Tag Archives: Polygamy

Gbẹ̀dẹ̀ bi Ogún Ìyá, Ogún Bàbá ló ni ni lára – Maternal Inheritance comes with ease, while paternal inheritance brings about trouble

Ogún jẹ́ gbogbo ohun ìní ti bàbá tàbi ìyá bá fi silẹ́ ti wọn bá kú.  Ni ìgbà àtijọ́, kò wọ́pọ̀ ki olóògbé ṣe ìwé-ìhágún, bi wọn ṣe má a pín ohun ini wọn lẹhin ikú.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ki i ni ọrọ̀ bi ti àwọn ọkùnrin nitori wọn ki i ni ogún bi ilé, ilẹ̀ tàbi oko.  Bi wọn ba ti fẹ ọkọ pàtàki bi ẹbi bá ti gba nkan orí ìyàwó, wọn kò tún lè padà wá gba ilé, ilẹ̀ tàbi oko ni ilé bàbá wọn, nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin kò ni ohun ini púpọ̀.  Ọkùnrin ló ni oko, ilé àti ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àṣà àdáyé ba nitori àwọn ni ‘’Àrólé’’ ti ó njẹ́ orúkọ ìdílé.

Àwọn obìnrin Yorùbá bi Ìyá Tinubu, Ẹfúnṣetán Iyalode Ìbàdàn, Ìyá Tẹ́júoṣó, mọ nipa iṣẹ́ òwò púpọ̀ àti pé láyé òde òni àwọn obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ si kàwé lati lè ṣe iṣẹ ti àwọn ọkùnrin nṣe tẹ́lẹ̀.  Nitori eyi,  lati ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn obìnrin Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si ni ohun ini bi ilé, ilẹ̀, owó tàbi oko ti ọmọ lè jogún.

Lẹhin ikú bàbá tàbi ìyá, lai si ìwé-ìhágún, àwọn ẹbí ni àṣà àdáyébá ti wọn fi le pín ogún fún àwọn ọmọ olóògbé.  Àwọn ẹbí miran lè lo ‘’orí ò jorí’’ tàbi idi-igi (oye ìyàwó) ti ó bá jẹ ogún bàbá.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bàbá gbogbo ayé”, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ bàbá lo ni iyawo púpọ̀.  Ìdí ti ogún bàbá ṣe lè mú ìnira wá ni wi pé ohun ti wọn bá pín fún idi-igi kan lè fa owú jijẹ fún idi-igi miran eyi si ma a ndá ìjà silẹ̀ lẹhin ikú bàbá.  Eyi pẹ̀lú idi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ki i náání ohun ini bàbá lẹhin ikú irú bàbá bẹ́ ẹ̀.  Ìgbà miran idi-igi ti o jogún ilé, lè má lè tọ́jú rẹ titi yio fi wó.

Àwọn ilé ti wọn kò tọ́jú – Abandoned houses

Ogún ìyá ko ti bẹ̀rẹ̀ si fa ìjà bi ti bàbá.  Ó lè jẹ́ wi pé nitori àwọn obìnrin ti o ni ogún ti wọn lè jà lé kò ti pọ̀ tó bi ti àwọn ọkùnrin ti o ni ìyàwó àti ohun ìní rẹpẹtẹ.  Yoruba ni ‘Ọmọ ti a kò kọ́ ló ngbé ilé ti a bá kọ́ tà’.  Ọmọ ti ó bá njà du ogún ma nba ogún jẹ ni. Lati din rògbòdiyàn ti ogún ma nfà, ó yẹ ki bàbá tàbi ìyá ṣe ìwé-ìhágún, ki wọn fún ọmọ ni ẹ̀kọ́ ilé àti ẹ̀kọ́ ilé-iwé ti ọmọ kò ni fi jà du ogún bàbá tàbi ti ìyá.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

“Ni Ayé òde òni, njẹ́ ó yẹ ki a pọ́n Àṣà fi fẹ́ Iyàwó púpọ̀ lé ni Igbéyàwó Ìbílẹ̀ Yorùbá?” – “In Modern times, should Polygamy be encouraged in Yoruba Traditional Marriage?”

Ni igbà àtijọ́, oníyàwó kan kò wọ́pọ̀ nitori iṣẹ́ Àgbẹ̀.  Àṣà fi fẹ́ iyàwó púpọ̀ ṣe kókó nitori bibi ọmọ púpọ̀ pàtàki ọmọ ọkùnrin fún irànlọ́wọ́ iṣẹ́-oko.  Fi fẹ̀ iyàwó púpọ̀ kò pin si ilẹ̀ Yorùbá tàbi ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú nikan, ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀funfun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin ṣùgbọ́n nitori òwò ẹrú àti ẹ̀sin igbàgbọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ àṣà fi fẹ iyàwó kan.  Lẹhin òwò ẹrú, li lo ẹ̀rọ igbàlódé fún iṣẹ́ oko jẹ ki Aláwọ̀funfun lè dúró pẹ̀lú àṣà fi fẹ́ iyàwó kan.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ayé òde òni ti kọ àṣà fi fẹ́ iyàwó púpọ̀ silẹ̀ nitori ẹ̀sìn, ìmọ̀ àti si sá fún rògbòdiyàn ti ó lọ pẹ̀lú iyàwó púpọ̀.  Iṣẹ́ Alákọ̀wé kò ṣe fi jogún fún ọmọ nitori iwé-ẹ̀ri àti ipò ti èniyàn dé ni iṣẹ́ Akọ̀wé tàbi iṣẹ́ Ìjọba kò ṣe fi jogún fún ọmọ bi oko.  Owó ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Oniṣẹ́-oṣ̀u ngba kò tó lati bọ́ iyàwó kan ki owó oṣù míràn tó wọlé, bẹni kò tó gba ilé nla ti ó lè gba iyàwó púpọ̀ pàtàki ni ilú nla bi Èkó.  Àṣà iyàwó púpọ̀ ṣi pọ̀, ni àwọn ilú kékeré tàbi Abúlé laarin àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ti kò kàwé.

Ọmọ Oníyàwó púpọ̀ – Many children of a PolygamistYorùbá ni “Bàbá, bàbá gbogbo ayé”, bi iyàwó kò bá ni iṣẹ́ lati tọ́jú ọmọ wọn, ìṣẹ́ dé, nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin Yorùbá ma ntẹpá mọ́ṣẹ́ lati lè tọ́jú ọmọ wọn lai dúró de ọkọ.  Ìyà àti ìṣẹ́ ni fún ọmọ púpọ̀ àti àwon iyàwó ọkùnrin ti kò ni iṣẹ́ tàbi eyi ti ó ni iṣẹ́ ti kò wúlò.

Ewu ti ó wà ni ilé oníyàwó  púpọ̀ ju ire ibẹ̀ lọ.  Yorùbá ni “Oníyàwó kan kò mọ ẹjọ́ oníyàwó  púpọ̀ da a”.  Lára ewu wọnyi ni, ki i si ifọ̀kànbalẹ̀ nitori ijà àti ariwo ti owú ji jẹ laarin àwọn iyàwó ma nfà pàtàki ni agbo ilé nlá tàbi ilé Ọlọ́rọ̀ àti Olóyè.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oníyàwó  púpọ̀ ma nda ahoro lẹhin ikú Olóri ilé nitori kò si ẹni ti ó ni ìfẹ́ tọ si Bàbá oníyàwó  púpọ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share

Òrìṣà òkè jẹ́ ki npé meji obinrin kò dé inú – Àṣà Ìkó-binrin-jọ: “The prayer of a woman to the god of heaven to have a co-wife/rival is not sincere” – The Culture of Polygamy

Ọkùnrin kan pẹ̀lú iyàwó púpọ̀ wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá.  Àwọn obinrin ti ó bá́ fẹ́ ọkọ kan naa ni à ńpè ni “Orogún”.  Ìwà oriṣiriṣi ni ó ma ńhàn ni ilé olórogún, àrù̀n iyàwó ti ó ńjalè, purọ́, ṣe àgbèrè, aláisàn, ti ó ńṣe òfófó, àti bẹ̃bẹ lọ,  lè má hàn bi ó bá jẹ́ obinrin kan pẹ̀lú ọkọ rẹ ni ó ńgbe gẹ́gẹ́ bi ti ayé ode oni.  Bi iyàwó bá ti pé meji, mẹta, bi àrù́n yi bá hàn si iyàwó keji, èébú dé, pataki ni àsikò ijà.

Ni ẹ̀sin ibilẹ̀, oye iyàwó ti ọkùnrin lè fẹ́, ko niye, pàtàki Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti akikanjú ni àwùjọ.  Bi àwọn ti ó ni ipò giga tabi òkìkí ni àwùjọ kò fẹ́ fẹ́ iyàwó púpọ̀, ará ilú á fi obinrin ta wọn lọ́rẹ.  Ẹ̀sin igbàlódé pàtàki, ẹ̀sin igbàgbọ́ ti din àṣà ikó-binrin-jọ kù.  Òfin ẹlẹ́sin igbàgbọ́ ni “ọkọ kan àti aya kan”.  Bi o ti jẹ́ pé ẹ̀sin Musulumi gbà ki  “Ọkùnrin lè fẹ́ iyàwó titi dé mẹrin”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin Musulumi igbàlódé ńsá fún kikó iyàwó jọ.

Fẹlá Kúti fẹ́ iyàwó mẹta-din-lọgbọn ni ọjọ kan – Fela Kuti married 27 wives in one day

Fẹlá Kúti fẹ́ iyàwó mẹta-din-lọgbọn ni ọjọ kan – Fela Kuti married 27 wives in one day

Yorùbá ni “Òriṣà òkè jẹ́ ki npé meji obinrin kò dé nú”.  Inú obinrin ti wọn fẹ́ iyàwó tẹ̀lé kò lè dùn dé inú, nitori eyi, kò lè fi gbogbo ọkàn rẹ tán ọkọ rẹ mọ, owú jijẹ á bẹ̀rẹ̀.  Iyàwó kékeré lè dé ilé ri àbùkù ọkọ ti iyálé mú mọ́ra.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oló-rogún kiki ijà àti ariwo laarin àwọn iyàwó àti àwọn ọmọ naa.  Diẹ̀ ninú ọkùnrin ti ó fẹ́ iyàwó púpọ̀ ló ni igbádùn.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ti ó kó obinrin jọ ni ó ńsọ ẹ̀mi wọn nù ni ọjọ́ ai pẹ́ nitori ai ni ifọ̀kànbalẹ̀ àti àisàn ti bi bá obinrin púpọ̀ lò pọ̀ lè fà.   Nitori eyi, ọkùnrin ti ó bá fẹ́ kó iyàwó jọ nilati múra gidigidi fun ohun ti ó ma gbẹ̀hìn àṣà yi.

ENGLISH LANGUAGE Continue reading

Share