Tag Archives: Nigeria Independence

Àjọ̀dún Òmìnira Nigeria Kẹrindinlọgọta – Nigeria’s Fifty-six Independence Celebration

Àjọ̀dún Òmìnira Nigeria Kẹrindinlaadọta – Nigeria’s Fifty-six Independence Celebration.  Courtesy: @theyorubablog

Àjọ̀dún Òmìnira Nigeria Kẹrindinlaadọta – Nigeria’s Fifty-six Independence Celebration. Courtesy: @theyorubablog

Share Button

Originally posted 2016-10-01 00:37:30. Republished by Blog Post Promoter

Olùkọ̀wé Èdè àti Àṣà Yorùbá lóri ayélujára, ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria kú àjọ̀dún Òmìnira kejìdínlọ́gọ́ta – The Yoruba Blog wishes all Nigerians happy 58th Independence Celebration

Àsíá orílẹ̀ èdè Nigeria – Nigerian Flag.

Fún ọdún mọ́kàndín-lọgọrun lati ìgbà ti Òyìnbó Ìlú-Ọba ti fi ipá gba Èkó titi di ọjọ́ kini oṣù kẹwa, odun Ẹgbẹ̀sánlé-ọkanlelọgọta ti orílẹ̀ èdè Nigeria gba Òmìnira, Òyìnbó Ìlú-Ọba kan èdè Gẹ̀ẹ́sì wọn nípá, wọ́n tún gàba lóri ọrọ adánidá ni orílẹ̀ èdè Nigeria.  Ṣi ṣe ìrántí Òmìnira yẹ kó rán gbobgo ọmọ Nigeria lápapọ̀ létí iṣé takun-takun ti àwọn olóri òṣèlú parapọ̀ ṣe lati tú orílẹ̀ èdè sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì, pàtàki bi àwọn olóri òṣèlú Ìlà-oòrùn àti Ìwọ̀-oòrùn ti kó ra pọ̀.  Èyi fi hàn wi pé bi àwọn  òṣèlú ayé òde òní bá fi ìfẹ orílẹ̀ èdè ṣáájú, wọn kò ni fi ẹ̀sìn àti ẹ̀yà bojú lati tú orílẹ̀ èdè ka, èyi ti ó njẹ ki wọn ri àyè jí ìṣúra orílẹ̀ èdè si àpò ara wọn nitori eyi, ó yẹ ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria ti ó ni ìfẹ́ orílẹ̀ èdè, pẹnupọ̀ lati bá àwọn òṣèlú ti ó nja ilú ló olè wi.

Bi a ṣe nṣe àjọ̀dún Òmìnira kejìdínlọ́gọ́ta yi, ó yẹ ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria gbé ìfẹ́ lékè ìríra.  Ìfẹ́ ló lè borí li lo ẹ̀yà àti ẹ̀sìn lati pín orílẹ̀ èdè, ti ó tún lè dín ojúkòkòrò àwọn òṣèlú kù.

Lati ọ̀dọ̀ àwọn Olùkọ̀wé Èdè àti Àṣà Yorùbá lóri ayélujára, a ki gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nigeria kú àjọ̀dún Òmìnira.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button