Tag Archives: The Greatest

Muhammad Ali – Ọ̀gá pátápátá Afẹ̀ṣẹ́ kù bi Òjò àwọn Akànṣẹ́ Relé: “The Greatest Boxer” – Muhammad Ali has gone home

Worshipers and well-wishers take photographs as the casket with the body of the late boxing champion Muhammad Ali is brought for his jenazah, …

Ìròyìn ikú Muhammad Ali ọmọ ọdún mẹ́rinlélaadọrin kàn ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹta, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún.  Bi ó ti ẹ jẹ wi pé, Ali ti wà lóri àisàn fún bi ọgbọ̀n ọdún, inú ọmọdé àti àgbà ni àgbáyé ṣe ìdárò nigbati wọn gbọ ìròyìn ikú rẹ.

Ki ṣe iṣẹ́ akànṣẹ́ nikan ni Muhammad Ali dúró fún, ó dúró fún ohun ti ó gbàgbọ́ lai bẹ̀rù.  Ni bi ọdún marun-dinlọgọta sẹhin, nigbati Aláwọ-funfun ṣe òfin lati ya Aláwọ̀-dúdú si ọ̀tọ̀, pé wọn kò lè lo ohun amáyédẹrùn (bi ọkọ̀ wi wọ̀ pọ̀, ilé oúnjẹ, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bẹ́ ẹ̀ b ẹ́ ẹ̀  lọ)  ti wọn pèsè fún ará ilú pẹ̀lú Aláwọ-funfun, Muhammad Ali kò pa ẹnu mọ lati dẹbi fún irú òfin àti iwà burúkú yi.  Ó kọ̀ lati lọ jagun (Vietnam), ti kò gbàgbọ́ nitori ó gbàgbọ́ pé alafia dára ju ogun lọ.  Muhammad Ali yi orúkọ ẹrú “Cacius Clay’’àti ẹ̀sìn padà lati kọ ẹ̀hin si iwà burúkú ti Aláwọ-funfun hù si enia rẹ.

Muhammad Ali mú adùn wọ iṣẹ́ akànṣẹ́, ó fi ọlà rẹ ṣe àánú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláìní, ó si jẹ àwòkọ̀ṣe fún àwọn ọ̀dọ́ pàtàki Aláwọ̀-dúdú ti ó fi hà̀n pé ‘kò si ohun ti kò ṣe é ṣe, bi enia bá fi ọkàn si’.  Eleyi jẹ ki èrò fẹ́ràn rẹ púpọ̀.

Muhammad Ali and Joe Frazier – The Thrilla In Manila

Àwọn Olóri Ilú àti Ẹlẹ́sin ni oriṣiriṣi ati gbogbo àgbáyé ṣe ìdárò Muhammad Ali bi wọn ti ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin tó yẹ fún Ọba, ni ibi ìtẹ́ ìsìnkú ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kẹwa, ọdún Ẹgbàálémẹ́rìndínlógún.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ, ọmọ-ọmọ, Ìyàwó, ẹbi àti ará ló gbẹ̀hin rẹ.  Sùn re o.

 

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button