Tag Archives: Mad person

A ki sọ pé ki wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri, bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́? – Never trust an unstable/unpredictable person with life and death decision making

Oriṣiriṣi wèrè ló wà, nitori pé ki ṣe wèrè ti ó wọ àkísà ni ìgboro tàbi já sita nikan ni wèrè.  Ẹnikẹni ti o nhu ìwà burúkú tàbi ṣe ìpinnu burúkú ni Yorùbá npè ni “wèrè”.

Wèrè – Mad person

Ìpinnu ṣi ṣe, ṣe pàtàki ni ayé àtijọ́ àti òde òní.  Òwe Yorùbá sọ wi pé “Bi ará ilé ẹni bá njẹ kòkòrò búburú, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ̀ kò ni jẹ́ ki a sùn ni òru”.  Àbáyọrí ìpinnu tàbi èrò burúkú kò pin si ọ̀dọ̀ ẹbi àwọn ti ó wà ni àyíká elérò burúkú, ó lè kan gbogbo àgbáyé. Fún àpẹrẹ, kò si ìyàtọ̀ laarin wèrè tó já sita nitori wèrè ni Yorùbá npe ọkọ tàbi ìyàwó ti ó ni ìwà burúkú, ẹbi burúkú, ọba ti ó nlo ipò rẹ lati rẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àti òṣèlu ti ó nja ilú ni olè lati kó owó ti wọn ji lọ si òkè òkun nibiti ohun amáyédẹrùn ti ilú wọn kò ni wà.

Gẹ́gẹ́ bi òwe Yoruba ti ó sọ wi pé “A ki sọ pé ki Wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri, bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́?” Ìtumọ̀ òwe yi ni wi pé ìpinnu pàtàki bi ìyè àti ikú kò ṣe é gbé lé wèrè lọ́wọ́. Ó yẹ ki àwọn ènìyàn gidi ti ori rẹ pé dásí ọkọ tàbi ìyàwó, ọba tàbi àwọn ti ó wà ni ipò agbára, òṣèlu ti o nfi ipò wọn jalè àti àwọn ti ó nhu ìwà burúkú yi lati din àbáyọrí ìwà burúkú lóri ẹbí, alá-dúgbò àti àgbáyé kù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2017-11-03 22:47:56. Republished by Blog Post Promoter