyá orúkọ àkọ́bí”, bi ó bá bi ibeji tabi ibẹta a di “Ìyá Ibeji tàbi Ìyá Ibẹta”.  Bàbá ọmọ a di “Bàbá orúkọ ọmọ àkọ̀bí, Bàbá Ibeji tàbi Bàbá Ìbẹta”.  Nitori idi eyi, ìgbéyàwó ti kò bá si ọmọ ma nfa irònú púpọ̀.

Ni abúlé kan ni aye atijọ, ọkọ ati ìyàwó yi kò bímọ fún ọpọlọpọ ọdún lẹhin ìgbéyàwó.  Nitori àti bímọ, wọn lọ si ilé Aláwo, wọn lọ si ilé oníṣègùn lati ṣe aajo, ṣùgbọ́n wọn o ri ọmọ bi.  Aladugbo wọn gbà wọn niyanju ki wọn lọ si ọ̀dọ̀ Olóri-awo ni ìlú keji.  Ọkọ àti ìyàwó tọ Olóri-awo yi lọ lati wa idi ohun ti wọn lè ṣe lati bímọ.  Olóri-awo ṣe iwadi lọ́dọ̀ Ifa pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lẹ̀ rẹ, o ṣe àlàyé pe ko si ọmọ mọ lọdọ Òrìṣà ṣùgbọ́n nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ, o ni ọmọ kan lo ku lọdọ Òrìṣà-Omi, ṣùgbọ́n ti ohun bá gba ọmọ yi fún wọn kò ni bá wọn kalẹ́, nitori ti o ba lọ si odò ki ó tó bi ọmọ ni ilé ọkọ yio kú, Òrìṣà-Omi á gba ọmọ rẹ padà.  Ọkọ àti Ìyàwó ni awọn a gbã bẹ.

Ààntére lọ fọ abọ́ lódò - Aantere went to the River to do dishes.  Courtesy: @theyorubablog

Ààntére lọ fọ abọ́ lódò – Aantere went to the River to do dishes. Courtesy: @theyorubablog

Ìyàwó lóyún, ó bi obinrin, wọn sọ ni “Ààntéré” eyi ti ó tumọ si “Ọmọ Omi”.  Gbogbo ẹbi àti ará bá wọn yọ̀ ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ.  Ni ọjọ kan, Ààntéré bẹ awọn òbí rẹ pé ohun fẹ́ sáré lọ fọ abọ́, awọn òbí rẹ kọ.  Nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ wọn gbà nitori o ti dàgbà tó lati wọ ilé-ọkọ, wọn ti gbàgbé ewọ ti Olóri-awo sọ fún wọn pe, o ni lati wọ ile ọkọ ki o to bímọ.  Ààntéré dé odò, Òrìṣà-omi, ri ọmọ rẹ, o fi iji nla fa Ààntéré wọ inú omi lai padà.

Ìyá àti Bàbá Ààntéré, reti ki ó padà lati odò ṣùgbọ́n kò dé, wọn ké dé ilé Ọba, Ọba pàṣẹ ki ọmọdé àti àgbà ìlú wa Ààntéré lọ.  Nigba ti wọn dé idi odò, wọn bẹrẹ si gbọ orin ti Ààntéré nkọ, ṣùgbọ́n wọn ò ri.

Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-11 20:24:26. Republished by Blog Post Promoter

“Ọbẹ̀ tó dùn, Owó ló pá: Àwòrán àti pi pè Èlò Ọbẹ̀” – “Tasty Soup, Cost Money – Pictures and pronunciation of Ingredients”

Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá”, ṣùgbọ́n kò ri bẹ̃ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se.  Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nitori, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù.

Ni tõtọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn.  Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi.

View more presentations or Upload your own.

 

View more presentations or Upload your own.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-08 16:30:36. Republished by Blog Post Promoter

ÌJÀPÁ JẸ ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ: The Tortoise is Punished for not Heeding to a Warning

ÌJÀPÁ/Àjàpá JẸ ÈRÈ AIGBỌRAN ÀTI ÌWÀ Ọ̀KANJÚÀ: THE RESULT OF DISOBEDIENCE AND GREED

The African tortoise

The tragic Tortoise — having eaten food made for his wife by the Herbalist — there really should have been a warning as to consequence. Image is courtesy of @theyorubablog

Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Ìjàpá/Àjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí.  Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn.  Yáníbo ko dúró lásán, ó tọ Babaláwo lọ láti ṣe ãjo bí òhun ti le ri ọmọ bí.

Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo.  Babaláwo kìlọ̀ fún Ìjàpá gidigidi wípé õgùn yí, obìnrin nìkan ló wà fún, pé kí o maṣe tọwò.  Ìjàpá ọkọ Yáníbo ṣe àìgbọràn, ó gbọ õrùn àsèjẹ, ó tanwò, ó ri wípé ó dùn, nítorí ìwà wobiliki ọkánjúwà, o ba jẹ àsèj̀ẹ tí Babaláwo ṣe ìkìlọ̀ kí ó majẹ. Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú.  Yorùbá ni “ohun ti a ni ki Baba mágbọ, Baba ni yio parí rẹ”.  Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ:

Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀,  Alugbirinrin 2ce
Õgùn to ṣe fún mi lẹ́rẹkan, Alugbinrin
Tóní nma ma fọwọ́ kẹnu, Alugbinrin
Tóní nma ma fẹsẹ kẹnu,  Alugbinrin
Mo fọwọ kan ọbẹ̀, mo mú kẹnu, Alugbinrin
Mofẹsẹ kan lẹ mo mu kẹnu, Alugbinrin
Mobojú wo kùn o ri gbẹndu, Alugbinrin
Babaláwo mo wa bẹ̀bẹ̀, Alugbinrin 2ce

Play the Tortoise’ tragic song here:

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: Babalawo mo wa bebe(mp3)

Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀.  Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú.

Ìtàn yí kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú.  Ìtàn Yorùbá yi wúlò lati ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ti o nwa owó òjijì nípa gbígbé õgùn olóró mì lati kọjá lọ si òkè okun/Ìlúòyìnbó lai bìkítà pé, bí egbògi olóró yí ba bẹ́ si inú lai tètè jẹ́wọ́, ikú ló ma nfa.  Ìtàn nã bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-21 10:45:28. Republished by Blog Post Promoter

ÀWÒRÁN ÀTI PÍPÈ ORÚKỌ ẸRANKO, APA KEJI – Names of Wild/Domestic Animals in Yoruba

Share Button

Originally posted 2018-03-22 01:59:26. Republished by Blog Post Promoter

ÀṢÀ ÌDÁBẸ́: A Culture of Female Genital Mutilation #IWD

Ìdábẹ́ jẹ ìkan nínú àṣà Yorùbá tí ólòdì si ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin.  Gẹ́gẹ́bí ìtàn ìdábẹ́, Yorùbá ndabẹ fún ob̀nrin ní àti ìkókó títí dé ọmọ ọdún kan,  nwọn ní ìgbàgbọ́ wipe yio da ìṣekúṣe dúró lára obìnrin.

Tiítí òde òní, àṣà Yorùbá ṣì nfi ìyàtọ̀ sí àárín obìnrin ati ọkùnrin, ní títọ́ àti ní àwùjọ.  Gẹ́gẹ́bí Olókìkí Oló́rin Jùjú Ebenezer Obey ti kọ́ lórin: “Àwa ọkùnrin le láya mẹ́fà, kò burú, ọkùnrin kan ṣoṣo lọba Olúwa mi yàn fún obìnrin”.

Gẹ́gẹ́bí Ìwé Ìròyìn Ìrọ̀lẹ́ ti ìlú London, ọjọ́ kẹfà oṣù kẹta, ọdún ẹgbẹ̀rún méji léní mẹ́tàlá, wọn ṣe àkíyèsí wípé àṣà ìdábẹ́ wọ́pọ̀ lãrin àwọn ẹ̀yà tó kéréjù ní Ìlú-Òyìnbó.  Wọ́n ṣe àlàyé àlébù tí àṣà burúkú yi jẹ́ fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá dábẹ́ fún, ara àlébù bi: ọmọ lè kú ikú ẹ̀jẹ̀ dídà, ìṣòro tí irú ẹni bẹ bá fẹ tọ̀, ìsòro ní ìgbà ìbímọ àti bẹbẹ lọ. Ìjọba ti pèsè owó pùpọ̀ lati fi òpin sí àṣà ìdábẹ́ ní Ìlú-Ọba.

Bí a ti nṣe àjọ̀dún “Ọjọ́ áwọn Obìnrin lagbaaye,” oṣe pàtàkì kí Yorùbá ní ilé àti ní àjò, di àṣà tí ó bùkún àwọn ọmọ mú, kí a sì ju àṣà tí ó mú ìpalára dání dànù.  Ìdábẹ́ kò lè dá ìṣekúṣe dúró, nítorí kò sí ìwáìdí pé bóyá ó dá tàbí dín ìṣekúṣe dúró lãrin obìnrin.  Ẹ̀kọ́ áti àbójútó lati ọ̀dọ́ òbí/alabojuto ló lè dá ìṣekúṣe dúró, ki ṣe ìdábẹ́.

English translation below:

THE CULTURE OF FEMALE GENITAL MUTILATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-03-08 17:47:03. Republished by Blog Post Promoter

“Orúkọ ẹni ló njẹri ẹni lókèèrè: Yorùbá tó wà ni òkè-òkun fẹ́ràn orúkọ kúkúrú” – “One’s name is one’s most advocate abroad: Yoruba people abroad, love shorter names”

Yorùbá ki dá gbé, nitori eyi, ẹbi àti ará á pa pọ̀ lati sọ ọmọ lórúkọ.  Ni ọjọ́ ìsọmọ-lórúkọ, ki ṣe iyá àti bàbá ọmọ nikan ni ó nmú orúkọ silẹ̀, iyá àti bàbá àgbà àti ẹ̀gbọ́n naa yi o fún ọmọ tuntun lórúkọ.  Nitori eyi ọmọ Yorùbá ki ni orúkọ kan wọn ma nni orúkọ púpọ̀ lori iwé-orúkọ.  Ni ayé òde oni pàtàki ni òkè-òkun, ọpọ fẹ́ràn à ti fi orúkọ kúkúrú dipò orúkọ gigun ayé àtijọ́. Nitori à ti pè ni wẹ́rẹ́, ṣùgbọ́n wọn lè fi orúkọ gigùn si aarin àwọn orúkọ yoku.   Ẹ ṣe àyẹ̀wò diẹ̀ ninú orúkọ kúkúrú Yorùbá ti ó ṣe fún ọmọ ni ojú iwé yi.

ENGLISH TRANSLATION

Yoruba people live communal life, hence, family and friends come together during child naming.  During the naming ceremony, not only the baby’s parent give name to the baby, grandparents, uncles and aunties do give name to the new-born.  Most often, this is why there are more than one name on the birth certificate of a Yoruba baby.  Nowadays, abroad, many prefer to give shorter names in place of the long olden days names.  This is to enable ease of pronunciation but other long names could still ne included as middle names.  Check below some of the short Yoruba names.

Orúḱ kúkúrú  Yorùba English meaning of short Yoruba names
Àánú God’s mercy is much/Mercy
Àbẹ̀ní Plead to own
Ádára It will be well
Adé Crown
Adéìfẹ́ Crown of love
Àyànfẹ́ Chosen love
Bídèmí A child born in the absence of Dad
Dide Rise up
Dúró Wait
Ẹ̀bùn Gift
Ẹniọlá Wealthy/Prominent person
Fara Cleave
Fẹ́mi Love me
Fèyi Use this
Gbenga Lift me
Ìbùkún Blessing
Ìfẹ́ Love
Ìfẹ́adé Love of crown
Ìkẹ́adé Crown’s care
Ìkórè Harvest
Ìmọ́lẹ̀ Light
Ìní Property
Ire Goodness
Ireti Hope
Ìtùnú Comfort
Iyanu Wonder
Iyi Honour
Jade Show up
Kẹ́mi Care for me
Lànà Open the way
Mofẹ́ I want
Nifẹ Show love
Ọlá Wealth
Oore Kindness
Oreọ̀fẹ́ Grace
Ṣadé Create a crown
Ṣẹ́gun Victor
Ṣeun Thanks
Ṣiji Shield
Simi Rest
Ṣọpẹ́ Give thanks
Tàjòbọ̀ Returnee
Tẹjú Concentrate
Temi Mine
Tẹni One’s own
Tẹra Persist
Tẹti Listen
Tirẹni It is yours
Tóbi Great
Tómi Enough for me
Tọ́mi Train me
Tóní Worthy to have
Wẹ̀mi Cleanse me
Wúrà Gold
Yẹmisi Honour me

 

Share Button

Originally posted 2015-01-20 14:00:28. Republished by Blog Post Promoter

“Àbíkú sọ Olóògùn di èké” – “Child mortality mis-portray the genuineness of the Herbalist”

Ìgbàgbọ́ Yorùbá yàtọ̀ si ohun ti àwọn Ẹlẹko-Ijinlẹ fi hàn ni ayé òde òni.  Ni igbà àtijọ́, bi obinrin/iyàwó bá bi ọmọ, ti ó kú ni ikókó tàbi ki ó tó gba àbúrò, ọmọ ti wọn bá bi lẹhin rẹ ni wọn ma fún ni orúkọ “Àbíkú” pàtàki ti ó bá tó bi meji, mẹta ki ọmọ tó dúró.  Yorùbá gbàgbọ́ ninú àpadà-wáyé, ni igbà miran, wọn á fi ibinú fi àmin, bi ki wọn kọ ilà si ara ọmọ ti ó kú tàbi gé lára ẹ̀yà ara ọmọ yi lati mọ bóyá yio padà wá.  Bi ìyá ti ó bi Àbíkú bá bímọ lẹhin ikú ọmọ ti wọn fi àpá si lára, àpá yi ni wọn ma kọ́kọ́ wò lára ọmọ titun.  Bi wọn bá ri àpá yi, wọn o sọ ọmọ naa ni orúkọ Àbíkú.  Orúkọ àbùkù ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Àbíkú – ó lè jẹ́ orúkọ ẹranko, orúkọ ti ó fi ìbẹ̀rù hàn, tàbi orúkọ fún ìmọràn.

Àbíkú jẹ́ ikú ọmọdé àti ìkókó titi dé ọmọ ọdún marun.  Ẹkọ-Ijinlẹ fi hàn pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ọmọdé ti Yorùbá mọ̀ si Àbíkú yi ti ìpasẹ̀ wọnyi wá: àrùn tó ṣe-dádúró, oúnjẹ-àìtó, omi-ẹlẹgbin,  ilé-iwòsàn ti kò pé tàbi ai si ilé-iwòsàn, àrùn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ọmọ ti ó ni iwọn-kékeré nigbà ìkókó. Owe Yoruba ti o ni “Àbíkú sọ Olóògùn di èké” fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn pé, kò si oògùn ti ó lè dá Àbíkú dúró.  Ìmọ̀ Ijinlẹ fi hàn pe ki ṣe gbogbo ọmọ ti ó kú, ni ó yẹ ki ó kú, nitori lati igbà ti àtúnṣe àwọn ohun ti ó nfa ikú ọmọdé yi ti wà, Àbíkú din-kù – nipa ìpèsè omi ti ó mọ́, ilé-ìwòsàn ọmọdé, ilà-lóye àwọn obinrin nipa ìtọ́jú aboyún àti ọmọdé

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-09-19 21:51:28. Republished by Blog Post Promoter

“Obinrin ki ṣe Ẹrú tabi Ẹrù ti wọn njẹ mọ́ Ogún – Àsikò tó lati Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró” – “Women are not Slaves nor Property that can be inherited – “It is Time to Stop Bequeathing Widows to the Next-of-Kin.”

 Yorùba Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró – Yoruba Stop Bequeathing Widows.  Courtesy: @theyorubablog

Yorùba Dáwọ́ Àṣà ṣì Ṣúpó Dúró – Yoruba Stop Bequeathing Widows. Courtesy: @theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, àṣà ṣì ṣúpó wọ́pọ̀ ni Ilẹ̀ Yorùbá. Obinrin ti ọkọ rẹ̀ bá kú wọn yio fi jogún gẹ́gẹ́ bi iyàwó fún ọmọ ọkọ ọkùnrin tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin. Eleyi wọ́pọ̀, pàtàki ni idilé Ọba, Ìjòyè nla, Ọlọ́rọ̀ ni àwùjọ àti àgbàlagbà ti ó fẹ́ iyàwó púpọ̀.  Bi Ọba bá wàjà, Ọba titun yio ṣu gbogbo iyàwó ti ó bá láàfin lópó.

Ni ayé ọ̀làjú ti òde òni, àṣà ṣì ṣúpó ti din kù púpọ̀, nitori ẹ̀sìn àti àwọn obinrin ti ó kàwé ti ó si ni iṣẹ́ lọ́wọ́ kò ni gbà ki wọn ṣú ohun lópó fún ẹbi ọkọ ti kò ni ìfẹ́ si.  Ọkùnrin ni ẹbi ọkọ na a ti bẹ̀rẹ̀ si kọ àṣà ṣì ṣúpó silẹ̀ pàtàki àwọn ti ó bá kàwé, nitori ó ti lè ni iyàwó tàbi ki ó ni àfẹ́sọ́nà.  Lai ti ẹ ni iyàwó, ọkùnrin ẹbi ọkọ lè ma ni ìfẹ́ si iyàwó ti ọkọ rẹ̀ kú.  Àṣa ṣì ṣúpó kò wọ́pọ̀ mọ laarin àwọn ti ó jade, àwọn ti ó ngbé ilú nla àti Òkè-òkun tàbi àwọn ti ó kàwé, ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ laarin àwọn ti kò jade kúrò ni Abúlé àti àwọn ti kò kàwé.

Idilé ti ifẹ bá wà laarin ẹbi, iyàwó pàápàá kò ni fẹ́ kúrò ni irú ẹbi bẹ́ ẹ̀ lati lọ fẹ́ ọkọ si idilé miran pàtàki nitori àwọn ọmọ tàbi ó dàgbà jù lati tun lọ fẹ ọkọ miran.  Ọmọ ọkọ tàbi ẹbi ọkọ ọkùnrin lè fi àṣà yi kẹ́wọ́ lati fẹ opó ni tipátipá, omiran lè pa ọkọ lati lè jogún iyàwó. Bi iyàwó bá kú, wọn kò jẹ́ fi ọkọ rẹ jogún fún ẹbi iyàwó.

Àsikò tó lati dáwọ́ àṣà ṣì ṣúpó dúró nitori obinrin ki ṣe ẹrú tàbi ẹrù ti wọn njẹ mọ́ ogún.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-18 19:53:23. Republished by Blog Post Promoter

Pi pè àti Orin fún orúkọ ọjọ́ ni èdè Yorùbá – Yoruba Days of the week pronunciation and song

OrúkỌjọ́ni èdè Yorùbá                 Days of the Week In English

Àìkú/Ọjọ́ Ọ̀sẹ̀/Ìsimi                            – Sunday

Ajé                                                      – Monday

Ìṣẹ́gun                                                – Tuesday

Ọjọ́rú                                                 – Wednesday

Ọjọ́bọ̀                                                – Thursday

Ẹti                                                      – Friday

Àbámẹ́ta                                            – Saturday

Share Button

Originally posted 2014-07-29 20:31:30. Republished by Blog Post Promoter

Ọdún Ẹgbã-lemẹ̃dogun wọlé, ọdún á yabo o – Year 2015 is here, may the year be peaceful

Ọdún tuntun Ẹgbã-lemẹ̃dogun wọlé dé.  Ilú Èkó fi tijó tayọ̀ gba ọdún tuntun wọlé, gbogbo àgbáyé naa fi tijó tayọ̀ gba ọdún wọlé.  A gbàdúrà pé ki ọdún yi tura fún gbogbo wa o (Àṣẹ).Governor Babatunde Fashola of Lagos State, members of the state executive council and the sponsors of the Lagos Countdown 2014 at the Lagos Countdown Festival of Light held on Monday at the Bar Beach, Lagos.

ENGLISH TRANSLATION

The New Year 2015 is here with us.  Lagos ushered in the New Year with dancing and joy, as the rest of the world received the New Year.  We pray that the New Year will be peaceful for all (Amen).

Share Button

Originally posted 2015-01-03 00:16:00. Republished by Blog Post Promoter