Tag Archives: Madam Tinubu

Gbẹ̀dẹ̀ bi Ogún Ìyá, Ogún Bàbá ló ni ni lára – Maternal Inheritance comes with ease, while paternal inheritance brings about trouble

Ogún jẹ́ gbogbo ohun ìní ti bàbá tàbi ìyá bá fi silẹ́ ti wọn bá kú.  Ni ìgbà àtijọ́, kò wọ́pọ̀ ki olóògbé ṣe ìwé-ìhágún, bi wọn ṣe má a pín ohun ini wọn lẹhin ikú.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ki i ni ọrọ̀ bi ti àwọn ọkùnrin nitori wọn ki i ni ogún bi ilé, ilẹ̀ tàbi oko.  Bi wọn ba ti fẹ ọkọ pàtàki bi ẹbi bá ti gba nkan orí ìyàwó, wọn kò tún lè padà wá gba ilé, ilẹ̀ tàbi oko ni ilé bàbá wọn, nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin kò ni ohun ini púpọ̀.  Ọkùnrin ló ni oko, ilé àti ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àṣà àdáyé ba nitori àwọn ni ‘’Àrólé’’ ti ó njẹ́ orúkọ ìdílé.

Àwọn obìnrin Yorùbá bi Ìyá Tinubu, Ẹfúnṣetán Iyalode Ìbàdàn, Ìyá Tẹ́júoṣó, mọ nipa iṣẹ́ òwò púpọ̀ àti pé láyé òde òni àwọn obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ si kàwé lati lè ṣe iṣẹ ti àwọn ọkùnrin nṣe tẹ́lẹ̀.  Nitori eyi,  lati ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn obìnrin Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si ni ohun ini bi ilé, ilẹ̀, owó tàbi oko ti ọmọ lè jogún.

Lẹhin ikú bàbá tàbi ìyá, lai si ìwé-ìhágún, àwọn ẹbí ni àṣà àdáyébá ti wọn fi le pín ogún fún àwọn ọmọ olóògbé.  Àwọn ẹbí miran lè lo ‘’orí ò jorí’’ tàbi idi-igi (oye ìyàwó) ti ó bá jẹ ogún bàbá.  Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bàbá gbogbo ayé”, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ bàbá lo ni iyawo púpọ̀.  Ìdí ti ogún bàbá ṣe lè mú ìnira wá ni wi pé ohun ti wọn bá pín fún idi-igi kan lè fa owú jijẹ fún idi-igi miran eyi si ma a ndá ìjà silẹ̀ lẹhin ikú bàbá.  Eyi pẹ̀lú idi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ki i náání ohun ini bàbá lẹhin ikú irú bàbá bẹ́ ẹ̀.  Ìgbà miran idi-igi ti o jogún ilé, lè má lè tọ́jú rẹ titi yio fi wó.

Àwọn ilé ti wọn kò tọ́jú – Abandoned houses

Ogún ìyá ko ti bẹ̀rẹ̀ si fa ìjà bi ti bàbá.  Ó lè jẹ́ wi pé nitori àwọn obìnrin ti o ni ogún ti wọn lè jà lé kò ti pọ̀ tó bi ti àwọn ọkùnrin ti o ni ìyàwó àti ohun ìní rẹpẹtẹ.  Yoruba ni ‘Ọmọ ti a kò kọ́ ló ngbé ilé ti a bá kọ́ tà’.  Ọmọ ti ó bá njà du ogún ma nba ogún jẹ ni. Lati din rògbòdiyàn ti ogún ma nfà, ó yẹ ki bàbá tàbi ìyá ṣe ìwé-ìhágún, ki wọn fún ọmọ ni ẹ̀kọ́ ilé àti ẹ̀kọ́ ilé-iwé ti ọmọ kò ni fi jà du ogún bàbá tàbi ti ìyá.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2017-10-27 10:54:25. Republished by Blog Post Promoter