Tag Archives: Plantain

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa” – Plantain – “Unripe/rotten plantain is no easy snack, beating a bad behaved child to death is not an option”.

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ – Bunch of unripe Plantains and Bananas Banana

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ jẹ́ èso ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ohun ọgbin ti a lè ri ni ilẹ̀ Yorùbá pàtàki ni agbègbè Okitipupa ni ipinlẹ Ondo.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ pé oriṣiriṣi, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ni à nsè fun jijẹ, nigbati ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ dára fún jijẹ bi èso lai sè.  Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tóbi ju ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ lọ.

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ọkọ̀ tó kó Ọ̀gẹ̀dẹ̀ – Lorry load of Plantain. Courtesy: theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, ohun ọgbin ti ó bá pọ̀ ni agbègbè ni èniyàn ma njẹ, nitori ko si ọkọ̀ tàbi ohun irinna tó yá  lati kó irè oko kan lọ si ekeji.  Eleyi jẹ ki àwọn ti iṣu pọ ni ọ̀dọ̀ wọn lo iṣu lati ṣe oúnjẹ ni oriṣiriṣi ọ̀nà, àwọn ti o ni àgbàdo pupọ nlo fún onírúurú oúnjẹ ti a lè fi àgbàdo ṣe, àwọn ti ó ni ẹ̀gẹ́/gbaguda ma nlo lati ṣe oriṣiriṣi oúnjẹ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìyàtọ laarin iṣu ati ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni pé, wọn wa iṣu ninú ebè nigbati wọn nbẹ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóri igi rẹ.  Kò si iyàtọ̀ laarin Èlùbọ́ iṣu àti Èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀, ṣugbon bi a bá ro fun àmàlà, àmàlà iṣu dúdú díẹ ju èlùbọ́ ọ̀gẹ̀dẹ̀ gbigbẹ, àmàlà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tútù kò dúdú ó pọ́n fẹ́rẹ́fẹ́.  Iṣu tútù kò ṣe e bùṣán nitori yio yún èniyàn ni ọ̀fun, nibi ti ó burú dé, bi omi ti wọn fi fọ iṣu bá ta si ni lára, yio fa ara yin yún. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá ti ó ni “Ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú/burúkú kò yá bù ṣán, ọmọ burúkú kò yá lù pa”, ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú kò dùn lati jẹ ni tútù, eyi ti ó bá ti kẹ̀ naa kò ṣe é jẹ, ṣùgbọ́n ọ̀gẹ̀dẹ̀ ti ó pọ́n ṣe jẹ ni pi pọ́n lai sè nitori adùn rẹ.  Àti ewé àti èso ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ó wúlò fún jijẹ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-12-02 19:09:48. Republished by Blog Post Promoter