Tag Archives: Western Region of Nigeria

“À ì sí Iná Mọ̀nà-mọ́ná àti Epo Ọkọ̀ bá Onílé pẹ̀lú Àlejò”: – “Everybody is affected by lack of electricity and petroleum scarcity”

Ki gbogbo Nigeria tó gba ominira ni àwọn Òṣèlú lábẹ́ olùdari Olóyè Ọbáfẹ́mi Awolọwọ ti fi owó kòkó àti iṣẹ́-àgbẹ̀ dá nkan ṣe fún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá.  Yorùbá jẹ èrè àwọn ohun gidi, amáyé-dẹrùn bi ilé-iwé ọ̀fẹ́, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé iṣẹ́ amóhùn-máwòrán àkọ́kọ́, ilé àwọn àgbẹ̀ (olókè mẹrin-lé-lógún – ilé giga àkọ́kọ́), ọ̀nà ọlọ́dà, omi, iná mọ̀nà-mọ́ná àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.  Àwọn ohun ipèsè wọnyi jẹ èrè lati ọ̀dọ̀ Òṣèlú tó fẹ́ràn ilú ti ó gbé wọn dé ipò, eleyi jẹ àwò kọ́ iṣe fún àwọn Òṣèlú ẹ̀yà ilẹ̀ Nigeria yókù.

Ìjọba Ológun fi ibọn àti ipá gbé ara wọn si ipò Òṣèlú, wọn fi ipá kó gbogbo ohun amáyé-dẹrùn si abẹ́ Ìjọba àpapọ̀.  Lati igbà yi ni ilé-iwé kékeré àti giga, ilé-ìwòsàn àti ohun amáyé-dẹrùn ti Òṣèlú pèsè fún agbègbè wọn ti bẹ̀rẹ̀ si bàjẹ́.  A lè fi ibàjẹ́ ohun amáyé-dẹrùn ti àwọn Òṣèlú àkọ́kọ́ pèsè fún ara ilú wọnyi wé ọbẹ̀ tó dànu,̀ ti igbẹhin rẹ já si òfò fún onilé àti àlejò.

Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dànù, òfò onilé, òfò àlejò” Àpẹrẹ pataki ni ọna àti ilé-iwosan ti ó bàjẹ́.  Òfò ni ọ̀nà ti ó bàjẹ́ mú bá ara ilú nipa ijàmbá ọkọ̀ fún onilé àti àlejò.  Ibàjẹ́ ile-iwosan jẹ òfò fún onilé àti àlejò nitori ọ̀pọ̀ àisàn ti kò yẹ kó pani ló ńṣe ikú pani, fún àpẹrẹ, itijú ni pé, Ọba, Ìjòyè àti Òṣèlú ńkú si àjò fún àìsàn ti kò tó nkan.  Dákú-dáji iná mọ̀nà-mọ́ná ti ó sọ ilú si òkùnkùn jẹ́ òfò fún olówó àti aláini nitori, yàtọ̀ si ariwo àti òórùn, ai mọye enia ni ikú ẹ̀rọ mọ̀nà-mọ́ná ti pa. À ì sí Iná Mọ̀nà-mọ́ná àti Epo Ọkọ̀ bá Onílé pẹ̀lú Àlejò.  Ìwà ìbàjẹ́, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló da ọbẹ̀ ohun amáyédẹrùn danu.

Bi ọbẹ̀ bá dànù, kò ṣe kó padà, à fi ki enia se ọbẹ̀ tuntun, bi ó bá fẹ jẹ ọbẹ̀.  Yorùbá ni “Ẹ̀bẹ̀ là nbẹ òṣikà, ki ó tú ilú ṣe”.  Fún àtúnṣe, ó ṣe pàtàki ki gbogbo ará ilú parapọ̀ lati tún ohun ti ó ti bàjẹ́ ṣe nipa gbi gbé ogun ti iwà ìbàjẹ́ àti àbẹ̀tẹ́lẹ̀ gbi gbà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-04-08 11:31:39. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ̀kọ́ àti Ọgbọ́n ni Ọ̀rọ̀ Àgbà lati Ẹnu Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ lórí Ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán Òpómúléró – Review of Words of Wisdom by Dr. Victor Omololu Olunloyo on Opomulero TV

Bi a ba fi eti si ọ̀rọ̀ ti àgbà Yorùbá Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ  ni ori ẹ̀rọ “Amóhùnmáwòrán Òpómúléró”, ni ori ayélujára, a o ṣe àkíyèsí àwọn nkan wọnyi:

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ fi àṣà Yorùbá ti ó ti ńparẹ́ hàn nipa bi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú “Oríkì”

Nínú ìtàn lati ẹnu agba, a o ri pé Bàbá loye lati kékeré.  Nkan bàbàrà ni ki ọmọ jade ni ilé ìwé giga ni ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ki ó si gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n ni ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.  Ni ọdún Ẹgbàádínméjìdínlógójì,  Gẹ́gẹ́ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ẹ̀kọ́ Ìṣirò, Ìjọba Ipinlẹ Ìwọ Oòrùn ayé ìgbà yẹn kò sọ pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ kéré jú lati fún ni ipò Alaṣẹ lóri iṣẹ́ Ìdàgbàsókè Ìtọ́jú Owó.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ fihàn pé, lai si ni ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, kò ni ki á di ọ̀tá bi ti ayé òde òní.  A ri àpẹrẹ bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Olunlọyọ ṣe súnmọ́ Olóògbé Olóye Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tó, bi ó ti jẹ́ wi pé wọn kò si ninú ẹgbẹ́ Òṣèlú kan naa, àwọn méjèèji jẹ olootọ ti ó si ni ìgboyà.

Ọgbọ́n ki i tán, bi Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọmọlolú Olunlọyọ ti kàwé tó, Bàbá ṣi ńkàwé lati wá ìmọ̀ kún ìmọ̀. Ọgbọ́n púpọ̀ wà ni ọ̀rọ̀ àgbà yi, ẹ ṣe àyẹ̀wò ọ̀rọ̀ yi lóri Amóhùnmáwòrán Òpómúléró.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2018-03-30 20:39:07. Republished by Blog Post Promoter