Tag Archives: nigeria

Ounjẹ Yorùbá: Yoruba Food

Ẹ GBA OUNJẸ YORÙBÁ LÀ: SAVE YORÙBÁ: SAVE YORUBA FOOD

Ọpọlọpọ oriṣiriṣi ounjẹ Yorùbá nparẹ lọ, nípàtàkì larin awọn to ngbe ìlú nla.  Òwe Yorùbá ni “Ki àgbàdo to de ilẹ aye, adíyẹ njẹ, adíyẹ nmu”.  Itumo eyi nipe ki a to bẹrẹ si ra ounjẹ latokere, a nri ounjẹ ilẹ wa jẹ. Awọn to ngbe ilu nla bi ti Eko ko ri aye lati se ọpọlọpọ ounjẹ ilẹ wa, èyí ko jẹki àlejò mọ wipe Yorùbá ni oriṣiriṣi ọbẹ, ounjẹ ati ìpanu. Ni ọpọ ọdun sẹhin, irẹsi ki ṣe ounjẹ ojojumọ ṣugbọn fun awọn ọmọ igbalode, Irẹsi “Burẹdi” ati “Indomie” ti di ounjẹ.  Ọpọlọpọ ko ti ẹ fẹ jẹ ounjẹ ibilẹ bi awọn ounjẹ òkèlè: Iyán, Ẹba, Láfún ati bệbệ lọ.  Ti a ba ṣakiyesi, ọpọ ọmọ to dagba si Eko, ko mọ wipe Yorùbá ni ju ọbẹ ata ati ẹfọ/ila lọ.  Ọbẹ ata lo yá lati fi jẹ irẹsi, nitori ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyi le jẹ irẹsi lojojumọ, larọ, lọsan ati lalẹ.  Ni ìlú Èkó, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki obi tètè délé lẹhin iṣẹ ojọ wọn, ẹlo miran ti ji kuro nílé lati bi agogo mẹrinabọ lai pada sílé titi di agogo mẹwa alẹ nigbati awọn ọmọ tisùn.  Nitori èyí ọpọ òbí ko ri aye lati se ounjẹ Yorùbá.   Àìsí ina manamana dédé tun da kun ifẹ si ounjẹ pápàpá.

Ìyàlẹnu ni wipe ọpọ awọn ti ówà l’Okeokun ngbe ounjẹ Yorùbá larugẹ ju awọn ti ówà ni ilé lọ pàtàkì ni ilu nla. Oṣeṣe pe bi iná manamana ba ṣe dédé ounje Yoruba yio gbayi si, nitori awọn òbì ma le se oriṣiriṣi ounjẹ pamọ.   Ẹjọwọ ẹ maṣe jẹ ki a fi ounjẹ òkèrè dipo ounjẹ ilẹ wa, okùnfà gbèsè ni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-19 21:47:33. Republished by Blog Post Promoter

ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ – Everyday is for the thief … a warning to fraudsters

ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ, ỌJỌ KAN NI TOLÓHUN”: “EVERYDAY IS FOR THE THIEF, ONE DAY FOR THE OWNER”.

Ní ọjọ Ẹti ọjọ keji lelogun oṣu keji ọdún yi, Ẹrọ amóhùn máwòrán Iluọba (BBC 1) tu asiri ọmọkunrin kan ti o ni iwe ijẹri irina ọmọ Naijeria ni oruko ọtọtọ mẹta ti o fi nlu ìjọba ní jìbìtì gba iranlọwọ ti ko tọ si. O ti gba owó rẹpẹtẹ ki wọn to ri mu.

Ni Ìlú Ọba (United Kingdom) Ìjọba pese ilé fún awọn abirùn ati aláìní ti o jẹ ọmọ onilu ati iranlọwọ miran lati mu ayé dẹrùn fún wọn.  Àwọn àjòjì ti o fi èrú ati irọ gba àwọn iranlọwọ yi, wọn a dẹ tún fi ma yangan titi ọjọ ti olóhun yio fi muwọn.  Irú iwa burúkú bi ka fi èrú gba ohun ti ko tọ wọnyi mba orúkọ jẹ.

Ẹ jẹ ki a fi owé Yorùbá to wipe “Ọjọ gbogbo ni tolè, ọjọ kan ni tolóhun” se ikilo fun iru awọn oníjìbìtì bẹ ere jibiti, nitori bi o ti wu ko pẹ to, ọjọ kan ọwọ òfin a ba iru àwọn bẹ.  Nigbati wọn ba ri wọn mu, wọn a ko ìtìjú ba orúkọ idile ati ìlú wọn.

ENGLISH TRANSLATION

On Friday 22nd February 2013, BBC 1 Television Channel exposed a man with 3 Nigerian Passports in different names that he was using to defraud the Government by collecting benefits that he was not entitled to claim.  He had collected large sums of money before he was caught. Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-22 20:58:21. Republished by Blog Post Promoter

“Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú Awólọ́wọ̀, Iyalode Rẹ́mọ, Yèyé Oòduà relé pẹ̀lú ijó àti ayọ̀” – “Chief (Mrs) Hannah Idowu Dideolu Awolowo, Remo Women Leader, Mother of Oodua departed with pomp and pageantry”

A bi Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ni ọjọ́ karundinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla, ọdún Ẹ̀dẹ́ẹ́gbãlemẹ̃dógún, ó ṣe igbéyàwó pẹ̀lú Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àgbà Òṣèlú ni ọjọ́ kẹrindinlọ́gbọ̀n, oṣù kejila, Ẹ̀dẹ́ẹ́gbãlemẹ̃tadinlọ́gbọ̀n, o jade láyé nigbati ó kú bi oṣú meji ó lé di ẹ ki ó pé ọgọrun ọdún.Image result for h i d awolowo burial

“Lẹhin ọkùnrin tàbi obinrin (ni ayé òde òni) ti ó bá ṣe ori-ire, obinrin tàbi ọkunrin rere wa lẹhin tabi ẹ̀gbẹ rẹ”.  Òwe yi ni a lè fi ṣe àpẹrẹ iṣẹ́ ribiribi ti Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ṣe fún Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ògúná gbongbo Òṣèlú ni ilẹ̀ Yorùbá àti fún orilẹ̀ èdè Nigeria.  Nigbati Bàbá mba iṣẹ́ oselu kiri gbogbo àgbáyé, Iyá ló di ilé mú, ti ọkàn Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ fi balẹ̀ lati le fi ipò Olóri Òsèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe.  Titi di ọjọ́ ikú ọkọ rẹ ni ọdún mejidinlọ́gbọ̀n sẹhin, lẹhin igbéyàwó àádọ́ta ọdún, ó ṣe àti lẹhin fún ọkọ rẹ titi di ọjọ́ alẹ́, eyi jẹ àpẹrẹ rere fún gbogbo obinrin.

Ẹbi àti ará ti bẹ̀rẹ̀ si palẹ̀mọ́ fún ọjọ́ ibi ọgọrun fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú nigbati iròyin ikú rẹ jade pé iyá sùn ni ọjọ kọkàndinlógún, oṣú kẹsan ọdún Ẹgbàálemẹ̃dógún.  Ipalẹ̀mọ́ ìsìnku bẹ̀rẹ lati ṣe àṣeyẹ ikẹhin fún olóògbé dipò ayẹyẹ ọjọ́ ọgọrun ibi. 

Olóri Òṣèlú Nigeria Muhammadu Buhari pẹ̀lú àwọn àgbà Òsèlú, àwọn Ọba àti  Ìjòyè, ọmọdé àti àgbà ilú dara pọ̀ pẹ̀lú ẹbi àti àwọn ọmọ Olóògbé lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú Awólọ́wọ̀ ni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla ọdún Ẹgbàálemẹ̃dógún.

Sùn re o, ó digbà, o di gbóṣe.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

“Ẹni àjò ò pé, kó múra ilé” – “Ìjà Boko Haram” – The person for whom a journey has not been profitable, should prepare to return home – “Boko Haram mayhem”

Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà ti ó wà ni Ìwọ̀-õrùn orilẹ̀ èdè Nigeria.  Bi Yorùbá ti fẹ́ràn igbádùn tó, bẹ ni wọn fẹ́ràn òwò ṣiṣe àti ẹ̀kọ́ kikọ́.  Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti aláìní ilẹ̀ Yorùbá ló fẹ́ràn àti rán ọmọ wọn lọ si ilé-iwé bi àwọn fúnra wọn kò ti ẹ lọ si ilé-iwé. Eleyi jẹ ki Yorùbá pọ kà kiri àgbáyé pàtàki ni Àríwá/Òkè-ọya Nigeria.

Nibi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ti fẹ́ràn “iwé-kikà” ni ẹ̀yà miràn ti fi ẹsin bojú lati ṣe àtakò iwé kikà, pàtàki àwọn ti o ni “A ò fẹ́ iwé – Boko Haram”.   Àwọn ti ó ni àwọn kò fẹ́ lọ si ilé-iwé bẹ̀rẹ̀ si pa ọmọ àwọn ti ó fẹ́ lọ.  Wọn kò dúró lóri ọmọ ilé-iwé nikan, wọn ńpa enia bi ẹni pa ẹran ni ọjà, oko, ilú, ọ̀nà àti gbogbo ibi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú ni òkè-Ọya pàtàki ni ilú “Borno”.

Girls kidnapped from Nigeria school

Islamic militants suspected in Nigeria abduction of 100 female students

Yorùbá ni “Bi onilé bá ti ńfi àpárí iṣu lọ àlejò, ilé tó lọ”.  Ki ṣe àpárí iṣu nikan ni wọn fi ńlọ àjòjì ni òkè-ọya/Àriwá “ikú òjiji” ni.  Àini ifọkàn balẹ̀ kò lè jẹ́ ki àjò ò pé.  Lati igbà ti “ẹni ti ó so iná ajónirun mọ́ra” ti bẹ̀rẹ̀ si pa enia bi ẹni pẹran ni ilé ijọsin – pàtàki ti onígbàgbọ́; ọjà; ãrin ilú; abúlé àti ilé-iwé ni àjò kò ti pé mọ́. Ìròyìn kàn ni ọjọ́ kẹdogun oṣù kẹrin ọdún ẹgbã-lé-mẹrinla, pe wọn ti tún bẹ̀rẹ̀ si ji ọmọ ilé-iwé gbé – ó lé ni ọgọrun  ọmọ obinrin ti wọn fi ipá ji wọn gbé, mẹrinla ni ó ri àyè sá mọ́ ajínigbé lọ́wọ́, òbi àwọn ti ó kù wà ninú ìrora.

A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni “Ẹni àjò ò pé, kó múra ilé” gba àwọn Yorùbá ti ó wà ni òkè-ọya ni ìyànjú pé ki wọn bẹ̀rẹ̀ si múra ilé, ki wọn ma ba pàdánù ẹmi, ó sàn ki enia pàdánù owó ju ẹ̀mi lọ.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

A kì dàgbà jẹ Òjó: Natural birth names not apt at old age — ÌDÁRÚKỌ PADÀ UNILAG – THE UNILAG NAME CHANGE

Univesity of Lagos Senate

UNILAG Senate Building – photo from http://www.unilag.edu.ng/

“A kì dàgbà jẹ Òjó”: “Natural birth names not appropriate at old age”

Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde ati bebe lo je orúkọ amu tọrun wa.  Pípa orúkọ Ilé-ìwé gíga ni Akoka, ilu Eko da lẹhin aadọta ọdún dàbí ìgbà ti a sọ arúgbó lorukọ àmú tọrun wa.  Apẹrẹ: ẹni ti ki ṣe ibeji ko le pa orúkọ da si orúkọ àmú tọrun wa.

A dupẹ lọwọ Olórí Ìlú Goodluck Jonathan to gbọ igbe awọn ènìyàn lati da orúkọ Ilé-ìwé Gíga ti o wa ni Akoko ti Ilu Eko pada gẹgẹbi Olukọagba Jerry Gana, ti kọ si ìwé ìròyìn ni ọjọ Ẹti, oṣù keji ẹgbaa le mẹtala.

ENGLISH TRANSLATION

Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde etc, all these names in Yoruba are given at birth as a result of natural circumstances observed at birth.  Continue reading

Share Button

ÌRÒYÌN – NEWS: Ogun àsọ tẹlẹ – A War Aforetold

ÌRÒYÌN ÌJÌ NLA JÀ NI ÌBÀDÀN: NEWS OF RAIN STORM IN THE IBADAN

Òjò ati ìjì bẹrẹ ni arọkutu ọjọ ajé, ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdún ẹgbẹwa le mẹtala.  Ìjì naa ba ílé ati ọna jẹ rẹpẹtẹ ni ìlú Ìbàdàn

Òwe Yorùbá sọ wipe “Ogun àsọ tẹlẹ ki parọ to ba gbọn”.  O ṣeni lanu wipe ko si àsọ tẹl tabi ipalẹmọ fún ará ìlú ati ijọba.  Iyalẹnu ni wipe lati ọpọ ọdun ti ìjì àti àgbàrá lati odò Ògùnpa ti mba ilé ati ọna jẹ lọdọdun, Ìjọba Ọyọ ko ti ri ogbọn kọ lati da ẹkun ati ibanujẹ ti iṣẹlẹ yi nda silẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Rain storm began early on Monday morning, 18 February, 2013.  The rain storm destroyed homes and properties in Ogun state, Nigeria. Continue reading

Share Button