Tag Archives: National Judicial Council

“Njẹ́ ó yẹ ki Adájọ́ ti ó bá hu iwà ibàjẹ́ kọjá Òfin?” – “Should Judges be above the Law?”

Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn - DSS arrest of alleged corrupt Judges. Courtesy: @theyorubablog

Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn – DSS arrest of alleged corrupt Judges. Courtesy: @theyorubablog

Ni ọjọ́ Ẹti, ọjọ́ keje, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbàálémẹ̀rindinlógún, ìròyìn pé àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ já lu ilé àwọn Adájọ́ ti wọn fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kàn jade lẹhin ti wọn ti dúró titi ki “Ẹgbẹ́ Adájọ́” gbé àwọn iwé ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ yẹ̀wò .  Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ròyìn pé wọn bá owó rẹpẹtẹ, pàtàki oriṣiriṣi owó òkè òkun, ni ilé awon Adájọ́ wọnyi.   Lati igbà ti iroyin ti jade, àwọn ‘Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò’ lérí pé àwọn yio da iṣẹ́ silẹ̀ ti Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari kò bá pàṣẹ ki wọn tú àwọn Adájọ́ naa silẹ̀ ni wéréwéré.

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, Adájọ́ àti Agbẹjọ́rò ki i ṣe iṣẹ́ nitori àgbà ni ó ndá ẹjọ́ bi ijà bá bẹ́ silẹ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá.  Fun àpẹrẹ, bi àwọn ọmọdé bá njá, àgbàlagbà ti ó bá wà ni ilé ni yio là wọ́n, bi àwọn iyàwó-ilé bá njà, olóri ẹbi tàbi Àrẹ̀mọ ni yio la ijà.  Bi ó bá jẹ́ ijà nitori ilẹ̀ oko, Baálẹ̀ Abúlé naa ni wọn yio kó ẹjọ́ lọ bá fún idájọ́, ti ó bá jẹ àdúgbò kan si ekeji ló njà, wọn á kó ẹjọ́ lọ bá Ọba ilú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.   Lati wa idi òtitọ́, wọn lè kó àwọn ti ó njà lọ si ojúbọ Òriṣà lati búra.  Lẹhin ti àwọn Ìlú-Ọba pin àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú àwọn Aláwọ̀dúdú, iṣẹ́ Agbẹjọ́rò di ki kọ́ ni ilé-iwé giga.

Kò si ọmọ Nigeria rere ti kò mọ̀ wi pé,  ‘’Ẹ̀ṣẹ̀ nlá ijiyà kékeré tàbi ki ó má si ijiyà rara fún Olówó, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kékeré ijiyà nla ni fún tálákà tàbi aláìní’’, nitori iwà burúkú àwọn Adájọ́ ti ó ti gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Agbejoro.  A ri gbọ́ wi pé bi “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò” bá ni ẹjọ́ ni iwájú Adájọ́ lẹhin ti ẹjọ́  agbejoro ti dé iwájú Adájọ́, wọn yio kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ ti “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò” gbé wá.  Eleyi jẹ́ ikan ninú idi pàtàki ti ọ̀pọ̀lọpọ̀  Agbejoro ti fẹ́ fi ọ̀nàkọnà dé ipò “Ọ̀gá Àgbà Agbẹjọ́rò”.  Ó yẹ ki wọn gbé eyi yẹ̀wò nitori ni ilú ti òfin bá wà, kò yẹ ki ẹnikẹni kọjá òfin.  Ni Òkè-Òkun, Gó́́mìnà, àgbà Òṣèlú àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ kò kọjá òfin.

“Ẹni ma a bèrè ẹ̀tó lábẹ́ òfin yio lọ pẹ̀lú ọwọ́ mímọ́”,  ẹ gb́e ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò bóyá bi wọ́n bá fi ẹ̀sùn iwà ibàjẹ́ kan Adájọ́, kò yẹ ki Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wa idi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-10-11 18:38:27. Republished by Blog Post Promoter