“Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nigeria ni pe“Àyípadà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi”: The current slogan in Nigeria is “Change begins with me”

Ohun ti wọ́n bá fi ogún ọdún tàbi ju bẹ́ ẹ̀ lọ kọ́, ṣe é bàjẹ́ ni iṣéjú akàn, ṣùgbọ́n lati ṣe àtúnṣe lè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún bakan na a.  Ó ṣe pataki ki gbogbo ọmọ ilú pinu ni ikan kan lati ṣe àtúnṣe lati bọ́ lọ́wọ́ ìnira ti ó wà ni ilú lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi - Change Begins with Me. Courtesy: @theyorubablog

Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi – Change Begins with Me. Courtesy: @theyorubablog

Àyípadà tàbi Àtúnṣe yẹ ki ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òṣiṣẹ́ Ìjọba, àwọn ti ó nta ọjà, ọ̀gá ilé-iwé àti àwọn ọmọ ilé-iwé, àwọn òṣiṣẹ́ ilé-ìwòsàn, ọmọdé àti àgbà ilú.  Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà àti àwọn iwà ibàjẹ́ ti ó ti gbilẹ̀ fún ọdún pi pẹ́ ti ba nkan jẹ ni orilẹ̀ èdè Nigeria.  Di ẹ ninú àwọn iwà burúkú wọnyi ni ki òṣiṣẹ́ ìjọba ji ẹrù àti owó Ìjọba fún ara wọn tàbi sọ ara wọn di alágbàtà ti o nsọ ọjà di ọ̀wọ́n nipa gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ.  Eleyi lo njẹ ki àwọn iṣẹ́ ti ìjọba bá gbé sita lati tú ọ̀nà ṣe, lati pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi àti ohun amáyédẹrùn miran wọn ju ti gbogbo àgbáyé lọ.  Nitori òṣiṣẹ́ Ìjọba ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ti ó gba iṣẹ́ lè ma ṣe iṣẹ́ tàbi ki wọn ṣe iṣẹ́ ti kò dára.   Ẹni ti ó nta ọjà á sọ̀rọ̀ si onibárà pẹ̀lú ẹ̀gàn, ojúkòkòrò, ìfẹ́ owó ki kó jọ ni ọ̀nà ẹ̀rú àti à ṣe hàn ló nfa iwà ibàjẹ́ àti olè jijà laarin àwọn Òṣèlú, olóri ẹ̀sìn, òṣiṣẹ́ Ìjọba, ọlọ́jà ti ó nkó ọjà pamọ́ lati fa ọ̀wọ́n, Olùkọ́ ilé iwé, ọmọ ilé-iwé kò ni itẹriba fún Olùko mọ́, àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀  lọ.

Ki àyipadà rere lè dé bá ilú, ó yẹ ki onikálukú yẹ ara rẹ̀ wò fún àtúnṣe kúrò ninú àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà, iwà ibàjẹ́, ai ṣojú ṣe ẹni ninú ẹbi, ai bẹ̀rù àgbà, ji ja ilú lólè, ki kó owó ilú lọ si òkèèrè, ki kọ oúnjẹ ilú ẹni silẹ̀ fún oúnjẹ òkèèrè, ayẹyẹ àṣejù, ni ná owó ti èniyàn kò gbà àti ai ni ìtẹ́lọ́rùn.

Ìpolongo tó nlọ lọ́wọ́ ni orilẹ́ èdè Nigeria ni pé “Àyípadà tàbi Àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mi”.   Yorúbà sọ wi pé “Igi kan ki da a ṣe igbó”, eyi túmọ̀ si wi pé ki i ṣe Olóri Ìjọba Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú yoku nikan ni ó yẹ ki ó ṣe àtúnṣe ohun ti ó ti bàjẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n gbogbo ọwọ́ ló yẹ ki ó ṣe àtúnṣe lati gbógun ti iwà ibàjẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

‘Gómìnà Ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ pèsè omi mi mun fún ará ilú ki wọ́n yé gbẹ́lẹ̀ kiri bi Òkété’ – ‘Yoruba Governors, provide your people safe water to prevent the digging of holes like Bush Rats’

Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ni abẹ́ Olóògbé Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi, da gbogbo ipinlẹ̀ pọ si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀.  Ki wọ́n tó dá àwọn ipinlẹ̀ pọ̀, àwọn ipinlẹ̀ ndàgbà sókè gẹ́gẹ́ bi ohun ti ó ṣe kókó fún wọn.  Ipinlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, ti ẹ̀yà Yorùbá ngbé, ni ìgbéga ni abẹ́ Olóri Òṣèlú Ipinlẹ̀, Olóògbé́ Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti ẹgbẹ́ Òṣèlú rẹ.  Wọ́n pèsè ohun amáyédẹrùn igbàlódé bi ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, ọ̀nà gidi, omi mi mun, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ ẹ̀  bẹ́ ẹ̀ lọ ni gbogbo agbègbè ilẹ́ Yorùbá.  Eleyi jẹ ki Yorùbá ri ohun mu yangàn.

Yàtọ̀ si Ìjọba Ológun lábẹ́ Ọ̀gágun Yakubu Gowon, ti ó lo ọ̀pọ̀ owó epo rọ̀bì dáradára lati pèsè ohun amáyédẹrùn ti igbàlódé ti ilú ngbádùn titi di ọjọ́ oni,  ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ìjọba Nigeria yókù ti ó ré kọjá lábẹ́ Ológun àti Òṣèlú kùnà nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn fún orilẹ̀ èdè nitori iwà ibàjẹ́.

Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó sọ wi pé “Ni ilú afọ́jú, olójú kan lọba”, laarin Ìjọba àpapọ̀, nitori iwà-ibàjẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, a lè sọ wi pé àwọn ipinlẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn, Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀yọ́ ṣe dáradára nipa ipèsè ohun amáyédẹrùn.  Àmọ́, ‘ilọsiwájú’ yi kò tó nkankan lára ogún ti Olóògbé Olóyè Awólọ́wọ̀ ṣe silẹ̀.  Kò si ipèsè ohun amáyédẹrùn pàtàki omi mi mun ni àwọn agbègbè tuntun lai yọ àdúgbò ọlọ́rọ̀ silẹ̀.  Eleyi ló sọ gbi gbẹ́ ihò fún omi àti kànga lati wá omi fún mi mun di àṣà.

Àwọn ipinlẹ̀ Yorùbá́ ti gbádùn ohun amáyédẹrùn igbàlódé fún ọjọ́ ti pẹ́, nitori èyi ni a ṣe mbẹ̀ àwọn Gómìnà ipinlẹ̀ Yorùbá pé ki wọn pèsè ‘’omi mi mun’ fún ará ilú gẹ́gẹ́ bi ẹ̀tọ́ lati dá àṣà gbi gbẹ́ ilẹ̀ bi ti Òkété lati wa omi ti kò ṣe e mu ni ọ̀pọ̀ igbà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Orúkọ Gbogbo Ẹ̀yà Ara ni Èdè Yorùbá – Names of part of Human Body in Yoruba

Nitotọ àti ṣe ẹ̀yà orí tẹlẹ ṣugbọn a lérò wípé orúkọ gbogbo ẹ̀yà ara lati orí dé ẹsẹ á wúlò fún kíkà.

Ẹ̀yà Ara ni Èdè Yorùbá and the English Translation of names of part of the body

Though the names of parts of the head had earlier been published but we think the readers will find the names of the whole body from head to toe will be useful for reading

 

View more presentations or Upload your own.

Share

Ìránti Aadọta Ọdún ti Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji fún Àlejò rẹ, Olóri-Ogun àkọ́kọ́ Aguiyi Ironsi: Fifty years’ celebration of Late Lt. Col. Adekunle Fajuyi an epitome of Loyalty

Yorùbá fẹ́ràn àlejò púpọ̀.  Ìwà ti ọmọ ilú lè hù ti yio fa ibinú, bi àlejò bá hu irú ìwà bẹ́ ẹ̀, wọn yio ni àlejò ni, ki wọn fori ji i.  Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Ojú àlejò ni a ti njẹ igbèsè, ẹhin rẹ  la nsaán”.  Eyi fi hàn bi Yorùbá ti  fẹ́ràn  lati ma ṣe àlejò tó.

Ìbàdàn ni olú-ilú ipinlẹ̀ Yorùbá ni Ìwọ̀-Oorun Nigeria tẹ́lẹ̀ ki Ìjọba Ológun ti Aguiyi Ironsi ti jẹ Olóri tó kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria pọ si aarin lẹhin ti wọn fi ibọn gba Ìjọba lọ́wọ́ Òṣèlú ni aadọta ọdún sẹhin. Lẹhin oṣù keje ni aadọta ọdún sẹhin, àwọn Ológun fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji.  Ti àkọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nigbati wọn fi ibọn lé àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ lẹhin òmìnira kúrò ni ọjọ́ karùndinlógún, oṣù kini ọdún Ẹdẹgbaalemẹrindinlaadọrin.  Lẹhin oṣù meje, àwọn Ológun tún fi ibọn gbà Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Ológun ti wọn fi ibọn gbé wọlé ti Aguiyi Ironsi jẹ olóri rẹ.  Lára Ìjọba Ológun àkọ́kọ ti Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi ti jẹ́ Olóri Ìjọba ni wọn ti fi Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi  jẹ Olóri ni ipinlẹ̀ Yorùbá dipò Òṣèlú Ládòkè Akintọ́lá ti àwọn Ológun pa.

Military incursion in Nigeria - 1966

Military incursion in Nigeria – 1966

Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi gba Olóri-ogun Aguiyi Ironsi ni àlejò ni ibùgbé Ìjọba ni Ìbàdàn nigbati àwọn Ológun dé lati fi ibọn gba Ìjọba ni igbà keji.   Nigbati àwọn Ajagun dé lati gbé Olóri Ogun Aguiyi Ironsi lọ, gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá, Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi bẹ̀bẹ̀ ki wọn fi àlejò òhun silẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kọ.  Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fi ara rẹ ji pé ti wọn ba ma a gbee,  ki wọn gbé òhun pẹ̀lú.  Nitori eyi àwọn Ológun gbe pẹ̀lú àlejò rẹ wọn si pa wọ́n pọ ni Ìbàdàn.

Ni ọjọ́ kọkandinlọgbọn oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rindinlógún, ilú péjọ pẹ̀lú ẹbi àti ará ni Adó-Èkìtì lati ṣe iranti Olóògbé Ọ̀gágun Adékúnlé Fájuyi fún iranti iwà iṣòótọ ti ó hù titi dé ojú ikú pẹ̀lú àlejò àti ọ̀gá rẹ Olóri Ogun Aguiyi Ironsi ni aadọta ọdún sẹhin.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

“Ìgbésí Ayé Aláwọ̀-dúdú Ṣe pàtàki” pé Àwọ Lè Yàtọ̀, Ṣùgbọ́n Ẹ̀jẹ̀ Kò Yàtọ̀ – “BLACK LIVES MATTER”, Though Colour may be different Human Blood is not”

B;ack Lives Matter protesters

B;ack Lives Matter protesters

Ikú àwọn ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ọwọ́ Ọlọpa ni orilẹ̀ èdè Àméríkà pọ̀ ju pi pa àwọn aláwọ̀ funfun tàbi laarin àwọn ẹ̀yà kékeré miran.  Ọ̀sẹ̀ kini oṣù keje ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún ṣòro fún àwọn Àméríkà.

Ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti yin ibọn si ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú ni ojú ọmọ àti aya nlọ lọ́wọ́ nigbati ìròyìn bi Ọlọpa funfun ti pa okunrin Aláwọ̀-dúdú miran bi ẹni pa ẹran ti tún jáde.  Àwọn iroyin yi bi àwọn èrò ninú,  nitori èyi, aláwọ̀ dúdú àti funfun tú jáde lati fi ẹ̀dùn hàn pé “Ìgbésí Ayé Aláwọ̀-dúdú ṣe pàtàki” pé àwọ lè yàtọ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ kò yàtọ̀.  Ó ṣe ni laanu pé Micah Johnson ọkùnrin Aláwọ̀-dúdú, jagunjagun fun orile ede Àméríkà, ló pa Ọlọpa marun, ó si ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ léṣe nipa gbi gbé òfin si ọwọ́ ara rẹ pẹ̀lú ibinu.

Micah Johnson a 25 year old U.S. Army Veteran, the Cops shooter

Micah Johnson a 25 year old U.S. Army Veteran, the Cops shooter

Ìwà burúkú ti di ẹ̀ ninú àwọn Ọlọpa funfun yi hu ki ṣe ìwà ti ó wọ́pọ̀ laarin ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọlọpa aláwọ̀ funfun tàbi gbogbo Ọlọpa ti wọn nṣe iṣẹ́ ribiribi lati dá àbò bo àwọn ará ilú.  Ó ṣe ni laanu pé àwọn Aláwọ̀-dúdú ni Ọlọpa nda dúró jù ni ojú ọ̀nà ọkọ̀, ti ó dẹ̀ n kú ni irú idá dúró bẹ́ ẹ̀.  Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, onidajọ ọ̀daràn kò ṣe idájọ òdodo fún Aláwọ̀-dúdú, èyi kò ran nkan lọ́wọ́.

A lérò wi pé àwọn oníwà ìbàjẹ́ ti ó jẹ́ Olóri Òṣèlú ilẹ̀ Alawo dudu ti ó n ja ilú lólè lati kó irú, ọrọ̀ ilú lọ pamọ́ si àwọn ilú ti o ti dàgbà sókè yio ronú pìwàdà.  Èrò ti ó n kú ni ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú nitori ọ̀nà ti kò dára, a i si ilé-ìwòsàn gidi, a i ni ohun amáyédẹrùn bi omi, iná mọ̀nàmọ́ná kò jẹ ki Aláwọ̀-dúdú Àméríkà lè fi orisun wọn yangàn.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Bẹni, Bẹ́ẹ̀kọ́ Ìbò Ọ̀rọ̀ Ìlú ni Ìlú-Ọba: Ẹ̀kọ́ fún Orilẹ̀-èdè Nigeria – ‘Yes or No’ The United Kingdom Referendum: Lessons for the Nigerian Nation

Ì̀bò Ọ̀rọ̀ Ìlu ni Ìlú-Ọba' UK Referendum

Ì̀bò Ọ̀rọ̀ Ìlu ni Ìlú-Ọba’ UK Referendum

Ni Ìlú-Ọba, lẹhin ọdún mẹtalelogoji, èrò jade lati di ìbò bẹni-bẹ́ẹ̀kọ́ lori àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ Ìlú-Oyinbo méjidinlọ́gbọ̀n ni Ọjọ́bọ̀, oṣu Kẹfa, ọdún Egbàálémẹẹdógún.   Idibò na a lọ wẹ́rẹ́ lai si ìjà, kò gbà ju ìṣéjú kan si meji lọ lati wọlé dibò ti ó  bẹ̀rẹ̀ ni agogo meje àárọ̀ titi di aago mẹwa alẹ́.  Lẹhin idibò, ni òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ keji idibò, ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ kẹrinlélógún, oṣù kẹfa, èsi ibò jade pé ibò bẹ́ẹ̀kọ́ ju ibò bẹni lọ, eyi ti ó túmọ̀ si wi pé, ará ilú ti ó fẹ́ ki wọn ‘kúrò’ ni ẹgbẹ́ Ilú-Oyinbo pọ̀ ju àwọn ti wọn ó fẹ́ ki wọn ‘dúró‘ ninú ẹgbẹ́.

Bi èsì ibò ti jade, Olóri Òṣèlú Ilú-Ọba, David Cameron, jade lati bá ará ilú sọ̀rọ̀.  Ninú ọ̀rọ̀ rẹ, ó ni nitori ohun polongo ki wọn dúró ninú ẹgbẹ́ Ilú-Oyinbo ṣùgbọ́n àwọn aráilú ti sọ̀rọ̀ wi pé ki wọn kúrò, nitori eyi ohun yio gbé Ijọba silẹ̀.

Ẹ̀kọ́ fún Ìjọba tiwa ntiwa ni orilẹ̀ èdè Nigeria ni wi pé iwá ibàjẹ́ ti àwọn Òṣèlú nhu ni Àbùjá lai fi eti si ará ilú pé àwọn ẹ̀yà mẹ́yà orilẹ̀ èdè Nigeria fẹ́ dá Ìjọba wọn ṣe ju ki Òṣèlú joko si Àbùjá lati maa na owó gbogbo ará ilú.  Ó yẹ ki wọn ronú bi wọn yio ti ṣe Ìjọba ti yio mu irọ̀rùn ba gbogbo ipinlẹ Nigeria.  Ki wọn fi eti si ohun ti ará ilú lati Guusu dé Àriwá sọ, pé ki wọn joko sọ̀rọ̀ bi wọn yio ti ma bára gbé.  Igbe àwọn Igbo ti pọ si lẹhin ti wọn jagun abẹ́lé, àwọn ẹya miran bi Yorùbá nkun ni abẹ́lẹ̀ pé àwọn ma fẹ dá dúró ki wọn san iṣákọ́lẹ̀ fún Ìjọba àpapọ̀.

Ó yẹ ki Òṣèlú Nigeria ṣe àyẹ̀wò òfin ti aṣojú Ilú Ọba – Lugard fi da Guusu àti Àríwá pọ fún irọ̀rùn ìṣàkóso orilẹ̀ èdè Nigeria ni ọgọrunlemeji ọdún sẹhin.  Nigeria gba Òmìnira ni bi ọdún mẹrindinlọgọta sẹhin.  Lẹhin Òmìnira, àwọn Òṣèlú pàtàki ni Ìwọ̀-oòrùn lábẹ́ Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ fi ipò Òṣèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi lati jẹ́ ki àwọn ará ilú jẹ èrè Òmìnira, ṣùgbọ́n lati igbà ti Ìjọba Ológun ti ó fi ibọn gba Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ si ṣe Òṣèlú ni ilú ti bàjẹ́ si, wọn si rò wi pé àwọn lé fi ipá kó orilẹ̀ èdè pọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Àjọ jẹ kò dùn bi Ẹni kan kò ri: Ìná dànù àwọn ọmọ Olówó Nigeria ni Ìlú-Ọba – Eating together is not fun when some are deprived: Squandering of Nigeria Wealth in the UK, TV Channel 4 Documentary

Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ti wà.  Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kún fún ọrọ̀ oriṣiriṣi, ṣùgbọ́n, iwà àpà, ojúkòkòrò, ki kó ti ilé dà si ita, àti ìfẹ́ àjòjì ju ara ilé ẹni lọ, ló fa iṣẹ́ ti ó pọ̀ ni Ilẹ̀-Aláwọ̀dúdú.  Iwà burúkú wọnyi, pàtàki laarin àwọn Olóri ilú tàbi alágbára ló fa ti ta ara ẹni lẹ́rú si Òkè-Òkun, ogun abẹ́lé àti òwò ẹrú ti ayé òde òni ṣi wà.  Àwọn Òṣèlú àti Olóri ilú kò ti kọ́ ọgbọ́n, nitori wọn nṣe àṣiṣe si nipa li lo iṣẹ ti wọn gbà lai ṣe kó owó ilú jẹ, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbigbà àti iwà ibàjẹ́ ló fa ibàjẹ́ ohun amáyédẹrùn àti ìṣẹ́ laarin ọrọ̀ ni orilẹ̀ èdè Nigeria.

Melo ninú ọmọ ayé òde òni ló ránti àwọn Ọlọ́rọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ni aadọta ọdún sẹhin?  Òmíràn kò mọ itumọ̀ ọ̀rọ̀ Èkó/Yorùbá pé “Bi ó ti ẹ lówó bi Da Rocha” lai bèrè pé tani Da Rocha?  Àwọn Ọlọ́rọ̀ àná bi Candido Joao Da Rocha, Ọlọ́rọ̀ owó ọ̀kẹ́ aimoye àkọ́kọ́ ni orilẹ̀ èdè Nigeria ti ilú Èkó, Olóyè Adéọlá Odùtọ́lá ọ̀gá Oníṣòwò ti Ìjẹ̀bú-Òde ti ìpínlẹ̀ Ògùn, Oloye Àjàó, S. Bọlaji Bakare, I.O. Àjànàkú Iléṣà, Olóyè T.A. Oni & ati àwọn ọmọ-kunrin rẹ ni Ìbàdàn ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Oṣinọwọ oníṣòwò ọkọ̀ irinna ni Èkó, Mobọ́láji Bank-Anthony, Asábọ́rọ̀, ọmọ Ìkárọ̀ ni ẹ̀gbẹ́ Ọ̀wọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ondo àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ ti wọn ti gbàgbé wọn pẹ̀lú ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀.  Àwọn ti wọn ránti, ki ṣe nitori ọrọ̀ ti wọn fi silẹ̀ láyé ni èrò ránti ṣùgbọ́n àwọn ọmọ tó gba ẹ̀kọ́ ni ó lè jẹ ki wọn ṣe iránti wọn àti bi wọn ti lo ọrọ̀ na a fún lati ṣe oore fún àwọn aláìní.

Àwọn Ọlọ́rọ̀ Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú kò kọ́ ọgbọ́n ninú itàn igbẹhin Ọba àti Ìjòyè ti kò lo ipò wọn dáradára, àwọn ti ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ, tàbi ti ó lo ipò wọn lati fi tẹ ará ilú mọ́lẹ̀ ni àtijọ́.  Irú ọrọ̀ bẹ́ ẹ̀  kò bá wọn kalẹ́ bẹni ìrántí wọn kò dára.

Ni ọjọ́ keji ọ̀sẹ̀, ọjọ́ keje oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbàá-lémẹ́rìndínlógún, ilé-iṣẹ́ Amóhùn-máwòrán Kẹrin ni Ilú-Ọba fi àpẹrẹ hàn bi àwọn ọmọ Ọlọ́rọ̀ lati Nigeria ti mba owó ninú jẹ́ ni Ilú-Ọba.  Yorùbá ni “Ohun ti a kò bá jiyà fún, ki i lè tọ́jọ́”.  Wọn nná owó ti ọgọrun enia lè ná ni ọdún kan ni alẹ́ ọjọ́ kan lai ronú ọ̀pọ̀ aláìní ni orílẹ̀ èdè wọn, ti Bàbá wọn ti fa ijiyà fún lati kó ọrọ̀ ti wọn nná dànù jọ.  Kò si ìyàlẹ́nu ni irú iwà ti àwọn ọmọ ọlọ́rọ̀ Nigeria wọnyi hù nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bàjẹ́, wọn kò ni ẹ̀kọ́, wọn kò mọ iyi owó nitori wọn kò ṣiṣẹ́ fun.

ENGLISH TRANSLATION  Continue reading

Share

Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún, Ọbabinrin Elizabeth Keji – Celebration of 90th Birthday of Queen Elizabeth II

Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ibi Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún – Queen Elizabeth II at her 90th Birthday celebration.

Ọbabinrin Elizabeth Keji ni ibi Ayẹyẹ Ọjọ́-ibi Aadọrun Ọdún – Queen Elizabeth II at her 90th Birthday celebration.

Ọbabinrin Elizabeth Keji, pé aadọrun ọdún láyé ni ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálémẹrindinlólgún.  Gbogbo ará ilú àti àwọn Ìjọ Onigbàgbọ́ pé jọ lati ṣe ayẹyẹ à ṣe pọ̀ fún Ọbabinrin ni ọjọ́ Ìsimi, ọjọ́ kejila, oṣù kẹfà ọdún.  Eleyi bọ si àsikò ti ọkọ rẹ Philips pé ọgọrundinmarun ọdún.

Lẹhin ti Ọbabinrin Elizabeth keji gun ori oyè ni ọdún mẹtalelọgọta sẹhin, ó bẹ ilú Èkó wò ni ọgọta ọdún sẹhin, nigbati Ilú Èkó jẹ́ Olú-Ilú orilẹ̀ èdè Nigeria ki a tó gba Òminira lábẹ́ Ilú-Ọba ni odun Ẹdẹgbaalelọgọta.  A ṣe yi ṣe àmọ́dún o.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán wọnyi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Muhammad Ali – Ọ̀gá pátápátá Afẹ̀ṣẹ́ kù bi Òjò àwọn Akànṣẹ́ Relé: “The Greatest Boxer” – Muhammad Ali has gone home

Worshipers and well-wishers take photographs as the casket with the body of the late boxing champion Muhammad Ali is brought for his jenazah, …

Ìròyìn ikú Muhammad Ali ọmọ ọdún mẹ́rinlélaadọrin kàn ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹta, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún.  Bi ó ti ẹ jẹ wi pé, Ali ti wà lóri àisàn fún bi ọgbọ̀n ọdún, inú ọmọdé àti àgbà ni àgbáyé ṣe ìdárò nigbati wọn gbọ ìròyìn ikú rẹ.

Ki ṣe iṣẹ́ akànṣẹ́ nikan ni Muhammad Ali dúró fún, ó dúró fún ohun ti ó gbàgbọ́ lai bẹ̀rù.  Ni bi ọdún marun-dinlọgọta sẹhin, nigbati Aláwọ-funfun ṣe òfin lati ya Aláwọ̀-dúdú si ọ̀tọ̀, pé wọn kò lè lo ohun amáyédẹrùn (bi ọkọ̀ wi wọ̀ pọ̀, ilé oúnjẹ, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀  lọ)  ti wọn pèsè fún ará ilú pẹ̀lú Aláwọ-funfun, Muhammad Ali kò pa ẹnu mọ lati dẹbi fún irú òfin àti iwà burúkú yi.  Ó kọ̀ lati lọ jagun (Vietnam), ti kò gbàgbọ́ nitori ó gbàgbọ́ pé alafia dára ju ogun lọ.  Muhammad Ali yi orúkọ ẹrú “Cacius Clay’’àti ẹ̀sìn padà lati kọ ẹ̀hin si iwà burúkú ti Aláwọ-funfun hù si enia rẹ.

Muhammad Ali mú adùn wọ iṣẹ́ akànṣẹ́, ó fi ọlà rẹ ṣe àánú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláìní, ó si jẹ àwòkọ̀ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ pàtàki Aláwọ̀-dúdú ti ó fi hà̀n pé ‘kò si ohun ti kò ṣe é ṣe, bi enia bá fi ọkàn si’.  Eleyi jẹ ki èrò fẹ́ràn rẹ púpọ̀.

Muhammad Ali and Joe Frazier – The Thrilla In Manila

Àwọn Olóri Ilú àti Ẹlẹ́sin ni oriṣiriṣi ati gbogbo àgbáyé ṣe ìdárò Muhammad Ali bi wọn ti ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin tó yẹ fún Ọba, ni ibi ìtẹ́ ìsìnkú ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹwa, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, ọmọ-ọmọ, Ìyàwó, ẹbi àti ará ló gbẹ̀hin rẹ.  Sùn re o.

 

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

YORÙBÁ alphabets – A B D

A B D E F G GB H I J K L M N O P R S T U W Y

 

You can also download the Yoruba alphabets by right clicking this link: A B D – audio file Yoruba alphabets recited (mp3)

Continue reading

Share